Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
1 Ọ̀gá wa ti sàsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò rí ìpọ́njú. (Mát. 24:9) Irú ojú wo ló yẹ ká fi wo àdánwò? Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìpọ́njú? Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká ti ọdún 2004 yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí. Ẹ Máa Ní Ìfaradà Lábẹ́ Ìpọ́njú.”—Róòmù 12:12.
2 Àpínsọ Àsọyé Méjì: Àpínsọ àsọyé àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ẹ Máa Fi Ìfaradà So Èso,” yóò ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà so èso. A óò fọ̀rọ̀ wá àwọn akéde díẹ̀ lẹ́nu wò nípa bí wọ́n ṣe ń wàásù tí wọ́n sì ń fi ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú kọ́ni. Àwọn òbí ní pàtàkì jù lọ yóò fẹ́ láti fiyè sí apá náà, “Nígbà Tí Jèhófà Bá Bá Wa Wí,” èyí tí yóò jíròrò bí àwọn òbí ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Olùbánisọ̀rọ̀ tí yóò sọ̀rọ̀ kẹ́yìn nínú àpínsọ àsọyé náà yóò sọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ayé bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ wọnú ìgbésí ayé wa tí èyí yóò sì mú ká di aláìléso.—Máàkù 4:19.
3 “Ẹ Fi Ìfaradà Sá Eré Ìje Náà” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpínsọ àsọyé kejì. Yóò jẹ́ ká rí i kedere bí ọ̀nà táà ń gbà gbé ìgbésí ayé wa ṣe dà bí eré ìje. Kí nìdí tá a fi ní láti sáré níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tá a fi lélẹ̀? Báwo la ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ìsapá wa láti mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò tí a kò sì ní káàárẹ̀ nínú eré ìje ìyè náà? Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó bá àkókò mu tí a óò pèsè fún wa yóò ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú ìfaradà.
4 Ìforítì Máa Ń Mú Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run Wá: Àwọn àsọyé tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò yóò sọ yóò mú kí ìgbàgbọ́ àwọn tó bá fetí sílẹ̀ tí wọ́n sì fi ìmọ̀ràn náà sílò lágbára sí i. Ọ̀kan lára àwọn àsọyé tí alábòójútó àgbègbè yóò sọ ní àkòrí náà, “Ìfaradà Máa Ń Múni Dẹni Ìtẹ́wọ́gbà.” Àsọyé fún gbogbo ènìyàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè náà: Nínú orúkọ ta ló yẹ kí àwọn orílẹ̀-èdè fi ìrètí wọn sí, kí sì ni ohun tí ìyẹn ní nínú? Àsọyé náà, “Nípasẹ̀ Ìfaradà Ni Ẹ Ó Fi Jèrè Ọkàn Yín,” tí yóò kádìí àpéjọ náà yóò ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí Jésù gbà fara da àìṣèdájọ́ òdodo tí kò sì di ẹni tá a mú bínú.
5 Má gbà gbé láti mú ẹ̀dà ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ilé Ìṣọ́ tìrẹ tí a óò kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ náà dání. Kọ àkọsílẹ̀ kó o lè pọkàn pọ̀, kó o sì tún lè rí àkọsílẹ̀ náà lò lọ́jọ́ iwájú. A ṣì máa ṣàgbéyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà nínú ìjọ.
6 Jèhófà fúnra rẹ̀ ló pèsè àkànṣe àsè tẹ̀mí yìí. Wá ká jọ jẹ àsè tẹ̀mí náà! A óò hó ìhó ayọ̀ bí a bá pésẹ̀ síbẹ̀ láti jàǹfààní látinú gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.—Aísá. 65:14.