ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/07 ojú ìwé 1
  • “Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ń fi Agbára Fún Ẹni Tó Ti Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jehofa Ń fún Àwọn Tí Àárẹ̀ Mú Lágbára
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • “Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Jèhófà ‘Ń Fi Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìgbàgbọ́ Bọ́ Wa’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 5/07 ojú ìwé 1

“Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”

1 Kò sẹ́ni tí kì í rẹ̀ nínú wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ tá à ń ṣe, àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí tún máa ń jẹ́ kó rẹ̀ wá. (2 Tím. 3:1) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, báwo la ṣe lè rí agbára gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn agbára tá a nílò ká má bàa dẹni tó ń dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? A máa rí i gbà bá a bá ń gbára lé Jèhófà, ẹni tó “ní okun inú nínú agbára.” (Aís. 40:26) Ó mọ ohun tá a nílò, ó sì ń wù ú láti máa ràn wá lọ́wọ́.—1 Pét. 5:7.

2 Ètò Tí Jèhófà Ti Ṣe Sílẹ̀: Jèhófà máa ń fún wa lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, èyí tó jẹ́ agbára tí kì í bà á tì tó fi ṣẹ̀dá ayé. Ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká lè “jèrè agbára padà” nígbà tó bá ti rẹ̀ wá. (Aís. 40:31) Bi ara rẹ pé, ‘Ó tó ìgbà wo kẹ́yìn báyìí tí mo ti dìídì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi ní ẹ̀mí mímọ́ kí n lè ní agbára láti máa ṣe ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni?’—Lúùkù 11:11-13.

3 Bá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí déédéé, tá a sì ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé látinú àwọn ìtẹ̀jáde wa, ńṣe la máa rí bí “igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀, èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ.”—Sm. 1:2, 3.

4 Jèhófà tún máa ń lo àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti di “àrànṣe afúnnilókun” fún wa. (Kól. 4:10, 11) Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ará wọ̀nyí, àlàyé tí wọ́n máa ń ṣe bí wọ́n bá ń dáhùn nínú apá tó jẹ́ ìbéèrè àti ìdáhùn tàbí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nípàdé àti iṣẹ́ tí wọ́n máa ń ṣe lórí pèpéle máa ń gbé wa ró. (Ìṣe 15:32) Mélòó la fẹ́ sọ nípa báwọn alàgbà ṣe máa ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa lókun, tí wọ́n sì máa ń tipasẹ̀ ọ̀rọ̀ ìṣírí sọ agbára wa dọ̀tun.—Ais. 32:1, 2.

5 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Bó o bá kíyè sí i pé ó ti ń rẹ̀ ọ́, má ṣe dẹ́kun láti máa wàásù! Láìdàbí ọ̀pọ̀ àwọn ìgbòkègbodò míì, lílọ sóde ẹ̀rí déédéé máa ń sọ agbára wa dọ̀tun. (Mát. 11:28-30) Wíwàásù ìhìn rere máa ń jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ ká lè fi ìyè àìnípẹ̀kun àtàwọn nǹkan mèremère míì tí Ọlọ́run máa ṣe fún wa sọ́kàn.

6 Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ṣì wà tá a máa ṣe kí ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó o ròkun ìgbàgbé. Níwọ̀n ìgbà tá a bá ti “gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè,” kò sí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ aláìdúróṣinṣin lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. (1 Pét. 4:11) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a óò kẹ́sẹ járí lẹ́nu iṣẹ́ wa, ó ṣe tán, òun lẹni tí “ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.”—Aís. 40:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́