Kí Ló Yẹ Ká Gbé Ìwéwèé Wa Kà?
1 Gbogbo wa ló máa ń ronú nípa ohun táa ń wéwèé nípa ọjọ́ ọ̀la. Àwọn tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé máa ń fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà tó lè gba ìrètí yẹn kúrò lọ́kàn èèyàn. A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti máa fi ìgbòkègbodò Ìjọba náà ṣáájú nínú ìgbésí ayé wa, ká má sì jẹ́ kí àwọn ohun tí ẹran ara ń fẹ́ tó ń dẹni wò mú wa yà bàrá.—1 Jòh. 2:15-17.
2 Ohun táwọn tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa ń fi ṣe góńgó wọn kò lè yé ayé yìí. (1 Kọ́r. 2:14) Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe làwọn yòókù láyé máa ń ṣe kìràkìtà láti lókìkí, láti gba agbára, tàbí láti lọ́rọ̀, àwọn ìṣúra tẹ̀mí làwá máa ń lépa. (Mát. 6:19-21) Bí a bá gbìyànjú láti yí ìrònú wa padà kí ó lè bá èrò tí ayé ní nípa ọjọ́ ọ̀la mu, ǹjẹ́ ọwọ́ wa á lè tẹ àwọn góńgó tẹ̀mí táa ní? Kò ní pẹ́ táwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì á fi gba gbogbo ọkàn wa. Báwo la ṣe lè dènà èyí?
3 “Ẹ Gbé Olúwa Jésù Kristi Wọ̀”: Ṣíṣàyẹ̀wò ohun táa máa ń jíròrò rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè gbà mọ̀ bóyá a ń fi àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba náà ṣáájú. Ṣé gbogbo ìgbà la máa ń jíròrò nípa àwọn nǹkan ti ara àti àwọn ìgbòkègbodò tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò bóyá ọkàn wa ti ń kúrò lórí àwọn góńgó tẹ̀mí. Ó lè pọndandan pé ká túbọ̀ fiyè sí ‘gbígbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀, dípò wíwéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.’—Róòmù 13:14.
4 Àwọn èwe lè ‘gbé Kristi wọ̀’ nípa wíwéwèé ṣáájú fún ọjọ́ kan tí wọ́n á wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ọ̀dọ́ kan tó fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé ni wọ́n tọ́ dàgbà níbi tó ti jẹ́ àṣà pé kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣiṣẹ́ láti di ọlọ́rọ̀. Nítorí náà, ó kira bọ iṣẹ́ ajé débi tó fi jẹ́ pé agbára káká ló fi ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, tó sì fi ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Mátíù 6:33, ló bá jáwọ́ nínú iṣẹ́ àṣekúdórógbó tó ń ṣe, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ní báyìí, ó ń fi ẹ̀rí ọkàn rere sin Jèhófà, ó sì ‘ń fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀’ bí òun alára ṣe sọ.
5 Bíbélì sọ pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn wéwèé fún ọjọ́ ọ̀la. (Òwe 21:5) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe bẹ́ẹ̀ bí a ti ń jẹ́ kí ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ wà ní góńgó ẹ̀mí wa.—Éfé. 5:15-17.