Apá Karùn-ún: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bí A Ó Ṣe Mọ Ìwọ̀n Tí Òye Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Gbé
1 Jésù máa ń kíyè sí bí agbára òye àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe mọ nígbà tó bá ń kọ́ wọn, nípa bẹ́ẹ̀, kì í sọ̀rọ̀ ju “bí òye wọn ti mọ.” (Máàkù 4:33, Ìròyìn Ayọ̀; Jòh. 16:12) Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kí àwọn olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóde òní mọ ìwọ̀nba kókó tí wọ́n máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí òye olùkọ́ àti ti akẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe pọ̀ tó àti ipò àwọn méjèèjì ni wọn ó fi mọ ohun tí wọ́n máa kọ́ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan.
2 Kọ́ Ọ Lọ́nà Tí Yóò Fi Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan wà tó jẹ́ pé kíá lòye ohun tí wọ́n ń kọ́ máa ń yé wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe la máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì. Nítorí náà, kò yẹ kó jẹ́ pé torí àtilè ka ojú ìwé tó pọ̀ la ò ṣe ní bìkítà nípa bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ní òye tó kún rẹ́rẹ́. Ó ṣe tán orí ìpìlẹ̀ tó lágbára, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ló yẹ kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ gbé ìgbàgbọ́ wọn kà.—Òwe 4:7; Róòmù 12:2.
3 Bó o ṣe ń bá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, máa lo àkókò tó pọ̀ tó kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè ní òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó sì tẹ́wọ́ gbà á. Tó o bá ń kánjú jù, akẹ́kọ̀ọ́ náà ò ní lóye bí òtítọ́ tó ń kọ́ ti ṣe pàtàkì tó. Fara balẹ̀ ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tì wọ́n lẹ́yìn.—2 Tím. 3:16, 17.
4 Má Ṣe Yà Bàrá: Bí kò ṣe yẹ ká kánjú tá a bá ń bá akẹ́kọ̀ọ́ wa ṣèkẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe yẹ ká máa yà sígbó yà síjù. Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí kò sí lára ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ ló ń gbé akẹ́kọ̀ọ́ náà níkùn, ẹ lè jẹ́ kó dìgbà tẹ́ ẹ bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ kẹ́ ẹ tó gbé e yẹ̀ wò.—Oníw. 3:1.
5 Àmọ́ ṣá o, tí àwa náà ò bá ṣọ́ra àlàyé wa lè pọ̀ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nítorí bí ìmọ̀ òtítọ́ tá a ní ṣe rí lára wa. (Sm. 145:6, 7) Lóòótọ́ o, àwọn àyàbá tàbí ìrírí kọ̀ọ̀kan lè jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tètè yéni àmọ́ kò yẹ ká jẹ́ kí ìwọ̀nyí pọ̀ jù tàbí kó gùn jù débi pé akẹ́kọ̀ọ́ ò ní lè ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì.
6 Tí a bá ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ní ìwọ̀nba ohun tí òye wọn lè gbé nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, a ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa “rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.”—Aísá. 2:5.