Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa
1 “Ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ tí a ń jẹ́ ní èyí tí ó ju 200 èdè lọ. Ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ tí a ń gbọ́ ní èyí tí ó ju 210 ilẹ̀ lọ. Ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ kan tí a ń jẹ́ fúnra ẹni níbikíbi tí a bá ti lè rí àwọn ènìyàn. Ó jẹ́ gbogbo apá ìgbétásì ìwàásù títóbi lọ́lá jù lọ tí ayé tí ì mọ̀ rí, ìhìn iṣẹ́ kan tí ń so àràádọ́ta ọ̀kẹ́ pọ̀ ṣọ̀kan kárí ilẹ̀ ayé. A ti ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí fún ohun tí ó ju ọ̀rúndún kan lọ!”
2 Bí àlàyé fídíò náà, Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn àwọn ìbéèrè náà: Àwọn wo gan-an ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Báwo ni a ṣe ṣètò ìgbòkègbodò wọn? Báwo ni a ṣe ń darí rẹ̀? Báwo ni a ṣe ń pèsè owóòná rẹ̀? Ó tẹ òtítọ́ náà pé “a ti dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aládùúgbò wọn láti gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Bíbélì,” mọ́ àwọn tí ń wò ó lọ́kàn, ó sì fún wọn níṣìírí láti rí ètò àjọ náà tí ó wà lẹ́yìn orúkọ wa fúnra wọn. Lẹ́yìn rírí fídíò yí, obìnrin kan tí ń kẹ́kọ̀ọ́ bú sẹ́kún ayọ̀ àti ìmọrírì, ó sì sọ pé: “Báwo ni ẹnì kan kò ṣe ní rí i pé ètò àjọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, ni èyí?”—Fi wé Kọ́ríńtì Kíní 14:24, 25.
3 Obìnrin mìíràn ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìdákúrekú fún ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n òun kò lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà pé Mẹ́talọ́kan jẹ́ ẹ̀kọ́ èké. Lẹ́yìn náà, a fi fídíò wa han òun àti ọkọ rẹ̀. Ìgbékalẹ̀ náà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì wò ó lẹ́ẹ̀mejì ní alẹ́ kan náà. Ní ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn tí ó tẹ̀ lé e, ìyàwó náà sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti di Ẹlẹ́rìí jáde. Ó sọ pé òun ti ń pọkàn pọ̀ sórí ìgbàgbọ́ òun nínú Mẹ́talọ́kan, òun sì kùnà láti wo ètò àjọ wa àti àwọn ènìyàn tí ó wà nínú rẹ̀. Láti inú fídíò náà, ó mọ̀ pé òun ti rí ètò àjọ tòótọ́ ti Ọlọ́run. Ó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé lójú ẹsẹ̀. Lẹ́yìn tí a ti ṣàlàyé àwọn ìgbésẹ̀ pípọn dandan fún dídi akéde tí kò tí ì ṣe batisí fún un, ó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí a jáfara nípa rẹ̀.” Ó kọ̀wé yọ ara rẹ̀ kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá, ó sì di ògbóǹkangí nínú fífi Mẹ́talọ́kan hàn pé ó jẹ́ irọ́.
4 A ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dáradára pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí dídára jù, wọ́n sì ń yára dàgbà dénú nígbà tí wọ́n bá mọ ètò àjọ Jèhófà tí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ọn. Lọ́nà tí ó gba àfiyèsí, lẹ́yìn tí a batisí àwọn 3,000 ní Pẹ́ńtíkọ́sì, “wọ́n bá a nìṣó ní yíya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì, àti fún kíkẹ́gbẹ́pọ̀.” (Ìṣe 2:42, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Ó ṣe pàtàkì pé kí a ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà lónìí. Báwo ni a ṣe lè ṣe é?
5 Gbé Ẹrù Náà: Olùsọnidọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ẹrù iṣẹ́ òun ni láti darí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ètò àjọ Ọlọ́run. (1 Tím. 4:16) A ní láti máa wo sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí òkúta àtẹ̀gùn kan síhà ọjọ́ aláyọ̀ náà nígbà tí ẹni tuntun náà yóò ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Jèhófà nípasẹ̀ batisí. Ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè tí a óò bi í nígbà ayẹyẹ batisí náà ni: “O ha lóye pé ìyàsímímọ́ àti batisí rẹ ń fi ọ́ hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ Ọlọ́run tí a ń fẹ̀mí darí bí?” Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí ó mọ̀ pé òun kò lè ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run láìfi aápọn bá ìjọ Kristẹni tòótọ́ kẹ́gbẹ́.—Mát. 24:45-47; Jòh. 6:68; 2 Kọ́r. 5:20.
