ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/00 ojú ìwé 3-4
  • Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ A Lè Mú Kí April 2000 Jẹ́ Oṣù Tí A Tíì Ṣe Dáadáa Jù Lọ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Jẹ́ Onítara fún Ohun Rere!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 4/00 ojú ìwé 3-4

Oṣù April Jẹ́ Àkókò Láti Jẹ́ Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà!

1 Bí ìjì líle bá ti ń sún mọ́ àgbègbè kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni yóò jẹ́ kánjúkánjú pé ká kìlọ̀ fún àwọn èèyàn nípa ewu tó ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ náà. Bí ìjì líle náà bá ṣe ń sún mọ́ tòsí sí i tó ni ìkìlọ̀ náà ṣe gbọ́dọ̀ máa dún gbọnmọgbọnmọ tó. Èé ṣe? Ìdí ni pé, ẹ̀mí àwọn ènìyàn wà nínú ewu! Ó ṣeé ṣe káwọn kan máà gbọ́ ìkìlọ̀ táa ṣe tẹ́lẹ̀. Àwọn míì sì lè gbọ́ ṣùgbọ́n kí wọ́n máà gbégbèésẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ìkìlọ̀ àtọ̀runwá tí a ti gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká kìlọ̀ kí “ẹ̀fúùfù oníjì” ti ìbínú òdodo Ọlọ́run tó gbá gbogbo ohun tó ṣẹ́ kù tó jẹ́ ti ayé búburú yìí lọ. (Òwe 10:25) Ìyè ayérayé ẹgbàágbèje èèyàn wà nínú ewu! A gbọ́dọ̀ kìlọ̀. A gbọ́dọ̀ jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”—Títù 2:11-14.

2 Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, a ti sún àwọn èèyàn Jèhófà láti mú kí ìgbà Ìṣe Ìrántí máa jẹ́ àkókò fún ìtara àkànṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà ìrúwé ọdún 1939, Informant, tí í ṣe orúkọ táa fi ń tẹ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa jáde tẹ́lẹ̀, fúnni ní ìṣírí yìí pé: “Bí ìgbà ìrúwé ṣe ń bọ̀ yìí, tójú ọjọ́ á sì dára, ó yẹ ká retí pé wákàtí tí àwọn akéde ìjọ yóò lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá á di ìlọ́po méjì, tí wákàtí àwọn aṣáájú ọ̀nà á sì pọ̀ sí i dáadáa. Ọjọ́ Sunday márùn-ún loṣù April ní. Ó tún ní Sátidé márùn-ún. Jẹ́ kí gbogbo ọjọ́ Sátidé àti Sunday nínú oṣù April . . . jẹ́ àkókò ìjẹ́rìí àkànṣe fún ẹ.” Ìyẹn jẹ́ góńgó tí ń peni níjà, tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ará ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn! Lọ́dún yìí, bó ṣe rí lọ́dún 1939, oṣù April ní òpin ọ̀sẹ̀ kíkún rẹ́rẹ́ márùn-ún. Kí làwọn ìwéwèé rẹ lóṣù yìí? Àwọn ohun wo tóo fẹ́ ṣe lo ti kọ sórí kàlẹ́ńdà rẹ fún oṣù April 2000? Wéwèé láti kópa lọ́nà tó jọjú nínú iṣẹ́ àtàtà pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà yòókù nínú oṣù àkànṣe yìí, tí a óò mú kí ìgbòkègbodò tẹ̀mí pọ̀ sí i.

