Ǹjẹ́ O Ti Fìgbà Kan Rí Béèrè Ẹni Tó Tún Máa Nífẹ̀ẹ́ sí I?
O ò ṣe béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní báyìí bó bá mọ ẹnì kan lára àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, tàbí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tó lè nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni? Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí àwọn orúkọ bíi mélòó kan gbà. Béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bóyá ó fẹ́ kó o dárúkọ rẹ̀ nígbà tó o bá lọ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tó dárúkọ fún ẹ. Nígbà tó o bá ń ṣe ìkésíni náà, o lè sọ pé: “[Orúkọ ẹni náà] ti gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an débi pé, ó ronú pé ìwọ pẹ̀lú lè fẹ́ láti jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tá a máa ń ṣe.” Lẹ́yìn náà, ní ṣókí, ṣe bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lójú ẹ̀ nípa lílo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
Bí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń tẹ̀ síwájú dáadáa, o lè fún un níṣìírí láti ṣàlàyé bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó lè nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tiẹ̀ lè pè wọ́n wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ tiẹ̀. Tíyẹn ò bá sì rọ̀ wọ́n lọ́rùn, ó lè ṣètò pé kó o lọ fi bá a ṣe máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn wọ́n nílé wọn. Èyí á lè fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí láti lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìmọ̀ Bíbélì tó ti ní kọ́ àwọn ẹlòmíràn.
Àwọn tó o máa ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn pàápàá lè sọ ẹni tí wọ́n rò pé ó lè nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ẹ ká tiẹ̀ ní àwọn fúnra wọn ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún. O lè fún wọn ní ẹ̀dà kan ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó o wá sọ pé, “Ǹjẹ́ o mọ ẹlòmíì tó máa fẹ́ láti ka ìwé yìí?”
Lásìkò kánjúkánjú tá a wà yìí, a fẹ́ lo gbogbo ọ̀nà tó bá ṣeé ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà. Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí béèrè ẹni tó tún máa nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?