ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/02 ojú ìwé 4
  • Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ní Ìṣọ̀kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ní Ìṣọ̀kan
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣọ̀kan Àwa Kristẹni Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • “Jèhófà Kan Ṣoṣo” Ń kó Ìdílé Rẹ̀ Jọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Báwo Lo Ṣe Lè Pa Kún Ìṣọ̀kan Tó Wà Láàárín Àwa Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 7/02 ojú ìwé 4

Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ní Ìṣọ̀kan

1 Báwo ni ọ̀nà àgbàyanu tí a gbà dá ara ẹ̀dá èèyàn ṣe sábà máa ń yà ọ́ lẹ́nu tó? (Sáàmù 139:14) Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀yà ara ló ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn mìíràn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ìjọ Kristẹni wé ara kan tí gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Lábẹ́ Orí náà, Kristi, gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ni a ‘so pọ̀ ní ìṣọ̀kan tí a sì mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò.’ (Éfé. 4:16a) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti lo àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà ní ìṣọ̀kan láti máa gbé àwọn nǹkan àgbàyanu ṣe.

2 Àwọn tó jẹ́ ara ìjọ ọ̀rúndún kìíní ṣiṣẹ́ “pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan” bí wọ́n ti ń bójú tó àwọn ohun tí ẹnì kìíní-kejì wọn ṣaláìní nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Ìṣe 2:44-47) Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, wọ́n fìmọ̀ ṣọ̀kan bí wọ́n ti ń kojú àwọn àtakò gbígbóná janjan tí wọ́n sì ń borí wọn. (Ìṣe 4:24-31) Wọ́n ń polongo ìhìn Ìjọba náà níbikíbi tí wọ́n bá lọ, wọ́n sì wàásù ìhìn rere náà dé apá ibi tí ayé gbòòrò dé nígbà yẹn. (Kól. 1:23) Lóde òní, ìjọ Kristẹni tó fìmọ̀ ṣọ̀kan ń ṣe irú àwọn ohun kan náà lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò gan-an. Kí làwọn ohun tó mú kí ìṣọ̀kan yìí ṣeé ṣe?

3 Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ń Mú Ká Wà Ní Ìṣọ̀kan: Jákèjádò ayé, ìjọsìn wa ń mú ká wà ní ìṣọ̀kan. Báwo lèyí ṣe ṣeé ṣe? A mọ ọ̀nà tó ṣeé fojú rí tí Jèhófà ń lò láti pèsè ‘oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ (Mát. 24:45) A tún mọyì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” tí Ó ti pèsè gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ nínú ìjọ. Bá a ṣe ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìṣètò tí Jèhófà ṣe láti bọ́ wa nípa tẹ̀mí, òye wa nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pọ̀ sí i, èyí sì ń jẹ́ ká ní irú ìfẹ́ àtọkànwá kan náà láti fara wé Jésù gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. A ní láti máa tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa fi tọkàntọkàn sapá láti “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.” (Éfé. 4:8, 11-13) Ṣé ò ń gbé ìṣọ̀kan tẹ̀mí wa lárugẹ nípa kíka Bíbélì lójoojúmọ́?

4 Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni Ń Mú Ká Wà Ní Ìṣọ̀kan: Ìfẹ́ ló ń jẹ́ ká lè kẹ́gbẹ́ pọ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni. Láwọn ìpàdé wọ̀nyí, a máa ń “gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì.” (Héb. 10:24, 25) Èyí ń béèrè pé a ò kàn ní máa wo ìrísí òde ara àwọn arákùnrin wa nìkan, ṣùgbọ́n àá máa gbìyànjú ní ti gidi láti mọ̀ wọ́n dunjú, ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n ni a ó sì máa fi wò wọ́n, ìyẹn ni pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣeyebíye. (Hag. 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.) Bá a ṣe ń fetí sílẹ̀ sí àwọn ìdáhùn wọn tó fi ìgbàgbọ́ hàn, ìfẹ́ tá a ní fún wọn ń jinlẹ̀ sí i, èyí sì ń jẹ́ ká túbọ̀ wà ní ìṣọ̀kan. Ṣé àwọn ará mọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó máa ń pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé?

5 Àwọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù: Wíwàásù ìhìn rere pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa ń mú ká wà ní ìṣọ̀kan bá a ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì àwọn ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ fún ìjọba Ọlọ́run.’ (Kól. 4:11) Ṣíṣàjọpín ìrírí àti ṣíṣèrànwọ́ fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nígbà tá a bá wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tá a yàn fún àwa Kristẹni, ó sì ń fún ìdè ìṣọ̀kan wa lókun.—Kól. 3:14.

6 Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Mú Wa Ṣọ̀kan: Bá a ṣe ń fi tọkàntara ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ó ń fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. Èyí ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú èdèkòyedè, ká sì máa bá ara wa gbé ní ìṣọ̀kan. (Sm. 133:1) Ó ń sún wa “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Kálukú wa lè fi kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run nípa fífi àwọn èso tẹ̀mí ṣèwà hù nínú àjọṣe wa pẹ̀lú ẹnì kìíní-kejì.—Gál. 5:22, 23.

7 Sísìn pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan lábẹ́ ipò orí Kristi “ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.” (Éfé. 4:16b) Láfikún sí i, ó ń fògo fún Jèhófà, “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà.”—Róòmù 16:20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́