Àpótí Ìbéèrè
◼ Báwo ní a ṣe lè ran ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ìgbà pípẹ́ lọ́wọ́ láti tún padà tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere náà?
Ó máa ń fúnni láyọ̀ nígbà tí ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ bá fi ẹ̀rí hàn pé òun ní ìfẹ́ àtọkànwá láti sin Jèhófà. (Lúùkù 15:4-6) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni ẹni yẹn jẹ́ kí àtakò tàbí pákáǹleke ìgbésí ayé dí òun lọ́wọ́ tó fi di pé kò ráyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé, àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Báwo la ṣe lè ràn án lọ́wọ́ dáadáa kí ó lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ láti mú un dá ẹni náà lójú pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àwọn alàgbà yóò yára kánkán láti mọ ohun tí ó jẹ́ àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí ní pàtó. (Ják. 5:14, 15) Bó bá jẹ́ pé kò tíì pẹ́ tó di aláìṣiṣẹ́mọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kìkì ìrànlọ́wọ́ láti ọwọ́ akéde kan tó ní ìrírí ló nílò láti di onítara nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lẹ́ẹ̀kan sí i. Bó ti wù kó rí, bó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ gan an tí aláìṣiṣẹ́mọ́ náà kò ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ, a jẹ́ pé ó nílò ìrànlọ́wọ́ tó pọ̀ gan-an nìyẹn. Láti ru ìgbàgbọ́ àti ìmọrírì rẹ̀ sókè, ó yẹ kí ó máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú onírúurú ìtẹ̀jáde wa. Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò ṣètò pé kí akéde kan tí ó tóótun darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. (Héb. 5:12-14; wo Àpótí Ìbéèrè tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1998.) Bóo bá mọ ẹnì kan tó nílò irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, sọ fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ìjọ rẹ.
Kí o tó ké sí ẹnì kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ìgbà pípẹ́ láti nípìn ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí àwọn alàgbà méjì lọ bá a jíròrò láti mọ̀ bóyá ó tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde Ìjọba. Wọ́n á tẹ̀ lé irú ìlànà tí a ń lò nígbà tí a bá ń jíròrò pẹ̀lú àwọn ẹni tuntun tó fẹ́ di akéde ìjọba náà. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà November 15, 1988, ojú ìwé 17.) Ẹni tó di aláìṣiṣẹ́mọ́ náà gbọ́dọ̀ ní ìtara-ọkàn láti ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bákan náà, òun gbọ́dọ̀ dé ojú ìlà àwọn ohun àbéèrèfún tí a tò lẹ́sẹẹsẹ ní ojú ewé 98 àti 99 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ Ojiṣẹ Wa, kí ó sì máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé.
Níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tó dára yóò ran ẹni náà tó ń padà bọ̀ sípò lọ́wọ́ láti mú kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i kí ó sì wà pẹ́ títí, kí ó sì máa bá a lọ ní rírìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 7:14; Héb. 10:23-25) Bó ṣe ń ṣe “gbogbo ìsapá àfi-taratara-ṣe” tó sì tún ń mú àwọn ànímọ́ Kristẹni tó lè wà pẹ́ títí dàgbà kò ní jẹ́ kí ó tún di “aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso” mọ́ láé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ọmọlẹ́yìn.—2 Pét. 1:5-8.