Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Yin Jèhófà Lógo
1 Ìhìn pàtàkì kan wà tí à ń polongo jákèjádò ayé. Ìhìn náà ni: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé, nítorí náà, ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti àwọn ìsun omi.” (Ìṣí. 14:6, 7) A láǹfààní láti máa kópa nínú pípolongo ìhìn yìí. Kí ló yẹ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà kí wọ́n lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì máa jọ́sìn rẹ̀?
2 Orúkọ Rẹ̀: Ó yẹ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, kí wọ́n lè fi ìyàtọ̀ sáàárín òun àti ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́run èké tí wọ́n ń jọ́sìn lónìí. (Diu. 4:35; 1 Kọ́r. 8:5, 6) Ká sòótọ́, àwọn tó kọ Bíbélì lo orúkọ ọlọ́lá ńlá Jèhófà ní iye ìgbà tó ju ẹgbẹ̀rún méje lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká lo ìfòyemọ̀ ní ti ìgbà tá a máa sọ orúkọ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, a kò gbọ́dọ̀ fi pa mọ́ fún wọn tàbí ká kùnà láti lò ó. Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo ìran èèyàn mọ orúkọ òun.—Sm. 83:18.
3 Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀: Láti yin Jèhófà lógo, ó yẹ káwọn èèyàn mọ irú Ọlọ́run tó jẹ́. A ní láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó ní ìfẹ́ títayọ, ọgbọ́n tó ga jù lọ, ìdájọ́ òdodo tó pé pérépéré, àti agbára tó ju gbogbo agbára lọ, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àánú rẹ̀, inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àtàwọn ànímọ́ àgbàyanu mìíràn tó ní. (Ẹ́kís. 34:6, 7) Wọ́n tún ní láti mọ bí wọ́n ṣe lè ní ìbẹ̀rù àtọkànwá fún Ọlọ́run, àti bí wọ́n ṣe lè máa fi ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ hàn fún un, kí wọ́n sì mọ̀ pé ìwàláàyè wọn sinmi lórí rírí ojú rere Jèhófà.—Sm. 89:7.
4 Sísúnmọ́ Ọlọ́run: Bí àwọn èèyàn bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbà wọ́n là nígbà ìdájọ́ rẹ̀ tó ń bọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Jèhófà. (Róòmù 10:13, 14; 2 Tẹs. 1:8) Èyí kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn mímọ orúkọ Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ nìkan. A ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e. (Òwe 3:5, 6) Bí wọ́n bá ṣe ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò, tí wọ́n ń gba àdúrà àtọkànwá sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń rí ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fún wọn nínú ìgbésí ayé wọn, ìgbàgbọ́ wọn yóò pọ̀ sí i, wọ́n á sì lè sún mọ́ Jèhófà.—Sm. 34:8.
5 Ẹ jẹ́ ká máa fi tìtaratìtara polongo orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti fi gbogbo ọkàn wọn gbẹ́kẹ̀ lé e, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ̀. A ṣì láǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn sí i lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa yìn ín lógo gẹ́gẹ́ bí “Ọlọ́run ìgbàlà” wọn.—Sm. 25:5.