Polongo Ìhìn Ìjọba Náà
1 “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run . . . , nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹṣin ọ̀rọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀—ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run. Orí Ìjọba yìí ni ìhìn tí àwa náà ń polongo lónìí dá lé, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 24:14 pé: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Àwọn òtítọ́ wo nípa Ìjọba Ọlọ́run ló yẹ káwọn èèyàn gbọ́?
2 Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lọ́run báyìí, láìpẹ́ ni yóò sì rọ́pò gbogbo ìṣàkóso èèyàn. Lọ́wọ́lọ́wọ́, a ti lé Èṣù jáde kúrò ní ọ̀run, ètò nǹkan búburú ìsinsìnyí sì ti wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn rẹ̀. (Ìṣí. 12:10, 12) Ètò nǹkan búburú Sátánì tó ti di ògbólógbòó yìí ni a óò pa run yán-ányán-án, àmọ́ mìmì kan ò ní mi Ìjọba Ọlọ́run. Yóò wà títí ayérayé.—Dán. 2:44; Héb. 12:28.
3 Ìjọba náà yóò ṣe àwọn ohun dáradára táwọn ẹ̀dá èèyàn onígbọràn ń fẹ́ fún wọn. Yóò mú àwọn ìṣòro tí ogun, ìwà ọ̀daràn, ìnilára, àti ipò òṣì ń mú wá kúrò. (Sm. 46:8, 9; 72:12-14) Ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ yóò wà fún gbogbo èèyàn. (Sm. 72:16; Aísá. 25:6) Àìsàn àti àléébù ara yóò di ohun ìgbàgbé. (Aísá. 33:24; 35:5, 6) Bí ìran ènìyàn ṣe ń dàgbà lọ sí ìjẹ́pípé, ayé yóò di Párádísè, àwọn èèyàn yóò sì máa gbé pa pọ̀ nínú ìrẹ́pọ̀.—Aísá. 11:6-9.
4 Bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa nísinsìnyí ló máa fi hàn pé a fẹ́ láti jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìhìn Ìjọba náà gbọ́dọ̀ nípa lórí gbogbo apá ìgbésí ayé wa, títí kan àwọn ohun tí à ń lépa àtàwọn ohun tí à ń fi sí ipò àkọ́kọ́. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe wa ni láti pèsè fún ìdílé wa, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àníyàn nípa àwọn nǹkan tara gbà wá lọ́kàn pátápátá tá ò fi ní ráyè fún ire Ìjọba náà. (Mát. 13:22; 1 Tím. 5:8) Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti máa fi ìṣílétí Jésù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí [àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé] ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mát. 6:33.
5 Ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí àwọn èèyàn gbọ́ ìhìn Ìjọba náà kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lé e lórí nígbà tí àkókò ṣì wà. Ǹjẹ́ kí a ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ‘lílo ìyíniléròpadà nípa ìjọba Ọlọ́run.’—Ìṣe 19:8.