ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/12 ojú ìwé 7
  • Ohun Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Ti Fìgbà Kan Rí Béèrè Ẹni Tó Tún Máa Nífẹ̀ẹ́ sí I?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Apá Keje: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Bí Gbogbo Ìjọ Ṣe Lè Mú Kí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kan Tẹ̀ Síwájú Kó sì Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 10/12 ojú ìwé 7

Ohun Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

1. Tó bá ń ṣòro fún wa láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, kí la lè ṣe, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

1 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ní ẹni tí wàá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ, ṣe ni kó o túbọ̀ máa sapá. Jèhófà máa ń bù kún àwọn tí kò bá juwọ́ sílẹ̀ nínú bí wọ́n ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Gál. 6:9) Àwọn àbá márùn-ún tó wà nísàlẹ̀ yìí máa ràn ọ́ lọ́wọ́.

2. Báwo la ṣe lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní tààràtà?

2 Fi Lọ̀ Wọ́n Ní Tààràtà: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé a máa ń fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àmọ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n má mọ̀ pé a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O ò ṣe gbìyànjú láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní tààràtà nígbà tó o bá ń wàásù láti ilé dé ilé? O tún lè béèrè lọ́wọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa bóyá wọ́n á fẹ́ kó o máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí wọn kò bá fẹ́, o lè máa fún wọn láwọn ìwé wa, kó o sì túbọ̀ mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Arákùnrin kan ti máa ń fún tọkọtaya kan ní àwọn ìwé ìròyìn wa fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà tó fún wọn láwọn ìwé náà tán lọ́jọ́ kan, kó tó máa lọ, ó bi wọ́n pé: “Mi ò mọ̀ bóyá ẹ máa fẹ́ kí n máa wá kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Ó yà á lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n fún un lésì pé àwọn fẹ́. Ní báyìí, tọkọtaya yẹn ti ṣèrìbọmi.

3. Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa ronú pé gbogbo àwọn tó ń wá sípàdé wa ló ti ní ẹni tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Sọ ìrírí tó fi hàn pé kò yẹ ká máa ronú bẹ́ẹ̀.

3 Àwọn Tó Ń Wá sí Ìpàdé: Má ṣe ronú pé gbogbo àwọn olùfìfẹ́hàn tó ń wá sí ìpàdé ló ti ní ẹni tó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arákùnrin kan sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n wá sí ìpàdé ni mo bá wọn sọ̀rọ̀.” Arábìnrin kan ṣàkíyèsí pé obìnrin kan tó máa ń tijú máa ń tè lé àwọn ọmọ ẹ̀ tó ti ṣèrìbọmi wá sípàdé. Ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí obìnrin náà ti ń wá sípàdé, ó máa ń wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní gbàrà tí ìpàdé bá bẹ̀rẹ̀, ó sì máa ń lọ kété tí ìpàdé bá ti parí. Nígbà tí arábìnrin náà fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ obìnrin yẹn, ó gbà. Ní báyìí, obìnrin náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arábìnrin náà sọ pé: “Ó dùn mí pé lẹ́yìn ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí mo ti ń rí obìnrin yìí ni mo tó lọ fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́!”

4. Báwo lo ṣe lè tipasẹ̀ ẹlòmíì mọ ẹni tó o lè máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

4 O Lè Tipasẹ̀ Ẹlòmíì Mọ̀ Wọ́n: Arábìnrin kan sábà máa ń tẹ̀ lé àwọn ẹlòmíì lọ sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn. Nígbà tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kan lọ́jọ́ kan, ó tọrọ àyè lọ́wọ́ ẹni tó darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó sì wá béèrè lọ́wọ́ ẹni tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bóyá ó mọ ẹlòmíì tó ṣeé ṣe kó nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá fẹ́ fún ẹnì kan tó o ti máa ń lọ bẹ̀ wò tẹ́lẹ̀ ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, o lè bi í pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹlòmíì tó ṣeé ṣe kóun náà fẹ́ láti ka ìwé yìí?” Nígbà míì, àwọn nǹkan kan lè mú kó má ṣeé ṣe fáwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà kan láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan tí wọ́n bá pàdé lóde ẹ̀rí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, sọ fún àwọn akéde tàbí aṣáájú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ pé wàá fẹ́ láti máa kọ́ ẹni tí wọ́n bá pàdé yẹn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

5. Kí nìdí tá a fi lè bi àwọn aláìgbàgbọ́ tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà léèrè bóyá wọ́n á fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

5 Ọkọ Tàbí Aya Tó Jẹ́ Aláìgbàgbọ́: Ṣé àwọn akéde kan wà nínú ìjọ yín tí ọkọ tàbí aya wọn jẹ́ aláìgbàgbọ́? Àwọn aláìgbàgbọ́ kan wà tí wọn kì í fẹ́ bá ọkọ tàbí aya wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, àmọ́ tí wọ́n á gbà kí ẹlòmíì máa wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tó sábà máa ń dáa jù ni pé kó o kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya ẹni náà tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó o lè mọ bó ṣe dáa jù láti bá ẹni náà jíròrò.

6. Kí nìdí tí àdúrà fi ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

6 Fi Ọ̀rọ̀ Náà sí Àdúrà: Má ṣe fojú kéré agbára tí àdúrà ní. (Ják. 5:16) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa gbọ́ àdúrà wa tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (1 Jòh. 5:14) Arákùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà pé ó wu òun láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyàwó rẹ̀ ń wò ó pé bóyá ló máa ráyè gbọ́ ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, pàápàá tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ní ìṣòro tó pọ̀. Torí náà, ìyàwó rẹ̀ gbàdúrà nípa ọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà gbọ́ àdúrà wọn. Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, aṣáájú-ọ̀nà kan nínú ìjọ wọn rí ọkùnrin kan tó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì darí arákùnrin náà sí onítọ̀hún. Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Ìmọ̀ràn tí mo ní fún gbogbo àwọn tó bá rò pé ó ṣòro fún àwọn láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé, kí wọ́n sọ ohun pàtó tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn fún Jèhófà, kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó sú wọn láti máa fi ọ̀rọ̀ náà sí àdúrà. Mi ò ronú pé èmi àti ọkọ mi lè ní ayọ̀ tó pọ̀ tó báyìí rí.” Tí o kò bá jẹ́ kó sú ẹ láti máa sapá, ìwọ náà ṣì lè ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ran ẹlòmíì lọ́wọ́ láti wá sí “ojú ọ̀nà tí ó lọ [sí] ìyè.”—Mát 7:13, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́