Àpótí Ìbéèrè
◼ Ǹjẹ́ ó bójú mu láti ṣètò ìkówójọ torí àtifi owó ṣèrànwọ́ fún ìjọ?
Ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ètò ẹ̀sìn pé kí wọ́n máa ṣonígbọ̀wọ́ ètò ìkówójọ, bíi pípé jọ níbi àsè, títa bàsá, tàbí ṣíṣe ìkórè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè rí èyí bí ọ̀nà tó dáa láti gbà kówó jọ, kò yàtọ̀ sí dídọ́gbọ́n tọrọ owó. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í wá owó nírú ọ̀nà yẹn.
Ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kọ̀ láti máa ṣe bí àwọn tí wọ́n pera wọn ní ẹlẹ́sìn Kristi, tí wọ́n sì ń ṣagbe owó wà nínú ẹ̀dà kejì ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti oṣù August 1879, èyí tó kà pé: “‘Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé JÈHÓFÀ la gbà gbọ́ pó jẹ́ alátìlẹyìn wa nídìí títẹ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower, láé àti láéláé, a ò ní tọrọ tàbí ká ṣagbe owó dé ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé Òun alára tó sọ pé: ‘Gbogbo góòlù àti fàdákà àwọn orí òkè jẹ́ tèmi,’ kò bá lè pèsè owó tá a ó máa lò mọ́, a jẹ́ pé àkókò ti tó nìyẹn láti fòpin sí títẹ ìwé ìròyìn náà.”
Ìlànà Ìwé Mímọ́ la óò ṣì máa tẹ̀ lé, èyí tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́r. 9:7) A gbé àwọn àpótí ọrẹ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ẹni tó bá wù látọkànwá lè fi ọrẹ sínú rẹ̀. (2 Ọba 12:9) A kì í dọ́gbọ́n tọrọ owó; a kì í sì í fi ọrẹ sínú àpótí torí ká lè rí nǹkan míì gbà padà.