ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 5
  • Ìrànlọ́wọ́ ní Àkókò Tó Tọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrànlọ́wọ́ ní Àkókò Tó Tọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Gbàgbé Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • “Ẹ Pa Dà Sọ́dọ̀ Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Wọn Kí Wọ́n Lè Tètè Pa Dà Láìjáfara!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 5

Ìrànlọ́wọ́ ní Àkókò Tó Tọ́

1 Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù rí i pé ó pọn dandan pé kí òun fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun lókun, àníyàn tó ní fún wọn sún un láti fún wọn ní ìránnilétí àti ìṣírí onífẹ̀ẹ́. (2 Pét. 1:12, 13; 3:1) Ó rọ “àwọn tí ó ti gba ìgbàgbọ́” láti máa tẹ̀ síwájú láti ní àwọn ànímọ́ tẹ̀mí kí wọ́n má bàa di “aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso ní ti ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:1, 5-8) Ète tí Pétérù fi ṣe èyí ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú pípè tí Jèhófà pè wọ́n àti yíyàn tó yàn wọ́n dájú, kí a bàa lè “bá [wọn] nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.” (2 Pét. 1:10, 11; 3:14) Ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tó yẹ ni ìṣírí rẹ̀ yìí jẹ́ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.

2 Lónìí, àwọn Kristẹni alábòójútó ní irú àníyàn kan náà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà wà nínú àwọn ipò tó ṣòro tí wọ́n ní láti máa fara dà. (2 Tím. 3:1) Nítorí ìṣòro ìṣúnná owó, ìṣòro ìdílé, tàbí àwọn ìṣòro ara ẹni tí kò lọ bọ̀rọ̀, àwọn kan lè máa ní ìmọ̀lára bíi ti Dáfídì, ẹni tó sọ pé: “Àwọn ìyọnu àjálù ká mi mọ́ títí iye wọn kò fi ṣeé kà. Ọ̀pọ̀ ìṣìnà tèmi lé mi bá ju bí mo ti lè rí i; wọ́n pọ̀ níye ju irun orí mi, ọkàn-àyà mi sì fi mí sílẹ̀.” (Sm. 40:12) Àwọn ìṣòro náà lè máa ni àwọn kan lára débi pé, wọ́n lè máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ojúṣe tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì, kí wọ́n sì dáwọ́ kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni dúró. Síbẹ̀, láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n lè máa kojú sí, ‘wọn kò tíì gbàgbé àwọn àṣẹ Jèhófà.’ (Sm. 119:176) Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò títọ́ fún àwọn alàgbà láti fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò.—Aísá. 32:1, 2.

3 Láti ṣàṣeparí èyí, a ti fún àwọn alàgbà níṣìírí láti ṣe àkànṣe ìsapá láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti dáwọ́ dúró nínú kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ìsapá aláápọn láti ṣe èyí ti ń lọ lọ́wọ́ yóò sì máa bá a lọ jálẹ̀ oṣù March. A rọ àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti bẹ àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ wò kí wọ́n sì fún wọn ní ìrànwọ́ tẹ̀mí, kí wọ́n bàa lè tún máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú onítọ̀hún. Wọ́n lè ké sí àwọn akéde mìíràn nínú ìjọ láti ṣèrànwọ́. Bí a bá ké sí ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìsapá tó o bá ṣe lè ṣàǹfààní gan-an, pàápàá tó bá jẹ́ pé pẹ̀lú inú rere àti ìgbatẹnirò lo fi ń fún wọn níṣìírí.

4 Gbogbo wa pátá la nídìí láti yọ̀ nígbà tí ẹnì kan bá tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i. (Lúùkù 15:6) Àwọn ìsapá tá a bá ṣe láti fún àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ níṣìírí lè jẹ́ “ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́” ní ti gidi.—Òwe 25:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́