6 Máa bá a nìṣó láti kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọ àdúgbò àti ètò àjọ náà kárí ayé tí ó wà lẹ́yìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣe èyí ní sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ti àkọ́kọ́. Láti ìbẹ̀rẹ̀ gan-an, ké sí akẹ́kọ̀ọ́ náà sí àwọn ìpàdé, sì máa bá a nìṣó ní kíkésí i.—Ìṣí. 22:17.
7 Lo Àwọn Irin Iṣẹ́ Tí A Pèsè: Àwọn ìtẹ̀jáde wa dídára jù lọ fún lílò nínú dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé ni ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, àti ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Méjèèjì tẹnu mọ́ àìní náà láti dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Ìparí ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sọ pé: “O ní láti máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa, kí o sì ṣe àwọn ohun tí òun béèrè. Lílọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ó wà ládùúgbò rẹ, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Ìwé Ìmọ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́ níṣìírí léraléra láti dara pọ̀ ní àwọn ìpàdé. Orí 5, ìpínrọ̀ 22, nawọ́ ìkésíni yìí jáde pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa . . . fi tọ̀yàyà tọ̀yàyà rọ̀ ọ́ láti ṣàjọpín pẹ̀lú wọn nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run ‘ní ẹ̀mí ati òtítọ́.’ (Johannu 4:24)” Orí 12, ìpínrọ̀ 16, wí pé: “Bí o ti ń bá a lọ pẹ̀lú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí tí o sì sọ ọ́ di àṣà rẹ láti pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ìgbàgbọ́ rẹ ni a óò túbọ̀ fún lókun sí i.” Orí 16, ìpínrọ̀ 20, wí pé: “Sọ ọ́ di àṣà rẹ láti pésẹ̀ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Ó fi kún un pé: “Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àti lẹ́yìn náà kí o fi ìmọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ yóò sì mú ayọ̀ wá fún ọ. Jíjẹ́ apá kan ẹgbẹ́ àwọn ará Kristian kárí-ayé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti súnmọ́ Jehofa.” Orí 17 jíròrò bí ẹnì kan ṣe ń rí ààbò tòótọ́ láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn kẹ́kọ̀ọ́, ẹrù iṣẹ́ wa ni láti tẹnu mọ́ àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà.
8 Ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, jẹ́ irin iṣẹ́ àtàtà tí a pèsè láti sọ ẹnì kọ̀ọ̀kan dojúlùmọ̀ ètò àjọ kan ṣoṣo tí a lè fojú rí tí Jèhófà ń lò lónìí láti ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀. Kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni tí ó ní nínú nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn ìpàdé, àti ètò àjọ wa yóò fún òǹkàwé níṣìírí láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run. Gbàrà tí a bá ti fìdí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì múlẹ̀, a dábàá pé kí o jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí láti kà fúnra rẹ̀. Kò sí ìdí láti bá a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí.
9 Àwọn kan nínú àwọn fídíò tí Society ti pèsè jẹ́ irin iṣẹ́ dídára jù lọ fún dídarí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ètò àjọ náà tí ó wà lẹ́yìn orúkọ wa. Yóò dára bí wọ́n bá lè wo (1) The New World Society in Action, àtúnyẹ̀wò fíìmù ti 1954 tí ó ṣàgbéyọ ẹ̀mí dídán mọ́rán, tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́, èyí tí ètò àjọ Jèhófà fi ń ṣiṣẹ́; (2) United by Divine Teaching, tí ó ṣàyẹ̀wò ìṣọ̀kan alálàáfíà tí a ti fi hàn ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé wa ní Ìlà Oòrùn Europe, Gúúsù America, Áfíríkà, àti ní Éṣíà; (3) To the Ends of the Earth, tí ó sàmì sí àyájọ́ aláàádọ́ta ọdún ti Watchtower Bible School of Gilead, tí ó sì fi agbára ìdarí tí àwọn òjíhìn iṣẹ́ Ọlọ́run ní ilẹ̀ òkèèrè ti ní lórí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé hàn; (4) Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, tí ó sọ ìtàn tí ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa ìgboyà àti ìjagunmólú Àwọn Ẹlẹ́rìí lójú inúnibíni òǹrorò tí Hitler ṣe sí wọn; àti, (5) Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name bákan náà.
