ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/05 ojú ìwé 7
  • Àpéjọ Àgbègbè Tó Kọjá Ta Wá Jí Láti Bá Ọlọ́run Rìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpéjọ Àgbègbè Tó Kọjá Ta Wá Jí Láti Bá Ọlọ́run Rìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ Káàbọ̀ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn”
    Jí!—2004
  • Bíbá Ọlọ́run Rìn—Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • “Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 2/05 ojú ìwé 7

Àpéjọ Àgbègbè Tó Kọjá Ta Wá Jí Láti Bá Ọlọ́run Rìn

Ká sòótọ́, àpéjọ àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” tá a lọ ti túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí ìtọ́ni kan tí Jèhófà fún wa nínú Bíbélì ti ṣe pàtàkì tó, ìyẹn ni pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀”! (Aísá. 30:21) Bí a bá ń fi àwọn ohun tá a gbọ́ sílò, àá lè ‘máa ṣọ́ra lójú méjèèjì nípa bí a ṣe ń rìn.’ (Éfé. 5:15) Síwájú sí i, bí a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá a gbọ́, a ó lè máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 3.

Lo àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí àti àkọsílẹ̀ tìrẹ láti fi múra sílẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àgbègbè yìí. A ó ṣe àtúnyẹ̀wò yìí nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ March 7.

1. Kí ló ran Énọ́kù lọ́wọ́ tó fi lè bá Ọlọ́run rìn nígbà hílàhílo? (Héb. 11:1, 5, 6; Júúdà 14, 15; “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Nígbà Hílàhílo”)

2. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà lo ìlànà tó wà nínú Lúùkù 16:10 nígbèésí ayé wa? (“Ǹjẹ́ O Máa Ń Ṣòtítọ́ ‘Nínú Ohun Tí Ó Kéré Jù Lọ’?”)

3. (a) Sọ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́rin tó wà nínú Hóséà orí kẹfà sí ìkẹsàn-án tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn. (Hós. 6:6, 7; 7:14; 8:7) (b) Àwọn kókó mìíràn wo ló wà nínú Hóséà orí kẹwàá sí ìkẹrìnlá tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti bá Ọlọ́run rìn? (“Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń Fún Wá Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn”—Àpínsọ Àsọyé)

4. Àwọn nǹkan wo làwọn ọkọ àti aya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè ṣe kí ìgbéyàwó wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa? (Òwe 12:4; Éfé. 5:29; “Má Ṣe Ya ‘Ohun tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀’”)

5. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fún àwọn ìpéjọpọ̀ wa mímọ́? (Oníw. 5:1; Aísá. 66:23; “Bíbọ̀wọ̀ fún Àwọn Ìpéjọpọ̀ Wa Mímọ́”)

6. (a) Àwọn apá mẹ́ta pàtàkì wo nínú iṣẹ́ ìwàásù wa ló yẹ ká yẹ̀ wò ká lè rí i dájú pé à ń ṣe é lọ́nà tó múná dóko? (Aísá. 52:7; Sek. 8:23; Máàkù 6:34) (b) Àwọn ohun wo lo rí pé o wúlò fún ọ nínú ìwé Good News for People of All Nations? (“Ìhìn Rere fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè”; “Ríran Àwọn Tí Ń Sọ Èdè Mìíràn Lọ́wọ́”)

7. Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìgboyà tí wọn yóò fi máa sọ ìhìn Ìjọba Ọlọ́run? (Oníd. 7:17; “Ríran Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Dara Pọ̀ Mọ́ Wa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà”)

8. Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la gbà gbọ́ pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé”? (Sef. 1:14; “Nípa Ìgbàgbọ́ Ni Àwa Ń Rìn, Kì Í Ṣe Nípa Ohun Tí A Rí”)

9. (a) Báwo ni ọ̀ràn mímú ẹlòmíràn kọsẹ̀ ti burú tó? (Máàkù 9:42-48) (b) Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? (Sm. 119:165) (d) Kí la lè ṣe ká má bàa mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀? (1 Kọ́r. 10:24; “Yàgò fún ‘Ohunkóhun Tó Lè Fa Ìkọ̀sẹ̀’”)

10. Báwo la ṣe lè lo òye nígbà tá a bá ń wá ẹni tá a máa fẹ́, nígbà tá a bá ń wá ìwòsàn tó dára àti nígbà tá a bá fẹ́ dáwọ́ lé okòwò? (Sm. 26:4; Mát. 6:25; 1 Tím. 6:9; “Ẹ Pa Agbára Ìmòye Yín Mọ́ Délẹ̀délẹ̀”)

11. (a) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nípa àwọn àkókò tí àwọn èèyàn gba Jésù lálejò? (Lúùkù 10:42; 24:32) (b) Báwo la ṣe lè ṣe eré ìtura lọ́nà tó máa jẹ́ kí ara tu àwa àtàwọn ẹlòmíràn? (1 Kọ́r. 10:31-33; “Àwọn Ìgbòkègbodò Gbígbámúṣé Tó Ń Mára Tuni”)

12. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù orí kẹtàlélógún ṣe sọ, àwọn ìbùkún wo là ń rí gbà nítorí pé a jẹ́ àgùntàn Jèhófà, kí sì làwọn ojúṣe wa? (1 Kọ́r. 10:21; “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Wa”)

13. Báwo làwa Kristẹni ṣe lè fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká ‘máa ra àkókò tó rọgbọ padà’ sílò? (Éfé. 5:16; “Ríra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Padà”)

14. (a) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní ‘wákàtí ìdájọ́’ tí Ìṣípayá 14:7 mẹ́nu kàn? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ la ti kúrò nínú Bábílónì Ńlá? (“‘Ẹ Máa Ṣọ́nà’—Wákàtí Ìdájọ́ Ti Dé”) (d) Àwọn kókó wo lo gbádùn nínú ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!?

15. Sọ àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó yẹ ká ní ká má bàa yà kúrò ní “ipa ọ̀nà títọ́.” (2 Pét. 2:15; “Má Ṣe Yà Kúrò Ní ‘Ipa Ọ̀nà Títọ́’”)

16. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè yàgò fún “ọ̀nà àwọn ẹni búburú”? (Òwe 4:14; “Ẹ̀yin Èwe— Ẹ Máa Rìn ní Ọ̀nà Òdodo”)

17. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa tá a bá fẹ́ ní ìfaradà? (Ìṣe 14:19, 20; 16:25-33) (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù àwọn tó ń gbógun ti ìjọsìn tòótọ́? (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ àti àsọyé tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Wàásù Kúnnákúnná Lóde Òní Láìka Àtakò Sí”)

18. Àwọn ìbùkún wo làwọn tó ń bá Ọlọ́run rìn máa ń rí gbà? (“Bíbá Ọlọ́run Rìn Ń Ṣe Wá Láǹfààní Nísinsìnyí”)

Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa tẹ́tí sí ‘ọ̀rọ̀ tó wà lẹ́yìn wa’ ká lè máa bá Baba wa ọ̀run rìn títí ayé.—Aísá. 30:21; Jòh. 3:36.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́