Jíjàǹfààní Ní Kíkún Látinú Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run”
1 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tí Ń Tani Jí: Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń tani jí mà ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a gbádùn ní àpéjọ àgbègbè wa àìpẹ́ yìí o! Ète kan ló mú gbogbo wa kóra jọ, ìyẹn ni láti di ẹni tá a túbọ̀ mú gbára dì dáadáa láti máa fi ìtara polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ o rántí bí ẹni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ ṣe ṣàlàyé gbólóhùn náà, “láti polongo”? Ǹjẹ́ o rántí ìwádìí tá a rọ̀ wá láti ṣe nínú àsọyé tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “Ẹ Má Bẹ̀rù Nítorí Tí Jèhófà Wà Pẹ̀lú Wa”? Ìtàn ìgbésí ayé ta ni o ti gbé yẹ̀ wò látìgbà náà wá?
2 Àpínsọ àsọyé náà, “Onírúurú Àdánwò Ń Dán Bí Ìgbàgbọ́ Wa Ṣe Jẹ́ Ojúlówó Tó Wò” ṣàlàyé àwọn ìdí mẹ́ta pàtàkì tí Jèhófà fi ń gba inúnibíni láyè láti máa ṣẹlẹ̀. Ṣé o lè sọ àwọn ohun tí wọ́n jẹ́? Ìpìlẹ̀ Ìwé Mímọ́ wo la ní fún jíjẹ́ tá a jẹ́ Kristẹni tí kì í dá sí tọ̀tún-tòsì? Kí la rọ̀ wá láti ṣe ní ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ìṣòro tó máa ń dìde nítorí ipò tá a dì mú gẹ́gẹ́ bí aláìdásí tọ̀tún-tòsì? Báwo ni fífi ìṣòtítọ́ fara da àdánwò ṣe ń mú ìyìn bá Jèhófà?
3 Àwọn ìran wo nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Dúró Gbọn-in ní Àkókò Ìṣòro” ló fún ọ lókun gan-an? Báwo la ṣe lè dà bí Jeremáyà?
4 Nínú àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé, “Ìrísí Ìran Ayé Yìí Ń Yí Padà,” àwọn ìyípadà gbankọgbì tó ń bẹ níwájú wo ló máa wáyé ní kété ṣáájú ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù Ọlọ́run? Bó o ti ń tẹ́tí sí àsọyé tó kẹ́yìn náà, “Ẹ̀yin Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, Ẹ Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Àtàtà Yín Máa Pọ̀ Sí I,” ọ̀nà wo lo rò pé ìsọfúnni náà á gbà wúlò fún ọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
5 Àwọn Kókó Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fi Sílò: Gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ ti ṣàlàyé nínú àsọyé náà, “Ẹ Máa Kún fún Ọpẹ́,” ọ̀nà wo la lè gbà fi ìmọrírì àtọkànwá wa hàn sí Jèhófà? Nínú lájorí àsọyé náà, “A Mú Ìtara Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run Jó Lala,” ẹni wo la rọ̀ wá pé ká fara wé ìtara rẹ̀? Àyẹ̀wò ara ẹni wo la ní ká ṣe?
6 Nínú àpínsọ àsọyé náà “Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà Ń fún Wa Lókun Láti Máa Rìn ní Orúkọ Jèhófà,” àwọn ohun mẹ́ta wo ni a fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè rí ojú rere Jèhófà? Ǹjẹ́ agbára wa gbé e láti ṣe àwọn ohun náà? (Míkà 6:8) Níbàámu pẹ̀lú àsọyé náà, “Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nípa Dídáàbò Bo Ọkàn Rẹ,” àwọn ọ̀nà wo la gbọ́dọ̀ gbà jẹ́ oníwà mímọ́? Àwọn àgbègbè wo ni àsọyé náà, “Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn” ti fún wa ní ìkìlọ̀ ká má bàa di ẹni tí a tàn jẹ, kí àwa náà má sì di ẹni tó ń tan àwọn mìíràn jẹ?
7 Àwọn kókó tó wúlò wo nínú àpínsọ àsọyé náà, “Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Tí Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wọn Lógo,” lo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Nínú àsọyé náà, “Fífọ̀rọ̀wérọ̀ Nípa Nǹkan Tẹ̀mí Ń Gbéni Ró,” a ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ Fílípì 4:8. Báwo ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa jẹ́ èyí tá a gbé ka àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìgbà wo ló sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
8 Àsọyé náà “Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá Lákòókò Ìpọ́njú” jíròrò bí a ṣe lè fara da àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń kó ìbànújẹ́ báni, àìrówóná, àìsàn, ìṣòro ìdílé, àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa tí kò lọ bọ̀rọ̀? Báwo la ṣe lè fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà hàn nígbà tá a bá ń dojú kọ àwọn àdánwò wọ̀nyí?
9 Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí Tuntun: Inú wa dùn gan-an láti gbọ́ nípa ìmújáde ìwé tuntun náà, Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. Ipa wo ni ìfilọ̀ tó sọ ète tá a fi mú ìwé náà jáde ni lórí rẹ? Kí nìdí tí ìwé náà fi máa ṣèrànwọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí à ń ṣe?
10 Lẹ́yìn èyí la tún gbọ́ nípa ìmújáde ìwé ẹlẹ́wà náà, Sún Mọ́ Jèhófà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun pàtàkì tó ní nínú? Ta ló lè jàǹfààní nínú rẹ̀?
11 Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” ti fún wa ní ìṣírí tẹ̀mí tá a nílò láti kojú àwọn àkókò líle koko yìí. Ká lè jàǹfààní ní kíkún látinú ìpèsè tẹ̀mí tó jíire náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti máa rántí àwọn ohun tá a gbọ́ níbẹ̀, ká máa fi ìmọrírì hàn fún ohun tá a rí gbà, ká sì máa fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò. (2 Pét. 3:14) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fún wa lókun láti máa bá a lọ ní pípa ìwà títọ́ wa mọ́, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tó ń fi ìtara pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ní àfarawé Olúwa wa, Jésù Kristi, tí gbogbo èyí yóò sì jẹ́ fún ògo Jèhófà.—Fílí. 1:9-11.