Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣé ó ṣì bá a mu pé kí a bá arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí ó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé bí ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ bá sọ pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀?
Ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ, títí kan mẹ́ńbà èyíkéyìí tí ó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àwọn alàgbà. Wọ́n máa ń ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, wọ́n sì máa ń pinnu ìrànwọ́ tí a ní láti ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Níbi tí ó bá ti bá a mu, èyí lè ní nínú, pípèsè àǹfààní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ẹnì kan tí ó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́. Ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 103, ṣàlàyé pé Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ni yóò pinnu ẹni tí ó yẹ kí ó jàǹfààní nínú irú ìpèsè bẹ́ẹ̀.
Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni ó ń pinnu ẹni tí ó yẹ jù lọ fún pípèsè ìrànwọ́, àwọn kókó wo ni ó yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ dá lé, àti ìtẹ̀jáde tí yóò ṣèrànwọ́ jù lọ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹni tí ó bá ẹni náà kẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí ẹnì kan tí òun mọ̀ tí ó sì bọ̀wọ̀ fún ni ó wà ní ipò tí ó dára jù lọ láti ṣèrànwọ́. A lè sọ pé kí arábìnrin kan tí ó dáńgájíá tí ó sì dàgbà dénú ṣèrànwọ́ fún arábìnrin kan tí ó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́. Bí ó ti máa ń rí, kì yóò pọndandan pé kí akéde mìíràn bá olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn lọ. Nígbà tí a bá yan akéde kan láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó lè ka àkókò, ìpadàbẹ̀wò, àti ìkẹ́kọ̀ọ́.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1989, ìpínrọ̀ 1 àti 2.
Níwọ̀n bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ti jẹ́ ẹni tí a ti batisí, bí ó ti máa ń rí, kò yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa bá a nìṣó fún ìgbà pípẹ́. Kí a ran ẹni tí ó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ kí ó sì di akéde ìhìn rere tí ń ṣe déédéé ni góńgó náà. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò máa ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀síwájú irú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí lè gbé ẹrù ara wọn tí ó jẹ́ ojúṣe wọn níwájú Jèhófà kí wọ́n ‘ta gbòǹgbò, kí wọ́n sì fìdí múlẹ̀’ gbọn-ingbọn-in nínú òtítọ́ ni ó yẹ kí ó jẹ́ àbájáde ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ yìí.—Éfé. 3:17; Gál. 6:5.