Kí Ló Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Dúró Gbọn-in Nínú Ìgbàgbọ́?
1 Látìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà, ìtẹ̀síwájú tí a ń ní nípa tẹ̀mí ti jẹ́ orísun ayọ̀ ńlá fún wa! Ṣùgbọ́n o, bí a óò bá ‘ta gbòǹgbò, kí a gbé wa ró, kí a sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,’ ó pọndandan láti máa bá a lọ ní dídàgbà sókè nípa tẹ̀mí. (Kól. 2:6, 7) Nígbà tí ọ̀pọ̀ kẹ́sẹ járí nípa tẹ̀mí, àwọn kan ti sú lọ nítorí pé wọ́n kùnà láti “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” (1 Kọ́r. 16:13) A lè dènà èyí, kó má ṣẹlẹ̀ sí wa. Báwo la ṣe lè ṣe é?
2 Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Tó Ṣe Déédée: Máa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí nígbà gbogbo nínú ètò àjọ Jèhófà. Ibẹ̀ la ti ń bójú tó àwọn ohun táa nílò nípa tẹ̀mí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àwọn ìpàdé ìjọ àti àwọn àpéjọ ń ru wá sókè láti túbọ̀ máa dàgbà nípa tẹ̀mí, ká sì fẹsẹ̀ múlẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti ń lọ sí ìpàdé déédéé láti gba àwọn ìbùkún náà. (Héb. 10:24, 25) Kíka Bíbélì, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé àti àwọn ìwé tó jíròrò àwọn kókó jíjinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò mú kí gbòǹgbò tẹ̀mí tí a ní jinlẹ̀, kó sì lágbára. (Héb. 5:14) Gbígbé àwọn góńgó tẹ̀mí kalẹ̀ fúnra ẹni, àti ṣíṣiṣẹ́ taápọntaápọn kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n yóò tún mú àwọn àǹfààní pípẹ́ títí wá.—Fílí. 3:16.
3 Ìrànwọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Tó Dàgbà Dénú: Gbìyànjú láti túbọ̀ máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ. Gbìyànjú láti mọ àwọn alàgbà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn lẹni tó lè fún wa lókun ní pàtàkì. (1 Tẹs. 2:11, 12) Tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tàbí àbá èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ọ. (Éfé. 4:11-16) Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nífẹ̀ẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, fún ìdí èyí, máa wá ìṣírí lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin wọ̀nyí.
4 Ǹjẹ́, o ń fẹ́ ìrànwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Bá àwọn alàgbà sọ̀rọ̀, kí o sì wá ìrànwọ́ wọn. Bóyá ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi ẹ kún ètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́. Ṣé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí ni? Kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti fífi àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ sílò yóò mú kí o máa tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí. Ṣé òbí ni ọ́? Máa bá a nìṣó láti maá fún ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ lókun.—Éfé. 6:4.
5 Nípa títa gbòǹgbò àti fífẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, a ń ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, a sì ń ní ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà pẹ̀lú àwọn ará. Èyí ń mú kí a lè kojú ìkọlù Sátánì, ó sì ń fún ìrètí wa nínú ọjọ́ ọ̀la tí kò nípẹ̀kun lókun.—1 Pét. 5:9, 10.