ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/02 ojú ìwé 7
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Fọkàn Tán Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 12/02 ojú ìwé 7

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun

1 Láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ nínú ayé tí kò dúró sójú kan yìí, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọ̀nà wo la lè gbà fi ìgbẹ́kẹ̀lé yìí hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́? Báwo ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà ṣe kan ìgbésí ayé wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ti ìdílé wa? Báwo ni èyí ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ kí ayé Sátánì má bàa nípa lórí wa? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká ti ọdún 2003 yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kí O sì Máa Ṣe Rere.”—Sm. 37:3.

2 Kì í ṣe láwọn àkókò kan pàtó tàbí láwọn ìgbà tí nǹkan bá nira fún wa nìkan ló yẹ ká máa fi ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà hàn. Ó kan ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Èyí ni a óò jíròrò nínú àsọyé àkọ́kọ́ tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Gbẹ́kẹ̀ Rẹ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo.” (Sm. 62:8) Àsọyé alápá mẹ́rin tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Fífi Ìgbẹ́kẹ̀lé Tá A Ní Nínú Jèhófà Hàn,” yóò jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè ṣàwárí àwọn ìsọfúnni tá a gbé ka Bíbélì àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò, èyí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìgbéyàwó wa kẹ́sẹ járí, láti kápá àwọn ìṣòro tó ń dìde nínú ìdílé, àti láti bójú tó àwọn ohun tá a nílò nípa tara.

3 Ayé Sátánì ń gbìyànjú láti fipá darí wa láti ní èrò òdì nípa ohun tó dára àti ohun tó burú, ó sì ń mú kó ṣòro láti mọ ohun tó yẹ ká fi sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa. (Aísá. 5:20) Àwọn àsọyé tó ní ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Yàgò fún Àwọn Ohun Asán Tó Wà Nínú Ìgbésí Ayé” àti “Ẹ Yàgò Fún Ohun Búburú—Ẹ Jẹ́ Olùṣe Ohun Rere,” yóò túbọ̀ fún ìpinnu wa láti rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà gíga Jèhófà lágbára.—Ámósì 5:14.

4 Nígbà tí Jèhófà bá mú òpin wá sórí ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí, yóò pọn dandan fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti gbẹ́kẹ̀ lé e ní kíkún. Èyí ni ohun tí a óò ṣàlàyé kúnnákúnná nínú àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Ìdáǹdè Kúrò Nínú Wàhálà Ayé Ti Sún Mọ́lé.” Lẹ́yìn èyí, a ó rọ̀ wá láti yẹ ara wa wò nínú apá tó sọ pé, “Ǹjẹ́ A Óò Kà Ọ́ Yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run?” Àsọyé kan tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú la ó fi parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà.”

5 Àsọyé ìrìbọmi jẹ́ ohun pàtàkì kan tó máa ń wáyé ní gbogbo àpéjọ. Kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága láìfi àkókò ṣòfò, kó bàa lè tètè ṣe àwọn ètò yíyẹ.

6 Ní àwọn àkókò tí kò dáni lójú yìí, Jèhófà nìkan ṣoṣo ni orísun tòótọ́ fún ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìfọ̀kànbalẹ̀. (Sm. 118:8, 9) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa mú ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ lágbára sí i nípa wíwà níbẹ̀ láti gbádùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́