Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Rọrùn Tó sì Yéni Ló Dára Jù Lọ
1 Kí nìdí tí àwọn akéde tó jẹ́ èwe fi sábà máa ń gba àfiyèsí àwọn tí wọ́n bá lọ sọ́ ìhìn Ìjọba náà fún? Ìdí kan ni pé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ lọ́nà rírọrùn tó sì yéni. Àwọn akéde kan lè ronú pé láti jẹ́rìí lọ́nà tó gbéṣẹ́, èèyàn gbọ́dọ̀ lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Ṣùgbọ́n, ìrírí ń fi hàn pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó bá rọrùn lọ́nà tó lè yéni ló dára jù lọ.
2 Jésù pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà rírọrùn tó sì yéni, kò fọ̀rọ̀ lọ́ko lọ́jù, ó sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣe bákan náà. (Mát. 4:17; 10:5-7; Lúùkù 10:1, 9) Ó lo ọ̀nà ìyọsíni tó rọrùn, ó lo ìbéèrè àti àkàwé láti mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ fetí sílẹ̀, kí ó sì dé inú ọkàn wọn. (Jòh. 4:7-14) Á dára ká ṣàfarawé àpẹẹrẹ rẹ̀ kí a sì máa gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó fi lè rọrùn láti yéni.
3 “Ìhìn rere ìjọba” náà ni iṣẹ́ táa ní láti pòkìkí. (Mát. 24:14) Fífi Ìjọba náà ṣe pàtàkì ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ yóò mú kí ọ̀nà tí o ń gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ rọrùn. Sọ nípa àwọn nǹkan tó kan àwọn tó ń fetí sí ọ. Àwọn obìnrin sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ tó bá sọ nípa ìdílé wọn ju èyí tó sọ nípa ìṣèlú. Ẹni tó bá jẹ́ bàbá á fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ rẹ̀ àti ààbò ìdílé rẹ̀. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ mọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wọn; àwọn àgbà sì máa ń fẹ́ jíròrò nípa ìlera tó sunwọ̀n sí i àti ààbò ara wọn. Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣàníyàn nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò wọn ju ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ òkèèrè lọ. Bí o bá ti jíròrò nípa àwọn ọ̀ràn tí ó kan ọ̀pọ̀ èèyàn, darí àfiyèsí sí àwọn ìbùkún tí aráyé onígbọràn yóò gbádùn lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ ṣókí, tó rọrùn láti yéni, tí o sì fara balẹ̀ ṣe àṣàyàn rẹ̀ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lè jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti ru ìfẹ́ ẹni tó ń fetí sí ọ sókè.
4 O lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan nípa sísọ pé:
◼ “Ó dájú pé o máa gbà pé ọ̀pọ̀ àìsàn tí kò gbóògùn ló ń bá aráyé fínra. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa tó mú gbogbo àìsàn àti ikú kúrò?” Jẹ́ kí ó fèsì, lẹ́yìn náà kí o ka Ìṣípayá 21:3, 4.
5 Nípa gbígbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó rọrùn tó sì yéni, kí o sọ̀rọ̀ tí yóò wọ èrò inú àti ọkàn èèyàn púpọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ rẹ, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ nípa Jèhófà àti nípa ìrètí gbígbádùn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 17:3.