ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/00 ojú ìwé 7
  • Béèrè Ìrànwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Béèrè Ìrànwọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • “Pe Àwọn Alàgbà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • “Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bá A Ṣe Ṣètò Ìjọ Kristẹni
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 4/00 ojú ìwé 7

Béèrè Ìrànwọ́

1 Àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí náà tó ṣàpèjúwe àkókò lílekoko tí a wà yìí pé yóò “nira láti bá lò” bá a mu gan-an ni. (2 Tím. 3:1) Nígbà náà, kí lo lè ṣe nígbà tí o bá kojú àwọn ìṣòro tẹ̀mí tó dà bíi pé agbára rẹ kò gbé láti borí wọn?

2 Ṣé wàá fẹ́ láti bá ẹnì kan tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí nínú ìjọ rẹ sọ̀rọ̀? Àwọn kan lè lọ́ tìkọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé ojú ń tì wọ́n, àwọn míì sì lè máà fẹ́ kó wàhálà tiwọn bá ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ sì làwọn míì lè máa ṣiyè méjì pé bóyá làwọ́n á rẹ́ni ran àwọn lọ́wọ́. Ká sòótọ́, ó yẹ ká sapá láti bójú tó ọ̀ràn ara wa bí a bá ti lè ṣe tó, ṣùgbọ́n, kò sígbà tó yẹ ká lọ́ tìkọ̀ rárá láti wá ìrànwọ́ nínú àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìlera wa nípa tẹ̀mí.—Gál. 6:2, 5.

3 Ibi Tó Yẹ Kí O Ti Bẹ̀rẹ̀: O lè lọ bá Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ, kí o sì bi í bóyá o lè bá a ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Èyí á fún ẹ láǹfààní láti sọ fún un pé o ń fẹ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí. Bí òun bá jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, jẹ́ kó mọ̀ pé o nílò ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí, yóò wá sọ fún àwọn alàgbà pé kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tàbí, o lè lọ bá èyíkéyìí lára àwọn alàgbà, kí o sì sọ ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún wọn.

4 Irú ìrànwọ́ wo lo ń fẹ́? Ṣé kì í ṣe pé ìtara rẹ ti jó rẹ̀yìn? Àbí òbí anìkantọ́mọ ni ẹ́, tí o ń gbìyànjú láti mú kí àwọn ọmọ rẹ fara mọ́ ìjọ dáadáa? Ṣé arúgbó ni ẹ́, tóo sì nílò ìrànwọ́? Àbí ìṣòro kan ló ń mú ẹ rẹ̀wẹ̀sì? Kíkojú àwọn àkókò lílekoko tí a wà lè nira, àmọ́ kì í ṣe pé a ò lè kojú rẹ̀. Ìrànwọ́ ń bẹ.

5 Bí Àwọn Àgbà Ọkùnrin Ṣe Ń Ṣèrànwọ́: Tinútinú làwọn alàgbà fi máa ń ṣèrànwọ́. Wọ́n á tẹ́tí sí àwọn ohun tó ń jẹ ọ́ lọ́kàn. Bírú àwọn ìṣòro yẹn bá tún ń dojú kọ àwọn akéde mìíràn nínú ìjọ, àwọn alàgbà á gbé èyí yẹ̀ wò bí wọ́n ti ń ṣolùṣọ́ àgùntàn, tí wọ́n sì ń kọ́ ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. Gẹ́gẹ́ bí “àpẹẹrẹ fún agbo,” wọ́n múra tán nígbà gbogbo láti ṣiṣẹ́ tayọ̀tayọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú rẹ. (1 Pét. 5:3) Fífetí sí àwọn arákùnrin tó nírìírí wọ̀nyí bí wọ́n ti ń ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ sunwọ̀n sí i, ó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ.—2 Tím. 3:16, 17.

6 Jésù ti fún wa ní ọ̀pọ̀ “ẹ̀bùn, tí wọ́n jẹ́ àwọn èèyàn.” (Éfé. 4:8, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Èyí túmọ̀ sí pé àwọn alàgbà wà ní sẹpẹ́ fún ẹ. Wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ká kúkú sọ pé wọ́n ‘jẹ́ tìẹ.’ (1 Kọ́r. 3:21-23) Nítorí náà, dípò pípa ẹnu mọ́, sọ̀rọ̀ jáde. Béèrè fún ìrànwọ́ tí o nílò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́