Máa Rántí Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Olùṣòtítọ́
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé opó ni Ánà, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin tó sì ti darúgbó gan-an, “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” Ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú kí Jèhófà san èrè pàtàkì fún un. (Lúùkù 2:36-38) Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ló ń fi irú ẹ̀mí tí Ánà ní yìí hàn láìka àwọn ipò tó nira tí wọ́n ń dojú kọ sí. Nígbà tí irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ bá ń dojú kọ àìsàn tàbí tí wọn ò bá lè ṣe àwọn ohun tí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́ nítorí ọjọ́ ogbó, ìrẹ̀wẹ̀sì lè máa dé sí wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ díẹ̀ yẹ̀ wò tá a lè gbà fún wọn níṣìírí tá a sì lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí déédéé.
2 Àwọn Ìpàdé Ìjọ àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Tí àwọn ẹlòmíràn bá fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣètò láti máa gbé àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ wá sípàdé, èyí á jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára wọn láti máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Èyí ń gbé àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ń sìn látọjọ́ pípẹ́ wọ̀nyí ró nípa tẹ̀mí ó sì tún ń ṣe ìjọ pẹ̀lú láǹfààní. Ṣé ìwọ náà máa ń kópa nínú iṣẹ́ àtàtà yìí?—Héb. 13:16.
3 Kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé ń mú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wá fún àwọn Kristẹni tòótọ́. Àmọ́ èyí lè jẹ́ ìṣòro fún àwọn àgbàlagbà àtàwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera. Ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ nínú àwọn apá kan nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí? (Róòmù 16:3, 9, 21) Bóyá o lè ké sí i láti bá ọ kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù tàbí láti bá ọ lọ sí ibi ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan. Bí àgbàlagbà náà kò bá lè jáde nínú ilé rẹ̀, ǹjẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè wá sí ilé ẹni náà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
4 Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀: Látìgbàdégbà, àwọn ará kan máa ń ké sí àgbàlagbà kan tàbí ẹnì kan tó jẹ́ aláìlera láti wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn, wọ́n tiẹ̀ lè ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ní ilé ẹni náà pàápàá. Ìyá kan kó àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké méjì lọ sílé arábìnrin àgbàlagbà kan láti lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn nínú Iwe Itan Bibeli Mi, gbogbo wọn ló sì rí ìṣírí gbà látinú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ náà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tún máa ń gbádùn rẹ̀ tá a bá ké sí wọn láti wá bá wa jẹun pọ̀ tàbí tá a pè wọ́n síbi àpèjẹ kan. Bí àwọn aláìlera kò bá lágbára láti gbàlejò fún àkókò gígùn, bóyá o lè pè wọ́n lórí tẹlifóònù tàbí kó o yà wò wọ́n fírí láti kàwé fún wọn, láti gbàdúrà pẹ̀lú wọn, tàbí láti sọ ìrírí kan tó lè gbé wọn ró.—Róòmù 1:11, 12.
5 Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. (Héb. 6:10, 11) A lè fara wé e nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọrírì wọn àti nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí déédéé.