“Tí A Mú Gbára Dì Pátápátá fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
1 Àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí ni a fi ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ dídọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí bù kún. (Aísá. 25:6) Ọ̀pọ̀ àkójọ ọ̀rọ̀ tí a mú jáde láti inú Ìwé Mímọ́ ni ó wà tí a lè gbádùn nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti ní àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀. Ṣùgbọ́n, a ha ń lo àǹfààní àwọn ìpèsè yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú ète dídi ẹni tí ó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo” bí?—2 Tím. 3:17.
2 Ṣáà ronú nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ oúnjẹ tẹ̀mí fún ọdún 1998, èyí tí ó ti kọjá ìlàjì! Nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a ń jíròrò mélòó kan nínú àwọn kókó ìtẹnumọ́ láti inú ìwé 23 nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a ń ṣàtúnyẹ̀wò ìsọfúnni tí ó wà nínú Awọn Akori Ọrọ Bibeli fun Ijiroro, a sì ń gbé àwọn kókó ẹ̀kọ́ tí a yàn láti inú àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti 1996 yẹ̀ wò. A tún ti ṣàtúnyẹ̀wò ìdá mẹ́ta ìwé Ìmọ̀, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí ìwé Ayọ̀ Ìdílé, a sì ti kárí ìwé pẹlẹbẹ náà, Ète Igbesi-Aye àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? látòkè délẹ̀. Ní àfikún sí i, a ń fi ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa 12, àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ 52, àti onírúurú ọ̀rọ̀ àsọyé lórí kókó ẹ̀kọ́ inú Bíbélì tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 52 bọ́ wa. Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àti àpéjọ dídọ́ṣọ̀ tún jẹ́ àfikún sí gbogbo èyí. Àwọn ohun rere nípa tẹ̀mí tí a pèsè fún wa mà pọ̀ jaburata o!
3 Fi Ìmọrírì Hàn Fún Àwọn Ìpèsè Jèhófà: Kí a lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó yẹ kí a lóye ìdí tí Jèhófà fi pèsè ohun rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ nípa tẹ̀mí. Fífi àwọn ohun rere wọ̀nyí bọ́ ara wa ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró, ó sì ń fún ipò ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ lókun. (1 Tím. 4:6) Àmọ́ ṣá o, a kò pèsè oúnjẹ tẹ̀mí kìkì fún ìtọ́ni wa nìkan. Ó ń sún wa láti ṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ó sì ń mú wa gbára dì láti jẹ́ ẹni tí ó jáfáfá ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere.—2 Tím. 4:5.
4 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣàìnáání àìní wa nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n kí a máa yán hànhàn nígbà gbogbo fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí ó dọ́ṣọ̀, tí ó sì ń tẹ́ni lọ́rùn, tí ń wá láti orí tábìlì Jèhófà. (Mát. 5:3; 1 Pét. 2:2) Láti jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ń béèrè pé kí a ya àkókò tí ó pọ̀ tó sọ́tọ̀ fún irú àwọn nǹkan pàtàkì bí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé àti lílọ sí ìpàdé déédéé. (Éfé. 5:15, 16) Àwọn èrè tí ń múni láyọ̀ fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìṣírí tí a mí sí tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sínú Hébérù 13:20, 21.