Ṣíṣàyẹ̀wò Ìtàn Inú Fídíò The New World Society in Action
Nígbà tí o bá ń wo fídíò tó ṣàgbéyọ fíìmù ọdún 1954 yìí, ronú nípa ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: (1) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe fíìmù yìí jáde nígbà náà lọ́hùn-ún, kí lohun tó sì gbé ṣe? (2) Àwọn ìwé wo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde, àwọn wo ni wọ́n tẹ̀ wọ́n fún, kí sì nìdí tí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n? (3) Báwo ni ìpínkiri ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti rí lóde òní táa bá fi wé ti ọdún 1954? (4) Láwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, báwo ni ọ̀nà táa ń gbà tẹ̀wé ṣe di èyí tí a sọ di ti ìgbàlódé sí i? (5) Kí ló wú ọ lórí nípa àpéjọpọ̀ àgbáyé táa ṣe lọ́dún 1953 ní Pápá Ìṣeré Yankee? (6) Kí ni Trailer City, kì sí làwọn nǹkan títayọ tí o ṣàkíyèsí nípa rẹ̀? (7) Kí ló fi hàn pé iṣẹ́ wa kì í ṣe iṣẹ́ táa ń ṣe ní orílẹ̀-èdè kan péré, pé kì í ṣe àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè kan péré ló ń ṣe é, pé kì í sì í ṣe àwọn ẹ̀yà kan péré ló ń ṣe é? (8) Àwọn ọ̀nà wo lo ti kíyè sí ẹ̀mí ìfẹ́ tí ètò àjọ Jèhófà fi ń ṣiṣẹ́? (Sm. 133:1) (9) Ta lo rò pé yóò mọrírì wíwo ìtàn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ ayé tuntun yìí, èyí tó wáyé láàárín ọdún 1950 sí 1959?