Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 9
Orin 193
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ December 15 lọni.
15 min: “Polongo Ìhìn Ìjọba Náà.”a Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, mẹ́nu kan àwọn àbá tó ń fi hàn bí a ṣe lè ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì jáde tààràtà nígbà tá a bá ń sọ ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn.—km-YR 12/01 ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 3.
18 min: Máa Tẹ̀ Síwájú Nínú Gbogbo Iṣẹ́ Rere. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí alàgbà kan bójú tó o. Ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn ìjọ yín àti ìtẹ̀síwájú tó ti wáyé, àtàwọn ìsapá tó wá yọrí sí dídá ìjọ náà sílẹ̀. Ṣètò ṣáájú fún àwọn kan tí wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí a dá ìjọ náà sílẹ̀ láti sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró. Sọ àwọn ohun tó ń fi hàn pé ìbísí ṣì máa wà sí i, kó o sì rọ gbogbo àwọn ará láti máa fi ìtara ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìgbòkègbodò ìjọ.
Orin 119 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ tó Bẹ̀rẹ̀ Ní December 16
Orin 29
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Sọ àwọn àkànṣe ètò tó wà fún ìjẹ́rìí ní December 25 àti ní January 1.
15 min: Àwọn Tó Ní Ìjìnlẹ̀ Òye Yóò Lóye. (Dán. 12:3, 10) Àṣefihàn. Olùfìfẹ́hàn béèrè pé: “Báwo ló ṣe lè dá mi lójú pé ẹ ní òye tó tọ̀nà nípa àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni?” Akéde ṣàlàyé bí a ṣe lè lo àkòrí ọ̀rọ̀ kan láti fi ṣèwádìí kókó kan tí a fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. (w96-YR 5/15 ìpínrọ̀ 19 àti 20) Nípa lílo àpẹẹrẹ kan tàbí méjì látinú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ní Ẹ̀kọ́ 5, ó ṣàlàyé pé fífarabalẹ̀ ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló jẹ́ ká lóye ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé. Akéde ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìlànà yìí kan náà láti ní òye tó tọ̀nà nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn, ó sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.
20 min: “Máa Rántí Àwọn Àgbàlagbà Tí Wọ́n Jẹ́ Olùṣòtítọ́.”b Fi àlàyé kún un látinú Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1994, ojú ìwé 29. Mẹ́nu kan ìṣètò tó ti wà báyìí fún àwọn aláìlera láti máa ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá látorí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sókè. Ṣètò kí àwọn bíi mélòó kan sọ àwọn ìrírí tó ń fi hàn bí níní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà ṣe ń mú ayọ̀ wá fún tọ̀tún-tòsì.
Orin 154 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 23
Orin 136
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January 8 lọni. Rọ gbogbo àwọn ará láti wo fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ January 6.
18 min: “Fi Ìdúróṣinṣin Kristẹni Hàn Nígbà Tí Ìbátan Rẹ Kan Bá Di Ẹni Tí A Yọ Lẹ́gbẹ́.”c (Ìpínrọ̀ 1 sí 8) Alàgbà tó dáńgájíá ni kó bójú tó o, kí ó sì lo àwọn ìbéèrè tá a pèsè. Kí ó jẹ́ kí arákùnrin kan tó mọ̀wéé kà dáadáa ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sókè ketekete.
17 min: “Ṣé Ò Ń Ṣe Ipa Tìrẹ Ká Lè Ṣàkójọ Ìròyìn Tó Pé Pérépéré?”d Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, fi àlàyé kún un látinú ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 106 sí 108.
Orin 165 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ Ní December 30
Orin 152
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn fún oṣù December sílẹ̀. Bí ìjọ yín yóò bá yí àkókò tí ẹ ń ṣe ìpàdé padà lọ́dún tuntun, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé déédéé ní àwọn àkókò tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣètò. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù January, kí o sì sọ àwọn ìwé ńlá tí ìjọ ní lọ́wọ́.
15 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun.” Àsọyé. Sọ déètì àpéjọ àyíká yín tó ń bọ̀ lọ́nà. Rọ gbogbo àwọn ará láti wà níbẹ̀ kí wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Fún àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi níṣìírí láti ronú nípa dídi ẹni tó tóótun láti ṣèrìbọmi. Kí a ṣe àkànṣe ìsapá láti ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti wá.
20 min: “Fi Ìdúróṣinṣin Kristẹni Hàn Nígbà Tí Ìbátan Rẹ Kan Bá Di Ẹni Tí A Yọ Lẹ́gbẹ́.”e (Ìpínrọ̀ 9 sí 14) Alàgbà tó dáńgájíá ni kó bójú tó o, kí ó sì lo àwọn ìbéèrè tá a pèsè. Kí o jẹ́ kí arákùnrin kan tó mọ̀wéé kà dáadáa ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sókè ketekete.
Orin 125 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 6
Orin 67
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: Ìrànwọ́ Láti Ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run Lórí Ẹ̀jẹ̀. Àsọyé tí alàgbà kan tó dáńgájíá yóò sọ, èyí tí a gbé ka ìwé àsọyé tí ọ́fíìsì ẹ̀ka pèsè. Kí akọ̀wé rí i pé káàdì Medical Directive/Release àti Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́ láti pín. A óò fún àwọn akéde tí wọ́n ti ṣèrìbọmi ní káàdì yìí bí ìpàdé tòní bá ti parí, àmọ́ ẹ MÁ ṢE buwọ́ lù ú lónìí. Lẹ́yìn ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀ ni ká buwọ́ lu àwọn káàdì yìí, tí a óò jẹ́rìí sí wọn, tí a ó sì kọ déètì sí i, tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sì ṣèrànwọ́ bó bá pọn dandan. [Kí àwọn òbí gba Identity Cards (Káàdì Ìdánimọ̀) fún àwọn ọmọ wọn.] Kí àwọn tí ń buwọ́ lu káàdì náà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí jẹ́ kí ẹni tó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn. Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè ṣètò láti ṣe káàdì tiwọn, èyí tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa lò, nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì yìí kọ láti bá ipò wọn àti ìgbàgbọ́ wọn mu.
17 min: “Rí I Pé O Wo Fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge.” Alàgbà kan tó dáńgájíá ni kó bójú tó o. Láìfi àkókò ṣòfò, bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò fídíò No Blood pẹ̀lú àwùjọ, nípa lílo àwọn ìbéèrè tá a pèsè nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 7. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn nínú àpótí náà. Ní àfirọ́pò, jíròrò “O lè Ní Ìgbàgbọ́ Tòótọ́.” Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ, èyí tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ October 1, 2001, ojú ìwé 4 sí 7.
Orin 79 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.