Jèhófà ‘Ń Fi Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìgbàgbọ́ Bọ́ Wa’
1 Ó gba ìsapá gidi kéèyàn tó lè jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ nígbèésí ayé. (1 Tím. 4:7-10) Bí a bá gbójú lé agbára wa, kò ní pẹ́ tó fi máa rẹ̀ wá tá a ó sì ṣubú. (Aísá. 40:29-31) Ọ̀nà kan tá a fi lè gba okun látọ̀dọ̀ Jèhófà ni pé ká jẹ́ ẹni “tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́.”—1 Tím. 4:6.
2 Oúnjẹ Tẹ̀mí Tó Ń Fúnni Lókun: Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fúnni lókun. (Mát. 24:45) Ǹjẹ́ à ń ṣe ohun tó yẹ ká ṣe káwọn oúnjẹ yẹn lè ṣe wá lóore? Ṣé a kì í jẹ́ kí ọjọ́ kan lọ láìjẹ́ pé a ka Bíbélì? Ǹjẹ́ a ní àkókò kan tá a yà sọ́tọ̀ láti máa fi dá kẹ́kọ̀ọ́ àti láti máa fi ṣàṣàrò? (Sm. 1:2, 3) Irú àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fúnni lókun yìí máa ń fún wa lókun, kì í sì í jẹ́ kí ayé Sátánì rí wa gbéṣe. (1 Jòh. 5:19) Tí a bá ń fọkàn wa ro àwọn ohun tó tọ́ tá a sì ń hù ú níwà nígbà gbogbo, Jèhófà á dúró tì wá.—Fílí. 4:8, 9.
3 Ìpàdé ìjọ tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà gbà ń fún wa lókun. (Héb. 10:24, 25) Ìtọ́ni tẹ̀mí tá a ń rí gbà láwọn ìpàdé wọ̀nyí àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó gbámúṣé tá a ń ní níbẹ̀ ń jẹ́ ká lè dúró ṣinṣin lásìkò ìṣòro. (1 Pét. 5:9, 10) Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Kò sọ́jọ́ tí mo lọ síléèwé tí kì í ṣe pé ìrẹ̀wẹ̀sì ni màá bá bọ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ìpàdé ìjọ wa yàtọ̀, ńṣe ló dà bí ibòji nínú oòrùn ọ̀sán ganrínganrín, nítorí ó ń jẹ́ kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn láti lè kojú wàhálà iléèwé lọ́jọ́ kejì.” Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá gbáà là ń rí gbà bá a ti ń sapá láti wà ní gbogbo ìpàdé!
4 Máa Polongo Òtítọ́: Iṣẹ́ ìwàásù dà bí oúnjẹ lójú Jésù, nítorí pé ó máa ń fún un lókun. (Jòh. 4:32-34) Lọ́nà kan náà, ara wa máa ń yá gágá nígbà tá a bá ń sọ àwọn àgbàyanu ìlérí Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn. Dídí tọ́wọ́ wa ń dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún ń jẹ́ ká lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn ìbùkún tó máa mú wá fún wa láìpẹ́. Ká sòótọ́, ó máa ń sọ agbára wa dọ̀tun.—Mát. 11:28-30.
5 Àǹfààní ńlá la ní o pé à ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tó ń fúnni lókun tí Jèhófà ń pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀ lónìí! Nítorí náà, títí láé ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa fi ìdùnnú polongo òtítọ́ láti fi yìn ín.—Aísá. 65:13, 14.