3 Ohun Táa Retí Pé A Ó Ṣe: Inú oṣù yìí ni ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún 2000 bọ́ sí. April 19 ni, àyájọ́ ikú Jésù. Ẹ jẹ́ ká sapá lákànṣe láti ké sí ọ̀pọ̀ èèyàn wá sí Ìṣe Ìrántí bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bí a ṣe dábàá lóṣù tó kọjá, kọ orúkọ gbogbo àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí, kí o sì yẹ̀ ẹ́ wò láti rí i pé kò sẹ́ni tóo yọ sílẹ̀. Àwọn tí o máa ké sí ni àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìpadàbẹ̀wò, àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ rí, àwọn tẹ́ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ nílé ẹ̀kọ́, àwọn aládùúgbò, àwọn ìbátan, àti àwọn ojúlùmọ̀ mìíràn. Ṣé gbogbo àwọn tó fẹ́ wá ló lóhun ìrìnnà tó lè gbé wọn wá? Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé o lè fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́? Lálẹ́ ọjọ́ Ìṣe Ìrántí náà, gbogbo wa yóò láǹfààní láti mú kí ara tu àwọn tó bá wá. Lẹ́yìn Ìṣe Ìrántí, a lè máa bá a nìṣó láti túbọ̀ ṣe ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí fún irú àwọn tó fìfẹ́ hàn bẹ́ẹ̀.

4 Jíjẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” ní àwọn ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ Ìṣe Ìrántí àti lẹ́yìn ọjọ́ yẹn jẹ́ ọ̀nà rere láti fi han Jèhófà pé lóòótọ́ la mọrírì gbogbo ohun tó ṣe fún wa. Bóo bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, sa gbogbo ipá rẹ kí o lè lo àádọ́ta wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Mát. 5:37) Tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tóo ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. (Oníw. 3:1; 1 Kọ́r. 14:40) Ǹjẹ́ kí àwa yòókù ṣe ohun táa bá lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà, nípa fífún wọn níṣìírí àti nípa bíbá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. (Fi wé 2 Àwọn Ọba 10:15, 16.) Bí a bá fi ìtara fúnrúgbìn lóṣù April, a lè retí ayọ̀ àti ìbùkún ńláǹlà látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Mál. 3:10) Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nìṣó tàbí ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ǹjẹ́ kí ìtara tẹ̀mí táa bá jèrè lóṣù April bá wa wọnú àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e bí a ṣe ń bá a nìṣó láti jẹ́ akéde Ìjọba náà tí ń ṣe déédéé.

5 Láìsí tàbí-tàbí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn Jèhófà yóò bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lóṣù yìí. Ṣé wàá fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀kan? Gbàdúrà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ní pàtó, kí o sì ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ. Kí ó dá ẹ lójú pé Jèhófà yóò mọrírì pé o fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè ìrànwọ́ láti rí aláìlábòsí ọkàn kan kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.—1 Jòh. 3:22.

6 Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan rèé táa ti lò nínú pápá, tó sì ti gbéṣẹ́ gidi láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Kí o bẹ̀rẹ̀ nípa bíbéèrè pé: “Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ìwà ipá tó ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ilé ìwé wa jẹ́ iṣẹ́ àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí ó jẹ́ torí àìlẹ́kọ̀ọ́ ilé?” Jẹ́ kó fèsì. Bí ẹni náà bá sọ pé “iṣẹ́ àwọn ẹ̀mí èṣù ni,” ka Ìṣípayá 12:9, 12, kí o sì ṣàlàyé ipa tí Èṣù ń kó nínú mímú kí pákáǹleke pọ̀ sí i nínú ayé. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 4, kí o sì béèrè bóyá ẹni náà ti ṣe kàyéfì rí nípa ibi tí Èṣù ti wá. Ka ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́, kí o sì jíròrò wọn. Bó bá jẹ́ pé “àìlẹ́kọ̀ọ́ ilé” lẹni náà sọ pé ó ń fa ìwà ipá nílé ìwé, ka 2 Tímótì 3:1-3 kí o sì tọ́ka sí ànímọ́ tó hàn gbangba pé ó ń dá kún ìṣòro yìí. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 8, ka ìpínrọ̀ 5, kí o sì máa bá ìjíròrò nìṣó. Bí o bá lè ṣe àdéhùn pé wàá padà wá, ó ṣeé ṣe gidigidi kó jẹ́ pé bí wàá ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹni yẹn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé lo bẹ̀rẹ̀ yẹn. Nígbà ìbẹ̀wò tóo bá ṣe tẹ̀ lé e, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó mọ ẹlòmíràn tó lè fẹ́ láti gbọ́ ohun tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.

