Fi Ìdúróṣinṣin Kristẹni Hàn Nígbà Tí Ìbátan Rẹ Kan Bá Di Ẹni Tí A Yọ Lẹ́gbẹ́
1. Ipò wo ló lè dán ìdúróṣinṣin Kristẹni kan wò?
1 Ìdè tó wà láàárín àwọn ìbátan máa ń lágbára gan-an. Èyí máa ń fi Kristẹni kan sínú ìdánwò nígbà tí ọkọ tàbí aya, ọmọ, òbí tàbí ẹbí ẹni kan tó sún mọ́ni bá di ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí ẹni náà fúnra rẹ̀ yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. (Mát. 10:37) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn Kristẹni adúróṣinṣin bá irú ìbátan bẹ́ẹ̀ lò? Ṣé ó yẹ kí ọ̀nà tí wàá gbà bá ẹni náà lò yàtọ̀, bó bá jẹ́ inú ilé kan náà ni ìwọ àti ẹni náà ń gbé? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí, ìyẹn àwọn ìlànà tó kan àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ àtàwọn tó fúnra wọn yọ ara wọn kúrò nínú ìjọ.
2. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, báwo làwọn Kristẹni ṣe gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tá a ti yọ kúrò nínú ìjọ lò?
2 Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Bá Àwọn Tá A Yọ Lẹ́gbẹ́ Lò: Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa á láṣẹ fún àwọn Kristẹni láti má ṣe bá ẹni tá a ti yọ kúrò nínú ìjọ kẹ́gbẹ́ tàbí ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun. . . . Ẹ mú ènìyàn burúkú náà kúrò láàárín ara yín.” (1 Kọ́r. 5:11, 13) Orí kókó yìí kan náà ni ọ̀rọ̀ Jésù nínú Mátíù 18:17 dá lé, èyí tó sọ pé: “Jẹ́ kí [ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ náà] rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Àwọn olùgbọ́ Jésù mọ̀ pé kò sí nǹkan kan tó pa àwọn Júù ayé ìgbà yẹn àtàwọn Kèfèrí pọ̀, ńṣe ni wọ́n sì máa ń pa àwọn agbowó orí tì bí ẹni tí kò bẹ́gbẹ́ mu. Jésù ń tipa báyìí kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti má ṣe bá àwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ kẹ́gbẹ́.—Wo Ile-iṣọ Naa ti January 15, 1982, ojú ìwé 18 sí 20.
3, 4. Irú ìbákẹ́gbẹ́ wo ni kò bófin mu pẹ̀lú ẹnì kan tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tó fúnra rẹ̀ yọ ara rẹ̀ kúrò nínú ìjọ?
3 Èyí túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin kì í ní àjọṣe tẹ̀mí pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tá a bá ti yọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò mọ síbẹ̀ o. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé a ‘kò tilẹ̀ gbọ́dọ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.’ (1 Kọ́r. 5:11) Nítorí náà, a tún gbọ́dọ̀ yẹra fún bíbá ẹni tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ ṣe wọléwọ̀de. Èyí á fagi lé bíbá ẹni náà jáde fàájì, bíbá a wà níbi àríyá, lílọ ṣe eré ìdárayá pa pọ̀, jíjọ lọ ra nǹkan lọ́jà, tàbí lílọ wo sinimá pa pọ̀ tàbí bíbá a jẹun, yálà nínú ilé tàbí nílé àrójẹ.
4 Ti bíbá ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ sọ̀rọ̀ ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ gbogbo onírúurú ipò tó lè dìde, 2 Jòhánù 10 ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ojú tí Jèhófà fi wo ọ̀ràn yìí, ó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá wá sọ́dọ̀ yín, tí kò sì mú ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé yín láé tàbí kí ẹ kí i.” Nígbà tí Ile-iṣọ Naa ti January 15, 1982, lójú ìwé 24, ń ṣàlàyé lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ó sọ pé: “Kìkì ‘Bawo ni o’ ti a sọ si ẹnikan le jẹ igbesẹ akọkọ ti yoo dagbasoke di ijumọsọrọpọ ati boya ibadọrẹ pàápàá. Awa yoo ha fẹ lati gbe igbesẹ akọkọ nì pẹlu ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ bi?”
