Apá Kẹta: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Lílo Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Múná Dóko
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé ọ̀rọ̀ wa ka Ìwé Mímọ́ nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Ìdí tá a fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé a fẹ́ ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ Kí wọ́n sì tó lè di ọmọ ẹ̀yìn, a ní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí wọ́n gbà pé òtítọ́ ni, kí wọ́n sì máa fi wọ́n sílò. (Mát. 28:19, 20; 1 Tẹs. 2:13) Nítorí náà, orí Ìwé Mímọ́ ló yẹ ká gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kà. Níbẹ̀rẹ̀, ó máa dára ká fi bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe lè wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú Bíbélì wọn hàn wọ́n. Àmọ́, báwo la ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ láti fi ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
2. Báwo la ṣe lè pinnu ẹsẹ Bíbélì tó yẹ ká kà ká sì ṣàlàyé?
2 Yan Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Tó Yẹ Kó O Kà: Nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀, ronú nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ṣe bá kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ mu, kó o sì pinnu èyí tó o máa kà tó o sì máa ṣàlàyé nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó máa dára kó o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti àwọn ohun tá a gbà gbọ́ lẹ́yìn ní pàtàkì. Kò pọn dandan pé kó o ka àwọn ẹsẹ tó kàn ń ṣe àfikún àlàyé. Máa fi ipò akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan àtàwọn ohun tó lè mú kó tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí sọ́kàn nígbà gbogbo.
3. Àǹfààní wo ló wà nínú bíbéèrè ìbéèrè, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí?
3 Máa Béèrè Ìbéèrè: Dípò tí wàá fi máa ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì fún akẹ́kọ̀ọ́, sọ pé kó ṣàlàyé wọn fún ọ. Bó o bá ń fi ọgbọ́n béèrè ìbéèrè, á lè ṣàlàyé fúnra rẹ̀. Bí àlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bá ṣe kedere, o kàn lè béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bí ẹsẹ náà ṣe ti ohun tí ìpínrọ̀ náà ń sọ lẹ́yìn. Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ pé ìbéèrè kan tó lọ tààrà tàbí onírúurú ìbéèrè ni wàá béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ kó lè róye ohun tí ẹ̀ ń kọ́. Bó bá pọn dandan kó o ṣe àfikún àlàyé, o lè ṣe èyí lẹ́yìn tí akẹ́kọ̀ọ́ bá ti dáhùn.
4. Báwo ló ṣe yẹ kí àlàyé tá a máa ṣe lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kà pọ̀ tó?
4 Jẹ́ Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Rọrùn: Lọ́pọ̀ ìgbà, tafàtafà tó bá jẹ́ ọ̀jáfáfá kì í lò ju ẹyọ ọfà kan lọ tí ọfà rẹ̀ yóò fi ba ibi tó fojú sùn. Bákan náà, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tí ọ̀jáfáfá olùkọ́ bá ṣàlàyé rẹpẹtẹ kí kókó kan tó yé akẹ́kọ̀ọ́. Ó lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́, tó sì máa yé e yékéyéké, kí àlàyé náà sì pé pérépéré. Nígbà míì, o ní láti ṣèwádìí nínú àwọn ìwé Kristẹni kó o lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, kó o sì lè ṣàlàyé rẹ̀ dáadáa. (2 Tím. 2:15) Àmọ́ o, kò yẹ kó o máa ṣàlàyé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ibi tẹ́ ẹ fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Kìkì ohun tí yóò bá mú kí kókó pàtàkì inú ibi tẹ́ ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ṣe kedere ni kó o sọ̀rọ̀ lé lórí.
5, 6. Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé wọn, àmọ́ kí ni kò yẹ ká ṣe?
5 Sọ Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Fi Ohun Tí Ẹ̀ Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Sílò: Nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ, jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ bí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ẹ̀ ń kà ṣe kan òun fúnra rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń ṣàlàyé Hébérù 10:24, 25 fún akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò tíì máa wá sí ìpàdé Kristẹni, o lè sọ fún un nípa ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe, kó o sì sọ pé kó wá. Àmọ́ o, má ṣe jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lò ń fipá mú un. Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sún un láti ṣe ohun tó yẹ kí ó ṣe kó bàa lè mú inú Jèhófà dùn.—Héb. 4:12.
6 Bí a ṣe ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ jẹ́ ká máa lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó múná dóko ‘láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ máa sún wọn ṣègbọràn.’—Róòmù 16:26.