ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/01 ojú ìwé 8
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Máa Lọ sí Àwọn Ìpàdé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Máa Lọ sí Àwọn Ìpàdé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 3/01 ojú ìwé 8

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Máa Lọ sí Àwọn Ìpàdé

1 “A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ẹnikẹ́ni tó bá wà ládùúgbò wa . . . tó bá fẹ́ láti máa wá sí àwọn ìpàdé pé kó máa wá o.” Látìgbà tí ìfilọ̀ yìí ti jáde nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower ti November 1880, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi ìtara ké sí àwọn èèyàn láti wá péjọ fún ìtọ́ni Bíbélì. (Ìṣí. 22:17) Èyí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́.

2 Ó Pọn Dandan Kí O Máa Wá Síbẹ̀: A máa ń bù kún wa nígbà tí a bá ń péjọ pẹ̀lú ìjọ. À ń túbọ̀ dojúlùmọ̀ àgbàyanu Ọlọ́run wa, Jèhófà lọ́nà tó dára sí i. Nínú ìjọ, a máa ń péjọ láti di ẹni tí a “kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísá. 54:13) Ètò àjọ rẹ̀ ń pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni Bíbélì tó ń bá a nìṣó tó ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, tí ó sì ń pèsè ìrànwọ́ tó wúlò fún fífi “ìpinnu Ọlọ́run” sílò. (Ìṣe 20:27; Lúùkù 12:42) Àwọn ìpàdé máa ń dá olúkúlùkù wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe lè máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni. Àwọn ìránnilétí látinú Ìwé Mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbádùn àjọṣe tó dán mọ́rán láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn àti Jèhófà alára. Bíbá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun.—Róòmù 1:11, 12.

3 Ké sí Wọn Ní Tààràtà: Látìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ àkọ́kọ́, ké sí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sí ìpàdé. Fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìwé ìléwọ́. Ru ìfẹ́ rẹ̀ sókè nípa bíbá a ṣàjọpín kókó kan tó fún ọ níṣìírí nínú ìpàdé tí ẹ ṣe kẹ́yìn, àti nípa yíyẹ nǹkan kan tẹ́ẹ máa jíròrò ní ìpàdé tó ń bọ̀ wò. Ṣàpèjúwe bí Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe rí, kí o sì rí i dájú pé ó mọ bí òun ṣe lè mọ ibẹ̀.

4 Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan kò bá wá lójú ẹsẹ̀, máa ké sí i ṣáá. Lo ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ́sẹ̀ láti fi bí ètò àjọ wa ṣe ń ṣiṣẹ́ hàn án. Lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹrii Jehofah Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, bó bá sì ṣeé ṣe, kí o tún lo fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name láti mú kí ó mọ̀ nípa wa àti nípa àwọn ìpàdé wa. Mú àwọn akéde mìíràn dání kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè mọ̀ wọ́n. Nígbà tí o bá ń gbàdúrà, dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ètò àjọ yìí kí o sì mẹ́nu kan yíyẹ tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà wá sínú ètò àjọ náà.

5 Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti ran àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ láti máa péjọ pẹ̀lú wa. Bí ìmọrírì wọn fún Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i, yóò mú kí wọ́n fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò kí wọ́n sì di ara ètò àjọ Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan.—1 Kọ́r. 14:25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́