Bó O Ṣe Lè Mú Káwọn Ọmọ Rẹ Máa Tẹ̀ Síwájú Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
1 Ojúṣe àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láti kékeré. Onírúuru ọ̀nà ni wọ́n sì lè gbà ṣe é. Àwọn ọmọ kan wà tí wọ́n lẹ́bùn àtimáa ka ẹsẹ Bíbélì lórí kódà kí wọ́n tó mọ̀wé kà pàápàá. Èyí sì máa ń wú àwọn tá à ń wàásù fún lórí. Báwọn ọmọ kéékèèké yìí bá dàgbà, wọ́n á lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ju bá a ṣe rò. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wàásù? Ó ṣeé ṣe káwọn àbá tó tẹ̀lé e yìí ṣèrànwọ́ síwájú sí i.
2 Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé, ó lè sọ pé:
◼ “Ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà nínú Ìwé Mímọ́ tí ọmọkùnrin mi yìí, [dárúkọ rẹ̀], fẹ́ fi hàn ọ́.” Ọmọ rẹ lè sọ pé: “Ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yìí ló jẹ́ kí n mọ orúkọ Ọlọ́run. [Kí ọmọ náà ka Sáàmù 83:18 látinú Bíbélì tàbí kó kà á lórí.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Ṣé kí n kúkú fi eléyìí sílẹ̀ fún yín?” O lè kádìí ìfèròwérò náà pẹ̀lú àlàyé nípa báwọn èèyàn ṣe ń ti iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.
3 Tàbí kó o sọ ọ́ báyìí:
◼ “Ẹ ǹlẹ́ ńbí o. Mò ń kọ́ ọmọbìnrin mi yìí, [dárúkọ rẹ̀], kó lè mọ bó ṣe yẹ kéèyàn máa ro tàwọn aládùúgbò rẹ̀ mọ́ tiẹ̀ ni. Ó máa fẹ́ báa yín sọ̀rọ̀ ṣókí nípa Bíbélì.” Ọmọbìnrin náà lè sọ pé: “Ọ̀nà kan tí mo fẹ́ láti máa gbà ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ni pé kí n máa ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ iwájú fún wọn. [Kí ọmọ náà ka Ìṣípayá 21:4 látinú Bíbélì tàbí kó kà á lórí.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún wa. Mo mọ̀ pé wàá gbádùn kíkà àwọn ìwé ìròyìn náà.”
4 Tẹ́ ẹ bá ń fi ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó ṣe ṣókí kọ́ àwọn ọmọ, á jẹ́ kí wọ́n lè ní ìgboyà láti lè sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Bí wọ́n bá ń ṣe ìdánrawò nípa bí wọ́n á ṣe máa sọ̀rọ̀ sókè lọ́nà tó lè yéni yékéyéké, á múra wọn sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ níbikíbi àti nígbàkigbà. Tẹ́ ẹ bá sì ń jẹ́ kí wọ́n máa múra sílẹ̀ dáadáa ṣáájú àkókò, tẹ́ ẹ sì ń yìn wọ́n, á túbọ̀ ran àwọn ògo wẹẹrẹ wọ̀nyí lọ́wọ́ láti máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn.
5 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé irú ìṣírí báyìí ti mú kí wọ́n di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi. Ẹ wo bí inú wa ṣe máa ń dùn tó báwọn ọmọ wa bá ń tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni!—Sm. 148:12, 13.