Má Ṣe Gbàgbé Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́
1. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ múra tán láti gba àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ níyànjú?
1 Ṣó o mọ ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́? Bóyá kò tiẹ̀ wá sípàdé mọ́ tàbí kó tiẹ̀ ti sú lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó o wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lo pàdé onítọ̀hún. A gbọ́dọ̀ máa rántí pé arákùnrin tàbí arábìnrin wa ṣì lẹni náà. A ní láti jẹ́ kó mọ̀ pé a ṣì nífẹ̀ẹ́ òun, ká sì ràn án lọ́wọ́ láti lè padà wá sínú ètò Ọlọ́run àti “sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó ọkàn” wa.—1 Pét. 2:25.
2. Báwo la ṣe lè fún aláìṣiṣẹ́mọ́ kan níṣìírí?
2 Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Mọ̀ Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Jẹ Wá Lógún: Bá a bá kàn fi tẹlifóònù bá aláìṣiṣẹ́mọ́ kan sọ̀rọ̀ tàbí tá a kàn ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ rẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó mọ̀ pé a ò gbàgbé òun. Kí la lè sọ? Bá a bá jẹ́ kó mọ̀ pé a ṣì ń ronú nípa òun, ìyẹn á fún un níṣìírí. A ní láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa gbádùn mọ́ ọn kó sì jẹ́ èyí tó ń gbéni ró. (Fílí. 4:8) A lè mẹ́nu ba kókó kan tá a gbọ́ nípàdé láìpẹ́ sígbà yẹn. A tún lè pè é sípàdé ìjọ tàbí ka pè é sí àpéjọ kan tó ń bọ̀ lọ́nà, ká sì jẹ́ kó mọ̀ pé a máa bá a gbàyè sílẹ̀ tàbí pé a máa bá a ṣètò bó ṣe máa rí ọkọ̀ wọ̀ débẹ̀.
3. Báwo ni arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ kan ṣe padà di akéde?
3 Akéde kan bá arábìnrin wa kan pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, ó sì ti lè lógún ọdún tí arábìnrin náà ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, akéde náà tóun náà jẹ́ obìnrin ń pààrà ọ̀dọ́ ẹ̀ ó sì ń fún un ní ìwé ìròyìn tó dé kẹ́yìn. Lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè, akéde náà jíròrò díẹ̀ lára àwọn kókó pàtàkì tó gbọ́ pẹ̀lú arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ náà, nígbà tó sì yá, ó padà di akéde.
4. Báwo la ṣe gbọ́dọ̀ ṣe sí aláìṣiṣémọ́ kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé?
4 Nígbà Tó Bá Padà Dé: Bí aláìṣiṣẹ́mọ́ kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, báwo la ṣe máa ṣe sí i? Ẹ jẹ́ ká wo bí Jésù ṣe ṣe sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti pa á tì. Tọkàntọkàn ló fi pè wọ́n ní “àwọn arákùnrin” òun ó sì gbọ́kàn lé wọn. Kódà iṣẹ́ pàtàkì ló tún gbé lé wọn lọ́wọ́. (Mát. 28:10, 18, 19) Kò pẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í polongo ìhìn rere ní pẹrẹu “láìdábọ̀.”—Ìṣe 5:42.
5. Ṣàlàyé àwọn ìgbà tá a gbọ́dọ̀ sọ fáwọn alàgbà nípa ẹni tó bá jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́.
5 Ká tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí ká tó ké sí ẹni tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ọ̀pọ̀ àkókò pé kó tẹ̀ lé wa lọ sóde ẹ̀rí, dandan ni ká gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ àwọn alàgbà. Bá a bá bá aláìṣiṣẹ́mọ́ kan pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ńṣe ni ká kọ́kọ́ fi tó àwọn alàgbà létí, kí wọ́n bàa lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà ràn án lọ́wọ́.
6. Ayọ̀ wo la lè pín nínú ẹ̀ bá a bá ran aláìṣiṣẹ́mọ́ kan lọ́wọ́?
6 Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, kìkì àwọn tó bá fara dà á títí dópin nìkan ni wọ́n máa rí ìgbàlà. (Mát. 24:13) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa kíyè sí àwọn tí wọ́n ti kọsẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n ti sú lọ. Bá a bá jẹ́ onísùúrù tá a sì fi ìfẹ́ bíi ti Jèhófà hàn nípa jíjẹ́ kí aláìṣiṣẹ́mọ́ rí i pé lóòótọ́ lọ̀rọ̀ òun jẹ wá lógún, ó ṣeé ṣe káwa náà pín nínú ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí i ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i.—Lúùkù 15:4-10.