5. Nígbà tá a bá yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́, kí lonítọ̀hún pàdánù?
5 Láìsí àní-àní, èyí ṣe gẹ́lẹ́ pẹ̀lú ohun tí ìtẹ̀jáde Ile-iṣọ Naa yìí kan náà sọ ní ojú ìwé 30 pé: “Otitọ naa ni pe nigba ti Kristian kan ba fi ara rẹ̀ fun ẹṣẹ ti o si di dandan pe ki a yọ ọ lẹgbẹ, oun padanu ohun pupọ: ibatan rere rẹ̀ pẹlu Ọlọrun; . . . ibakẹgbẹ alarinrin pẹlu awọn arakunrin, ati pupọ julọ ninu ibakẹgbẹ ti oun ti ni pẹlu awọn ibatan rẹ̀ ti wọn jẹ Kristian.”
6. Ǹjẹ́ a béèrè lọ́wọ́ Kristẹni kan láti má ṣe ní nǹkan kan ṣe rárá àti rárá pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ kan tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tí wọ́n jọ ń gbénú ilé kan náà? Ṣàlàyé.
6 Láàárín Àwọn Ìbátan Tó Jọ Ń Gbé Pọ̀: Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn Kristẹni tí wọ́n ń gbé inú ilé kan náà pẹ̀lú ẹni tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ kò wá ní sọ̀rọ̀, jẹun tàbí kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹni yẹn ni, bí wọ́n ti ń ṣe àwọn ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́? Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, nínú àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, ní ojú ìwé 22, sọ pé: “Bi o ba ṣẹlẹ pe ninu agbo idile Kristian kan ibatan kan wà ti a ti yọ lẹgbẹ, ẹni yẹn sibẹ yoo ṣì jẹ apakan awọn ajọṣepọ ati igbokegbodo ti a nṣe deedee lati ọjọ de ọjọ ninu agbo ile naa.” Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn yòókù nínú agbo ilé náà ló máa pinnu ibí tí àwọn máa gba ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ náà láyè dé nígbà oúnjẹ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ inú ilé mìíràn tó lè mú wọn wà pa pọ̀. Síbẹ̀, wọn kò ní jẹ́ kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá ẹni tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ náà lò mú káwọn ará tí wọ́n jọ ń dara pọ̀ máa ronú pé kò sí ìyàtọ̀ kankan láàárín ìgbà tí wọn ò tíì yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́ àtìgbà tí wọ́n ti yọ ọ́ lẹ́gbẹ́.
7. Báwo ni àjọṣe tẹ̀mí nínú ilé á ṣe yí padà nígbà tí a bá yọ ẹnì kan tó jẹ́ ara ìdílé lẹ́gbẹ́?
7 Bó ti wù kó rí, Ile-iṣọ Naa ti January 15 1982, ojú ìwé 27 sọ nípa ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tó fúnra rẹ̀ yọ ara rẹ̀ lẹ́gbẹ́ pé: “Awọn isopọ ti ẹmi ti o ti wà tẹlẹri li a ti já patapata. Eyii jẹ otitọ ani pẹlu awọn ibatan rẹ̀ paapaa, ati awọn wọnni ti o wà nínú idile rẹ̀ ti o sunmọ ọn julọ. . . . Eyiini yoo tumọsi awọn iyipada ninu ibakẹgbẹpọ ti ẹmi ti o ti le wà ninu idile. Fun apẹẹrẹ, bi ọkọ ba di ẹni ti a yọ lẹgbẹ, iyawo rẹ̀ ati awọn ọmọ rẹ̀ ki yoo ni itura pẹlu rẹ̀ lati maa dari ikẹ́kọ̀ọ́ Bibeli idile tabi ṣiṣaaju wọn ninu Bibeli kika tabi adura. Bi oun ba fẹ lati gbà adura, iru bi ni igba ounjẹ, oun ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ ninu ile ti ara rẹ̀. Ṣugbọn awọn le fi pẹlu idakẹjẹẹ gba adura tiwọn si Ọlọrun. (Owe 28:9; Orin Da. 119:145, 146) Kinni bi o ba ṣẹlẹ pe ẹnikan ti a ti yọ lẹgbẹ ninu ile fẹ lati wà nibẹ nigba ti idile naa ba nka Bibeli papọ tabi ti wọn nṣe ikẹkọọ Bibeli? Awọn iyoku le yọọda fun un lati wà nibẹ lati fetisilẹ bi oun ki yoo ba gbiyanju lati kọ wọn tabi ṣe ajọpin awọn ero rẹ̀ nipa isin.”
8. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni òbí ní lórí ọmọ aláìtójúúbọ́ kan tó ń bá wọn gbé àmọ́ tó ti di ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́?
8 Bí ọmọ aláìtójúúbọ́ kan tó ń gbé nílé bá di ẹni tá a yọ lẹ́gbẹ́, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni náà ló ṣì ni ẹrù iṣẹ́ láti tọ́ ọ. Ilé-Ìṣọ́nà ti November 15, 1988, ojú ìwé 20 sọ pé: “Gan-an gẹgẹbi wọn yoo ti maa baa-lọ lati maa pèsè ounjẹ, aṣọ-àgbéwọ̀, ati ibi-ààbò fun un, ó jẹ́ ọ̀ranyàn fun wọn lati fun un ní ìtọ́ni kí wọn sì bá a wí ní ìlà pẹlu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Owe 6:20-22; 29:17) Awọn òbí onífẹ̀ẹ́ lè tipa bayii ṣètò lati ṣe ìbaralẹ̀-kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé pẹlu rẹ̀, kódà bí a bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ó lè jẹ́ pe oun yoo rí èrè-àǹfààní atọ́nisọ́nà julọ fàyọ lati inú ìbaralẹ̀-kẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ṣe pẹlu oun nikanṣoṣo. Tabi wọn lè pinnu pe oun lè maa baa lọ lati ṣàjọpín ninu ìṣètò ìbaralẹ̀-kẹ́kọ̀ọ́ idile.”—Tún Wo Ilé Ìṣọ́ October 1, 2001, ojú ìwé 16 àti 17.
9. Ibo ló yẹ kí Kristẹni kan fi àjọṣe àárín òun àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ tí wọn ò jọ gbé pọ̀ mọ sí?
9 Àwọn Mọ̀lẹ́bí Tí Wọn Ò Jọ Gbé Pa Pọ̀: Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1988, ojú ìwé 28 sọ pé: “Ipo-ọran naa yatọ bí ẹni tí a yọlẹgbẹ naa tabi tí ó mú araarẹ̀ kuro lẹgbẹ ba jẹ́ ibatan kan tí ngbe ní ẹhin-ode agbo idile ati ile ẹni funraẹni. Ó lè ṣeeṣe lati fẹrẹẹ má ni ibatan-ibaraṣepọ kankan rara pẹlu ibatan naa. Koda bí awọn koko-ọran idile kan bá wà tí ó nbeere fun ajumọsọrọpọ, iwọnyi dajudaju ni a o fi mọ ní iwọnba,” níbàámu pẹ̀lú àṣẹ àtọ̀runwá náà láti “jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni” tó bá ṣẹ̀ láìronúpìwàdà. (1 Kọ́r. 5:11) Àwọn Kristẹni adúróṣinṣin gbọ́dọ̀ sapá láti yẹra fún àjọṣe tí kò pọn dandan pẹ̀lú irú mọ̀lẹ́bí bẹ́ẹ̀, kódà bíbá irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣòwò pọ̀ la gbọ́dọ̀ fi mọ sí ìwọ̀n tó kéré jù lọ.—Tún wo Ile-iṣọ Naa ti January 15 1982, ojú ìwé 29 àti 30.
10, 11. Kí ni Kristẹni kan máa gbé yẹ̀ wò kó tó lè gbà kí ẹbí rẹ̀ kan tá a yọ lẹ́gbẹ́ wá máa bá òun gbé?
10 Ìtẹ̀jáde Ile-iṣọ Naa tún pe àfiyèsí wa sí ipò mìíràn tó lè dìde, ó béèrè pé: “Ṣugbọn kinni bi o ba ṣẹlẹ pe ibatan timọtimọ kan, iru bi ọmọ kan tabi obi kan ti kii gbe ile naa ba di ẹni ti a yọ lẹgbẹ ati lẹhin naa ti o fẹ́ lati kó pada wá si ibẹ? Idile naa le pinnu ohun ti wọn yoo ṣe o sinmi lori bi ipo naa ba ṣe ri. Fun apẹẹrẹ, obi kan ti a ti yọ lẹgbẹ le ṣaisan tabi ki o má lagbara lati bojuto ara rẹ̀ mọ́ nipa iṣuna owó tabi nipa ti ara. Awọn ọmọ Kristian naa wà labẹ ẹru-iṣẹ Iwe Mimọ ati ti iwa rere lati ṣe iranlọwọ. (1 Tim. 5:8) . . . Ohun ti a ṣe le sinmi lori awọn koko bii awọn ohun ti o jẹ aini obi naa ni tootọ, iṣarasi rẹ̀ ati ọ̀wọ̀ ti olori idile naa ni fun ire ti ẹmi idile naa.”—Ile-iṣọ Naa ti January 15 1982, ojú ìwé 28.
