Wéwèé Ṣáájú!
1 Ètò àjọ Jèhófà ń pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ déédéé nípa àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí a ṣètò láti tẹ́ gbogbo àìní wa nípa tẹ̀mí lọ́rùn. Ìmọrírì ń sún wa láti lo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní gbogbo ohun tí a pèsè, irú bí ìbẹ̀wò alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀, àti àwọn ìgbòkègbodò àkànṣe tí a wéwèé nínú ìjọ. (Mát. 5:3) Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ máa ń pàdánù púpọ̀ nínú àwọn ìpèsè tẹ̀mí wọ̀nyí nítorí àwọn ìwéwèé mìíràn tí wọ́n ti ṣe. Kí la lè ṣe láti yẹra fún èyí? Báwo la ṣe lè rí i dájú pé àwọn ìgbòkègbodò tí kì í ṣe ti ìṣàkóso Ọlọ́run kò ṣèdíwọ́ fún “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù”?—Fílí. 1:10.
2 Ìwéwèé Táa Ń Fọgbọ́n Ṣe Ṣe Pàtàkì: Òwe 21:5 ṣíni létí pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” Láti jèrè “àǹfààní” nípa tẹ̀mí, ó yẹ ká wéwèé ṣáájú taápọntaápọn, ká máa fi àwọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọ́run tí a ti ṣètò sọ́kàn. Ó yẹ ká ṣètò àwọn ìgbòkègbodò ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sí àkókò tí wọn kò ní ṣèdíwọ́ fún wíwà wa lárọ̀ọ́wọ́tó láti kórè àwọn ìbùkún tẹ̀mí. Bí a bá fi ìwàǹwára wéwèé láti ṣe àwọn ohun táa fẹ́ ṣe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, láìjẹ́ pé a ronú nípa àwọn ètò ìṣàkóso Ọlọ́run tí ń bọ̀ lọ́nà, ó ṣeé ṣe kí “àìní” nípa tẹ̀mí bá wa fínra.
3 Má Ṣe Pàdánù! Gbogbo wa ló máa ń wéwèé fọ́jọ́ ọ̀la, títí kan ìwéwèé fún ìsinmi, ìrìn àjò iṣẹ́ ajé, ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ìbátan, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kóo tó ṣàdéhùn tàbí kóo tó parí ìwéwèé rẹ, ṣàyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìgbòkègbodò nípa tẹ̀mí tí ń bọ̀ lọ́nà. Bí o bá rí i pé alábòójútó àyíká ń bọ̀ tàbí pé a ṣètò àpéjọ kan sí àkókò kan náà tí oò ní sí nílé, sapá gidigidi láti tún ètò náà ṣe kí o lè lọ́wọ́ nínú rẹ̀. A máa ń tètè sọ fún wa nípa àwọn nǹkan pàtàkì táa ṣètò fún ọjọ́ iwájú. Àwọn alàgbà ìjọ rẹ lè sọ àwọn nǹkan tí ìjọ ti wéwèé fún ọ.
4 Nípa lílo òye rírí nǹkan tẹ́lẹ̀ àti wíwéwèé ṣáájú fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, a óò “kún fún èso òdodo, . . . fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.”—Fílí. 1:11.