ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/06 ojú ìwé 1
  • Rí I Pé O Ń Wá Ọ̀nà Láti Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rí I Pé O Ń Wá Ọ̀nà Láti Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Yin Jehofa Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Máa Yin Jèhófà Nípa Wíwàásù Lọ́nà Àìjẹ́ bí Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 8/06 ojú ìwé 1

Rí I Pé O Ń Wá Ọ̀nà Láti Wàásù

1 Onírúurú èèyàn tí ipò wọn yàtọ̀ síra ló para pọ̀ di ìjọ Kristẹni. Síbẹ̀, ìmọ̀ wa ṣọ̀kan ní ti ìpinnu tá a ṣe láti máa yin Jèhófà. (Sm 79:13) Ká ní àìlera tàbí ìṣòro míì ni ò jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ nínú pípolongo ìhìn rere, báwo la ṣe lè máa rí i pé à ń wá ọ̀nà láti wàásù?

2 Lẹ́nu Ìgbòkègbodò Wa Ojoojúmọ́: Jésù kì í jẹ́ kí àkókò tó ń lò pẹ̀lú àwọn èèyàn lójoojúmọ́ lọ lásán láìjẹ́ pé ó wàásù. Nígbà tó ń gba ibi ọ́fíìsì owó orí kọjá, ó wàásù fún Mátíù, bákan náà, nígbà tó ń rìnrìn-àjò, ó wàásù fún Sákéù, nígbà tó sì ń sinmi, ó tún wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan. (Mát. 9:9; Lúùkù 19:1-5; Jòh. 4:6-10) Lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́, àwa náà lè yí ìtàkúrọ̀sọ lásán sí ìwàásù. Ó máa yá wa lára láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tá à ń retí fáwọn èèyàn bá a bá ń jẹ́ kí Bíbélì àti ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí àwọn ìwé pẹlẹbẹ máa wà lọ́wọ́ wa ní gbogbo ìgbà.—1 Pét. 3:15.

3 Ṣé kì í ṣe pé àìlè rìn dáadáa ló fà á tó ò fi lè ṣe tó bẹ́ẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé? Má ṣe jáfara láti máa wàásù fáwọn òṣìṣẹ́ ìlera tó máa ń bẹ̀ ọ́ wò àtàwọn ẹlòmíì tó o máa ń bá pàdé. (Ìṣe 28:30, 31) Bó o bá bá ara ẹ nípò tó ò fi lè máa jáde kúrò nílé, o ò ṣe dán ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù wò tàbí kó o máa jẹ́rìí nípasẹ̀ lẹ́tà? Ohun tí arábìnrin kan ń ṣe ni pé ó máa ń kọ lẹ́tà sáwọn ará ilé ẹ̀ tí wọ́n kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lóòrèkóòrè. Ó máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ látinú Bíbélì tó lè fún ìdílé náà níṣìírí àtàwọn ìrírí tóun alára ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù sínú lẹ́tà náà.

4 Níbi Iṣẹ́ Tàbí Níléèwé: Wíwù tó ń wù wá láti máa yin Jèhófà á tún mú ká máa wá bá a ó ṣe máa fi òtítọ́ kọ́ àwọn èèyàn níbi iṣẹ́ tàbí níléèwé. Akéde kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ sọ ohun tó kà nípa òṣùpá nínú ìwé ìròyìn Jí! fáwọn tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì. Nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ ti gbọ́ pé látinú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ló ti rí àlàyé yẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé. Níbi iṣẹ́, bá a bá kàn fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni síbi táwọn èèyàn ti lè rí i, ìyẹn á mú káwọn ẹlòmíì béèrè àwọn ìbéèrè tó lè fún wa láǹfààní láti wàásù.

5 O ò ṣe ronú onírúurú ọ̀nà tó o lè gbà máa rí i pé ò ń wàásù lẹ́nu ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́? Bá a ṣe ń rí i pé à ń lo àwọn àǹfààní tó ń yọjú láti wàásù, ẹ jẹ́ ká máa rí i pé lójoojúmọ́ là ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run.”—Héb. 13:15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́