Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ìpìlẹ̀ Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Lélẹ̀ De Ẹ̀yìn Ọ̀la
1. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ní ìgbàgbọ́ tó lágbára?
1 Kí lohun tó jẹ ọ́ lọ́kàn jù lọ? Kí lo máa ń ronú nípa rẹ̀? Ṣé àwọn nǹkan ìsinsìnyí ló jẹ ọ́ lógún jù lọ ni tàbí àwọn nǹkan tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, tó dá lórí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí? (Mát. 6:24, 31-33; Lúùkù 8:14) Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Mósè ṣe fi hàn, ó gba pé ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára kí àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí tó lè sún wa ṣe ohunkóhun. (Héb. 11:8-10, 24-26) Báwo la ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, ká sì ‘fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la’?—1 Tím. 6:19.
2. Kí la rí kọ nínú àpẹẹrẹ Jòsáyà Ọba?
2 Wá Jèhófà: Bí ìwọ àti ìdílé rẹ bá jọ ń ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí pọ̀ déédéé, èyí dára gan-an. Àmọ́ má ṣe rò pé irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ yóò kàn ṣàdédé mú ọ dẹni tó nígbàgbọ́ tó lágbára o. Kó o tó lè rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” ó gbọ́dọ̀ fúnra rẹ wá Jèhófà. (Òwe 2:3-5; 1 Kíró. 28:9) Ohun tí Jòsáyà ọ̀dọ́mọdé ọba ṣe nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyíká tó lè máà jẹ́ kó ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí ló ti dàgbà, “ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀” nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.—2 Kíró. 34:3.
3. Báwo làwọn ọ̀dọ́ Kristẹni lónìí ṣe lè wá Jèhófà?
3 Báwo lo ṣe lè wá Jèhófà? O lè wá a nípa fífarabalẹ̀ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun tó o gbà gbọ́, kó o sì ‘ṣàwárí fúnra rẹ’ pé wọ́n jẹ́ òtítọ́ ní ti gidi. (Róòmù 12:2) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀jẹ̀ tàbí kó o fẹ̀rí hàn pé Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso ní ọ̀run lọ́dún 1914? Níní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́” jẹ́ apá pàtàkì nínú fífi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la.—1 Tím. 2:3, 4.
4. Báwo làwọn akéde tí kò tì í ṣèrìbọmi ṣe lè fi hàn pé àwọ́n ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
4 Wíwá tí Jòsáyà wá Ọlọ́run bímọọre. Kí ó tó pé ọmọ ogún ọdún, ó gbégbèésẹ̀ tìgboyàtìgboyà láti fòpin sí ìjọsìn èké ní ilẹ̀ náà. (2 Kíró. 34:3-7) Bákan náà, àwọn ohun tó o bá ń ṣe ló máa fi hàn pé ò ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (1 Tím. 4:15) Bó bá jẹ́ pé akéde tí kò tì í ṣèrìbọmi ni ọ́, sapá láti mú kí ọ̀nà tó o gbà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ sunwọ̀n sí i. Má kàn gbà pé bó o bá ti fi ìwé sóde, ó ti tó. Pinnu láti máa lo Bíbélì, láti máa ṣàlàyé òtítọ́ fáwọn èèyàn àti láti máa kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́. (Róòmù 12:7) Èyí á mú kó o lè dàgbà nípa tẹ̀mí.
5. Àwọn àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fáwọn Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i?
5 Fi Gbogbo Agbára Rẹ Sin Jèhófà: Nígbà tó o ṣèrìbọmi láti fi hàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó dẹni tí Ọlọ́run yàn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́. (2 Kọ́r. 3:5, 6) Èyí mú kó o ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún Jèhófà. Lára wọn ni ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì àti lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà mìíràn tó o lè gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i jẹ́ nípa kíkọ́ èdè mìíràn tàbí nípa ṣíṣí lọ sí àwọn ibi tí àìní gbé pọ̀.
6. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la?
6 Òótọ́ ni pé gbogbo wa kọ́ ló lè kópa nínú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọ̀nyí, àmọ́ olúkúlùkù wa ló lè fi gbogbo agbára rẹ̀ sin Jèhófà. (Mát. 22:37) Ipò yòówù tó o lè wà, fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ṣe ohun tó ò ń lépa ní ìgbésí ayé. (Sm. 16:5) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa fi ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ lélẹ̀ de ẹ̀yìn ọ̀la.