MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ̀mí Mímọ́ Mú Kí Wọ́n Ṣe Iṣẹ́ Tí Kò Rọrùn Láṣeyọrí
Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà ti ń gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe, kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe wọn ló ń mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí, Jèhófà ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Lọ́dún 1954, ètò Ọlọ́run ṣe fídíò The New World Society in Action. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ṣe fídíò yìí ló ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, wọn ò sì ṣe fídíò kankan rí. Iṣẹ́ yìí ò rọrùn lóòótọ́, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Ìyẹn mú kó dá wa lójú pé táwa náà bá gbára lé Jèhófà, àá ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá gbé fún wa.—Sek 4:6.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÁ A ṢE ṢE FÍDÍÒ “THE NEW WORLD SOCIETY IN ACTION,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí nìdí tí ètò Ọlọ́run fi pinnu láti ṣe fídíò nípa iṣẹ́ tá à ń ṣe lóríléeṣẹ́ wa?
Báwo ni fídíò yẹn ṣe fi Bẹ́tẹ́lì wé ẹ̀yà ara wa?—1Kọ 12:14-20
Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n kojú nígbà tí wọ́n ń ṣe fídíò náà, báwo ni wọ́n sì ṣe borí ẹ̀?
Kí ni ìrírí yìí kọ́ wa nípa bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?