7 Ọ̀nà mìíràn tí a lè gbà jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” lóṣù April jẹ́ nípa kíkópa nínú onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa jíjẹ́rìí níbi ìgbọ́kọ̀sí? Ní ibùdókọ̀ èrò tàbí ti ọkọ̀ ojú irin? Àbí wàá fẹ́ láti gbìyànjú láti fi tẹlifóònù jẹ́rìí, láti jẹ́rìí lópòópónà, tàbí ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n ti ń ṣòwò? Kí ló dé tí o ò kúkú ṣe àwọn nǹkan tí o ń rò lọ́kàn wọ̀nyẹn lóṣù yìí? Jèhófà á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìgboyà tóo nílò. (Ìṣe 4:31; 1 Tẹs. 2:2b) O lè ṣàdéhùn láti bá aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde tó dáńgájíá nínú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọ̀nyí ṣiṣẹ́.

8 Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí gbọ́dọ̀ jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó ń béèrè ni pé kóo bá ẹnì kan jíròrò lọ́nà ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Ṣáà ti mẹ́nu ba kókó ọ̀rọ̀ kan tí ọ̀pọ̀ máa ń nífẹ̀ẹ́ sí, bóyá kí o lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a ṣàlàyé ní ìpínrọ̀ 6. Gbìyànjú láti lo àkókò tóo bá ní lọ́nà rere, bó ti wù kó kéré mọ, dípò tí wàá fi jẹ́ kó ṣòfò. Kódà bó jẹ́ ìṣẹ́jú márùn-ún, ìṣẹ́jú mẹ́wàá, tàbí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni, o lè lò ó láti jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà.

9 Àkókò Kan Láti Ronú Jinlẹ̀: Rántí àwọn kókó pàtàkì tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí a ṣe ní Ìpàdé Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” lọ́dún tó kọjá tẹ̀ mọ́ni lọ́kàn. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní Mímọrírì Ogun Tẹ̀mí Táa Ní, mú wa ronú jinlẹ̀ nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jékọ́bù àti Ísọ̀. Ísọ̀ sọ pé bí Jékọ́bù ṣe fẹ́ràn àwọn nǹkan tẹ̀mí lòun náà ṣe fẹ́ràn wọn, ṣùgbọ́n iṣẹ́ Ísọ̀ kò fi hàn bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 25:29-34) Ìkìlọ̀ ńláǹlà ló mà jẹ́ fún wa o! Bíi Jékọ́bù, ẹ jẹ́ ká múra tán láti jìjàkadì, àní ká ja ẹkẹ láti rí ìbùkún Jèhófà. (Jẹ́n. 32:24-29) Kí ló dé ti a ò lo oṣù April àti àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e láti sọ ìtara wa dọ̀tun, ká má ṣe fojú tín-ínrín àgbàyanu ogún tẹ̀mí táa ní?

10 “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sef. 1:14) A gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere Ìjọba náà. Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu! Ǹjẹ́ kí oṣù yìí jẹ́ ìbùkún ní pàtàkì fún gbogbo àwọn èèyàn Jèhófà bí a ṣe ń fi hàn ní ìṣọ̀kan pé a “jẹ́ onítara fún iṣẹ́ àtàtà.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí

Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí bọ́ sí ọjọ́ Wednesday, April 19. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn ọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

◼ Ní ṣíṣètò àkókò fún ìpàdé náà, ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri títí di ẹ̀yìn tí oòrùn bá wọ̀.

◼ Kí a fi àkókò tí a óò ṣe ayẹyẹ náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é tó gbogbo ènìyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀, létí.

◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tó bá a mu wẹ́kú, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.

◼ Kí a gbé àwo, ago, àti tábìlì àti aṣọ tí ó yẹ wẹ́kú wá sínú gbọ̀ngàn, kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.

◼ Kí a tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò ti pàdé ṣe, kó wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.

◼ Kí a yan àwọn olùbójútó èrò àti àwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ẹrù iṣẹ́ wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é.

◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò lera, tí kò sì lè wá.

◼ Tí a bá ṣètò kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí ẹnu ọ̀nà, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, àti ibi ìgbọ́kọ̀sí má baà kún jù.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́