Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Gbígba Tiwọn Rò
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Aláṣẹ Láyé Àtọ̀run ni Jèhófà, síbẹ̀ onínúure ni, ó ń gba tàwọn èèyàn rò, ó sì ń fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn aláìpé wọ̀ wọ́n. (Jẹ́n. 13:14; 19:18-21, 29) Fífarawé Ọlọ́run wa tó jẹ́ onínúure tó sì ń gba táwọn èèyàn rò lè mú ká ṣàtúnṣe sí bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere. (Kól. 4:6) Èyí kọjá ká máa fi pẹ̀lẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ká sì máa fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n.
2 Tá A Bá Ń Wàásù Láti Ilé dé Ilé: Kí ni ṣíṣe bí onílé tá a lọ bẹ̀ wò kò bá ráàyè tiwa tàbí tí ọwọ́ rẹ̀ bá dí jù láti gbọ́ tiwa? Ó yẹ ká fi hàn pé àwa náà mọ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ dí, ká sì jẹ́ kí ìjíròrò wa mọ ṣókí tàbí ká ṣètò ìgbà míì tá a máa padà bẹ̀ ẹ́ wò. Bá a bá ń gba tàwọn èèyàn rò, a ò ní máa mú wọn ní dandan láti gba ìwé wa nígbà tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí i. Bá a bá ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò, a ó máa ṣe ohun tó fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún ilé wọn, bíi ká máa pa géètì àti ilẹ̀kùn dé, ká máa bọ́ bàtà wa ká tó wọlé, ká sì tún kọ́ àwọn ọmọ wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn tó ń kọjá lọ ò lè rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí tá a bá fi sẹ́nu ọ̀nà ẹni tá ò bá nílé. Kò sí àníàní pé gbígba tàwọn èèyàn rò á mú ká lè bá àwọn èèyàn lò bá a ṣe fẹ́ kí wọ́n bá wa lò.—Lúùkù 6:31.
3 Tá A Bá Ń Jẹ́rìí ní Òpópónà: Tá a bá ń jẹ́rìí ní òpópónà, a lè fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n nípa rírí i pé a ò dí ojú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ gbà bọ̀, a ò sì dúró síwájú ilé ìtajà. A gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò láti mọ ìṣesí àwọn èèyàn kó lè jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ṣì ráàyè láti lè gbọ́rọ̀ wa fún ìṣẹ́jú díẹ̀ la ó máa bá sọ̀rọ̀ dípò àwọn tó hàn kedere pé wọ́n ń kánjú. Láwọn ìgbà míì, ó lè pọn dandan pé ká gbóhùn sókè kí ariwo àwọn tó ń rìn lọ rìn bọ̀ má bàa bo ohùn wa mọ́lẹ̀. Síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ ṣe é lọ́nà tó máa pọ́n wa lé, kì í ṣe pé ká wá máa pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara wa.—Mát. 12:19.
4 Tá A Bá Ń Wàásù Lórí Tẹlifóònù: Bá a bá ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò, a ò ní dúró síbi tí ariwo ò ti ní jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ohun tá à ń sọ nígbà tá a bá ń wàásù fún wọn látorí tẹlifóònù. Á fìwà ọmọlúwàbí hàn bá a bá sọ ẹni tá a jẹ́ tá a sì ṣàlàyé ìdí tá a fi pe ẹni náà sórí tẹlifóònù. Ọ̀rọ̀ ìyànjú látinú Ìwé Mímọ́ tá à ń bá wọn sọ á dùn létí wọn bá a bá gbẹ́nu sún mọ́ tẹlifóònù náà dáadáa tá a sì jẹ́ kí ohùn wa bá etí mu. (1 Kọ́r. 14:8, 9) Bá a bá jẹ́ onínúure, tá à ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò tá a sì ń fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n láwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu bà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a jẹ́ pé Ọlọ́run wa Jèhófà là ń fara wé.