Oúnjẹ Tẹ̀mí ní Àkókò Yíyẹ
1. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Ìsíkíẹ́lì 36:29 ṣe ń ṣẹ lónìí?
1 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ pé: “Èmi yóò . . . pe ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ gidigidi, èmi kì yóò sì mú ìyàn dé bá yín.” (Ìsík. 36:29) Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ sí àwọn èèyàn Ọlọ́run lára lónìí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, Jèhófà ti mú kí ọkà tó ń fúnni ní ìyè dàgbà sókè kó sì pọ̀ yanturu fáwọn èèyàn rẹ̀. Oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò tí Jèhófà ń tipasẹ̀ àwọn àpéjọ àgbègbè wa pèsè fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àpéjọ àgbègbè láti fi pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò yíyẹ?
2 Ní àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní Columbus, Ohio, lọ́dún 1931, Jèhófà tọ́ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ sọ́nà pé kí wọ́n máa jẹ́ orúkọ tuntun kan, ìyẹn ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10-12) Lọ́dún 1935, a mọ àwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí Ìṣípayá 7:9-17 sọ. Lọ́dún 1942, Arákùnrin Knorr sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àlàáfíà—Ǹjẹ́ Ó Lè Wà Pẹ́ Títí?” Àsọyé yẹn ta àwọn èèyàn Ọlọ́run jí láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i kárí ayé, ó sì wà lára ohun tó jẹ́ kí ètò àjọ Ọlọ́run dá Watchtower Bible School of Gilead [Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì] sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpéjọ kan jẹ́ mánigbàgbé, gbogbo àpéjọ la ti ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ń ṣara lóore, èyí tá a pèsè ní àkókò yíyẹ.—Sm. 23:5; Mát. 24:45.
3, 4. Kí la ní láti ṣe ká bàa lè jàǹfààní nínú àsè tẹ̀mí ní àpéjọ àgbègbè wa?
3 Ǹjẹ́ Ò Ń Jẹun Tó Bó Ṣe Yẹ? Ó ṣeé ṣe pé kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, àmọ́ ká má jẹun kánú bí a ò bá sapá láti jẹun. (Òwe 26:15) Bọ́ràn ṣe rí nípa tẹ̀mí náà nìyẹn. Láwọn àpéjọ mélòó kan, a ti ṣàkíyèsí pé ńṣe làwọn kan fi gbọ̀ngàn àpéjọ sílẹ̀ tí wọ́n lọ ń ya fọ́tò nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Kódà, àwọn kan bá a débi pé wọ́n ń pe àwọn onífọ́tò wá sí ilẹ̀ àpéjọ. A kò fàyè gba èyí rárá.—Jòh. 2:16.
4 Síwájú sí i, a ti ṣàkíyèsí pé ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wá sí àpéjọ ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri láìnídìí tàbí kí wọ́n máa báwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé ìfararora tí ń gbéni ró jẹ́ ohun pàtàkì kan lára àpéjọ wa, àmọ́ ṣáájú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ti parí ló yẹ ká ṣe èyí. (Oníw. 3:1, 7) Bí a kò bá wà lórí ìjókòó ká máa fetí sílẹ̀, a lè máà gbọ́ àwọn kókó pàtàkì kan. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alábòójútó ẹ̀ka iṣẹ́ nígbà àpéjọ àtàwọn arákùnrin tó níṣẹ́ lè rí i pé ó pọn dandan pé káwọn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tó jẹ mọ́ àpéjọ nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó yẹ kí wọ́n fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa títẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Kò sí ẹnì kankan lára wa tó yẹ kó pàdánù ohunkóhun lára oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà pèsè.—1 Kọ́r. 10:12; Fílí. 2:12.
5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a dúpẹ́ fún ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè?
5 Inú wa mà ń dùn gan-an o pé Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀kọ́ òtítọ́ tẹ̀mí fún wa, èyí tó yàtọ̀ sáwọn ẹ̀kọ́ èké tí kò lè ṣeni lóore tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń pèsè! (Aísá. 65:13, 14) Ohun kan tá a lè ṣe láti ‘fi hàn pé a kún fún ọpẹ́’ ni pé ká máa wo àpéjọ àgbègbè bí àǹfààní kan láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà. (Kól. 3:15) Ohun tó ò ń gbọ́ ni kó o fọkàn sí kì í ṣe pé kó o máa ṣe lámèyítọ́ olùbánisọ̀rọ̀, kó o sì gbà pé ọ̀dọ̀ “Olùkọ́ni [wa] Atóbilọ́lá” ni ọ̀rọ̀ náà ti ń wá. (Aísá. 30:20, 21; 54:13) Fetí sílẹ̀ dáadáa. Bó o ṣe ń lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn,” rántí pé ó ṣe pàtàkì pé kó o kọ àkọsílẹ̀ ṣókí, èyí tó máa jẹ́ kó o lè kópa nínú àtúnyẹ̀wò tí ìjọ máa ṣe nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tó ń bọ̀. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Máa fi ohun tó o kọ́ sílò.
6. Kí làwọn ìdí táwọn àpéjọ àgbègbè wa fi ń fún wa láyọ̀?
6 Ìṣẹ́gun ni gbogbo àpéjọ tá a bá ṣe ṣáájú Amágẹ́dọ́nì jẹ́ lórí Sátánì, ì báà jẹ́ àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi la ti ṣe é, tàbí ibi tí ogun ti ń jà, tàbí kó jẹ́ ibi tí kò ti sí wàhálà tí èrò ti pọ̀ gan-an! Gbogbo àwa tá a wà nínú ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan mọrírì àwọn àǹfààní tá a ní láti kóra jọ ní àpéjọ àgbègbè wa. (Ìsík. 36:38) Ó dá wa lójú pé nínú àpéjọ yìí Jèhófà yóò tún fi ìfẹ́ pèsè “oúnjẹ [fún wa] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Lúùkù 12:42.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Mọrírì Oúnjẹ Tẹ̀mí Tí Jèhófà Ń Pèsè
◼ Fetí sílẹ̀ dáadáa
◼ Kọ àwọn kókó pàtàkì sílẹ̀
◼ Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan
◼ Máa fi ohun tó o kọ́ sílò