10 Fi Góńgó Tí Ń Tẹ̀ Síwájú Lélẹ̀ fún Àwọn Ìpàdé: A ní láti ṣàlàyé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé a nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni tí a ń pèsè nínú ìgbékalẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé àti ìjíròrò kíláàsì tí a ń pèsè ní àwọn ìpàdé ìjọ. (Jòh. 6:45) Ẹni tuntun kan ní láti tẹ̀ síwájú dọ́gbadọ́gba nínú òye rẹ̀ nípa Ìwé Mímọ́ àti nípa ètò àjọ náà. Láti lè ṣe ìyẹn, kò sí àfidípò fún lílọ sí àwọn ìpàdé. (Héb. 10:23-25) Bẹ̀rẹ̀ sí í ké sí ẹni náà sí àwọn ìpàdé lójú ẹsẹ̀. Àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun kan bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ṣáájú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ilé pàápàá. Àmọ́ ṣáá o, àwa fúnra wa fẹ́ láti fi àpẹẹrẹ yíyẹ lélẹ̀ nípa lílọ sí ìpàdé déédéé.—Lúùk. 6:40; Fílíp. 3:17.
11 Ṣàjọpín ìsọfúnni tí ó tó nípa àwọn ìpàdé àti bí a ṣe ń darí wọn kí ara akẹ́kọ̀ọ́ náà lè balẹ̀ nígbà tí ó bá wá sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́. Níwọ̀n bí ara àwọn ènìyàn kan kì í ti í balẹ̀ nígbà tí wọ́n bá lọ sí ibi tí wọn kò dé rí fún ìgbà àkọ́kọ́, ó lè ṣàǹfààní láti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ náà nígbà tí ó bá ń lọ sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́. Ara rẹ̀ yóò túbọ̀ balẹ̀ bí o bá wà pẹ̀lú rẹ̀ bí òun ti ń pàdé àwọn mẹ́ńbà ìjọ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, jẹ́ olùgbàlejò rere fún àlejò rẹ, ní mímú kí ara tù ú.—Mát. 7:12; Fílíp. 2:1-4.
12 Fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti lọ sí ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọpọ̀ àgbègbè nígbà tí àǹfààní rẹ̀ bá kọ́kọ́ ṣí sílẹ̀. Bóyá o lè fi í kún ìṣètò ọkọ̀ rẹ.
13 Gbin Ìmọrírì Àtọkànwá Síni Nínú: Ìwé náà, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 91 ṣàlàyé pé: “Bi imọriri tí ó jinlẹ tirẹ funraarẹ fun eto-ajọ Jehofah bá farahan ninu ijumọsọrọpọ rẹ pẹlu awọn eniyan olufifẹhan, yoo rọrun pupọ fun wọn lati dagba ninu imọriri ati pẹlu yoo sún wọn lati ní itẹsiwaju tí ó ga pupọ ninu didi ẹni tí ó mọ Jehofah.” Máa sọ̀rọ̀ ìjọ rẹ ní rere nígbà gbogbo, má ṣe sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní búburú láé. (Orin Dá. 84:10; 133:1, 3b) Nínú àwọn àdúrà tí ó ń gbà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, máa dárúkọ ìjọ àti àìní tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní láti dara pọ̀ mọ́ ọn déédéé.—Éfé. 1:15-17.
14 Dájúdájú, a fẹ́ kí àwọn ẹni tuntun mú ìmọrírì àtọkànwá dàgbà fún ìbákẹ́gbẹ́ tí ń múnú ẹni dùn àti ààbò tẹ̀mí tí ó wà láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. (1 Tím. 3:15; 1 Pét. 2:17; 5:9) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí ètò àjọ tí ó wà lẹ́yìn orúkọ wa.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí tí ó túbọ̀ yára kánkán nígbà tí wọ́n bá rí ètò àjọ náà fúnra wọn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Má ṣe jáfara láti ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ sí àwọn ìpàdé