11 Tó bá jẹ́ ọmọ ni, àpilẹ̀kọ náà ń bá a nìṣó pé: “Awọn igba ti wà ti awọn obi Kristian ti tẹwọgba ọmọ kan ti a ti yọ lẹgbẹ pada sinu ile fun akoko kan ẹni ti o ti di alailera nipa ti ara tabi nipa ti imi-ẹdun. Ṣugbọn ninu ọran eyikeyii awọn obi nilati diwọn awọn ipo ti o yí ọkọọkan ká. Ọmọ kan ti a yọ lẹgbẹ ha ti ndagbe funrarẹ̀, ati nisinsinyii oun ko ha tun le ṣe bẹẹ mọ bi? Tabi oun ha fẹ lati kó pada wá kìkì nitori pe yoo jẹ igbesi aye ti o tubọ rọrun? Kinni nipa ti awọn iṣarasi rẹ̀ ati awọn iwa rẹ̀? Yoo ha mu ‘iwukara’ wọ inu ile naa bi?—Gal. 5:9.”
12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí ìṣètò ìyọlẹ́gbẹ́ ní?
12 Àwọn Àǹfààní Jíjẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà: Fífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Ìwé Mímọ́ pé ká yọ àwọn tó ṣẹ̀ tí wọn ò sì ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́, àti pé ká má ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́ ṣàǹfààní. Ó ń jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní ó sì ń fi wá hàn yàtọ̀ pé a jẹ́ ẹni tó ń rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà ìwà rere gíga ti Bíbélì. (1 Pét. 1:14-16) Ó ń dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè kó èérí bá wa. (Gál. 5:7-9) Ó tún ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹlẹ́ṣẹ̀ náà láti jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìbáwí tó ń gbà yẹn, èyí tó lè ràn án lọ́wọ́ láti so “èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.”—Héb. 12:11.
13. Àtúnṣe wo ni ìdílé kan ṣe, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
13 Lẹ́yìn tí arákùnrin kan àti arábìnrin rẹ̀ gbọ́ àsọyé kan ní àpéjọ àyíká kan, wọ́n rí i pé ó pọn dandan kí àwọn yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá ìyá wọn lò padà, ẹni tí wọ́n ti yọ lẹ́gbẹ́ láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn tó sì ń gbé níbòmíràn. Gbàrà tí àpéjọ náà parí, arákùnrin náà pe màmá rẹ̀, lẹ́yìn tó sì ti jẹ́ kó mọ̀ pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó ṣàlàyé pé àwọn ò ní lè máa bá a sọ̀rọ̀ mọ́ àfi tí àwọn ọ̀ràn kan tó ṣe pàtàkì nínú ìdílé bá yọjú, èyí tó máa mú kó pọn dandan pé kí àwọn jọ sọ̀rọ̀. Láìpẹ́ sígbà náà, màmá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé ó sì di ẹni tá a gbà padà nígbà tó yá. Bákan náà, ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà.
14. Ìdí wo ló fi yẹ ká fi ìdúróṣinṣin rọ̀ mọ́ ìṣètò ìyọlẹ́gbẹ́?
14 Fífi ìdúróṣinṣin rọ̀ mọ́ ìṣètò ìyọlẹ́gbẹ́ tí Ìwé Mímọ́ là lẹ́sẹẹsẹ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ń jẹ́ kó lè dá ẹni náà tó ń ṣáátá Rẹ̀ lóhùn. (Òwe 27:11) Èyí ẹ̀wẹ̀ á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìdánilójú ìbùkún Jèhófà. Ọba Dáfídì kọ̀wé nípa Jèhófà pé: “Ní ti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀, èmi kì yóò yapa kúrò nínú wọn. Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”—2 Sám. 22:23, 26.