ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/06 ojú ìwé 5
  • Ìrànlọ́wọ́ Tá A Lè Rí Tìrọ̀rùntìrọ̀rùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànlọ́wọ́ Tá A Lè Rí Tìrọ̀rùntìrọ̀rùn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìjọ Kristẹni—Orísun Àrànṣe Afúnnilókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • “Pe Àwọn Alàgbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 2/06 ojú ìwé 5

Ìrànlọ́wọ́ Tá A Lè Rí Tìrọ̀rùntìrọ̀rùn

1. Kí ló lè mú kí ìgbàgbọ́ ẹnì kan dín kù?

1 Aláìgbàgbọ́ ni ọkọ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Anna, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí arábìnrin náà ń ṣe sì ń gbà á lákòókò. Èyí ló fà á tí kì í fi í rọrùn fún un láti máa lọ sí ìpàdé déédéé, kì í ráàyè kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé, kì í sì í ráàyè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, síbẹ̀ ó di aláìṣiṣẹ́mọ́. Àmọ́, inú rẹ̀ dùn nígbà táwọn alàgbà tí wọ́n wà lójúfò fi Ìwé Mímọ́ gbà á níyànjú.

2. Ọ̀nà wo ni gbogbo Kristẹni lè gbà jẹ́ ìrànwọ́ tá a lè rí tìrọ̀rùntìrọ̀rùn?

2 Bá a bá ń gba ìrànlọ́wọ́ nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni, ṣe ló túmọ̀ sí pé a gbára lé Jèhófà fúnra rẹ̀. Àwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ ń fara wé bí Jésù Kristi ṣe ń fi ìfẹ́ bójú tó ìjọ bí wọ́n ṣe ń sapá láti fúnni níṣìírí kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ tó bá yẹ fáwọn tó nira fún láti máa ṣe déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. (1 Tẹs. 5:14) Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìṣírí kan látinú Ìwé Mímọ́ ti tó láti fún ẹni náà lókun. Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan, gbogbo Kristẹni ló yẹ kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe ran àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára lọ́wọ́. Kò ní pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ, kálukú wa ló ti mọ ipa tí ọ̀rọ̀ tó fọgbọ́n yọ “tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́,” máa ń ní lórí ẹni.—Òwe 25:11; Aísá. 35:3, 4.

3, 4. Kí la lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

3 Lo Ìdánúṣe: Ká tó lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó nílò ìrànlọ́wọ́ jẹ wá lógún, àwa la ní láti kọ́kọ́ lo ìdánúṣe, ká fi ìfẹ́ ọmọnìkejì bá wọn lò ká sì ṣe é tọkàntọkàn. Nígbà tí Jónátánì mọ̀ nípa ìṣòro tó dojú kọ Dáfídì, ó gbéra “ó sì lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, kí ó bàa lè fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nípa ti Ọlọ́run.” (1 Sám. 23:15, 16) Bó o bá máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, dákun ṣe wọ́n jẹ́jẹ́ o. Ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ pé àníyàn tó ti ọkàn wá ló mú kéèyàn sọ ọ́, máa ń so èso rere. Síwájú sí i, àpèjúwe tí Jésù lò mú kó ṣe kedere pé èèyàn gbọ́dọ̀ sapá gidigidi kó tó o lè jèrè arákùnrin tàbí arábìnrin kan padà. (Lúùkù 15:4) Bó bá jẹ́ tọkàntọkàn la fi fẹ́ láti ran ọmọnìkejì wa lọ́wọ́, a ó lè ní ìforítì láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kódà bó bá tiẹ̀ dà bíi pé àtúnṣe tá a fẹ́ kó ṣe ò yá tó bá a ṣe fẹ́.

4 Ẹ̀yin ẹ wo bó ṣe máa jẹ́ ìṣírí tó nígbà tá a bá lo ìdánúṣe láti ké sí àwọn ẹlòmíràn, bí àwọn tá a jọ wà ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ, pé kí wọ́n tẹ̀lé wa jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá! Bá a ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bíi tiwa láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a lè lo àǹfààní yẹn láti fún ọwọ́ ẹni náà lókun láti ṣe púpọ̀ sí i. Irú àwọn àkókò aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ tá a bá jọ lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà máa ń jẹ́ ìṣírí fún àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń padà lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìjọ.

5. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú ìrànlọ́wọ́ wo làwọn alàgbà lè ṣe?

5 Ìṣètò Onífẹ̀ẹ́: Àwọn tó ti pẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tàbí tó ti tó ọjọ́ mẹ́ta kan tí wọ́n ti wá sí ìpàdé kẹ́yìn lè nílò ìrànlọ́wọ́ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ kí ìgbàgbọ́ wọn bàa lè lágbára sí i. Gbogbo ohun tí wọ́n nílò lè máà ju kí ẹnì kan kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, Sún Mọ́ Jèhófà, tàbí Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Torí pé onítọ̀hún ti ṣèrìbọmi tẹ́lẹ̀, kò pọn dandan kí ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ́ lọ títí. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti máa kíyè sí ẹni tí ìṣètò yìí bá máa ṣe láǹfààní.—Wo Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1998 àti ti November 2000.

6. Báwo ni arábìnrin kan ṣe padà dẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára?

6 Arábìnrin Anna tá a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí mọrírì ìṣètò táwọn alàgbà ṣe pé kí arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Wọn ò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ju ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ tó fi padà sún mọ́ Jèhófà. Ó tún padà bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé, bẹ́ẹ̀ ló sì tún padà ń bá a nìṣó láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ní yíyin Jèhófà Ọlọ́run. Arábìnrin náà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ tún ràn án lọ́wọ́ láti máa kópa nínu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá nípa mímú tó máa ń mú un dání lọ sọ́dọ̀ àwọn mìíràn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí dìgbà tóun náà fi lókun láti wàásù láti ilé dé ilé. Gbogbo ohun tó nílò láti bẹ̀rẹ̀ sí kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ ò ju ìrànwọ́ onínúure lọ!

7. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú ká máa fún ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíràn lókun?

7 Bá a bá ń fún àwọn aláìlera lókun, ìbùkún ló máa jẹ́ fún gbogbo wa. Ẹni tí wọ́n ràn lọ́wọ́ á láyọ̀ pé òun tún padà sún mọ́ Jèhófà á sì tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó ń kópa déédéé nínú ìgbòkègbodò ètò Ọlọ́run. Àwọn alàgbà tó ràn án lọ́wọ́ pẹ̀lú á láyọ̀ pé ẹni náà ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò ìjọ déédéé. (Lúùkù 15:5, 6) Bí gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ bá ń gba ti ara wọn rò, gbogbo ìjọ á wà ní ìṣọ̀kan. (Kól. 3:12-14) A ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fara wé Jèhófà, ẹni tó jẹ́ ìrànwọ́ tá a lè rí tìrọ̀rùntìrọ̀rùn!—Éfé. 5:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́