ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/07 ojú ìwé 1
  • Ẹ Máa Bá A Lọ ní “Síso Èso Púpọ̀”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Bá A Lọ ní “Síso Èso Púpọ̀”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Máa So Eso Púpọ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Béèyàn Ṣe Lè Dà Bí Ẹ̀ka Tó Ń So Èso, Kó sì Di Ọ̀rẹ́ Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • “Bójú Tó Àjàrà Yìí”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 6/07 ojú ìwé 1

Ẹ Máa Bá A Lọ ní “Síso Èso Púpọ̀”

1 Nínú àpèjúwe kan, Jésù fi ara rẹ̀ wé àjàrà tòótọ́, ó fi Baba rẹ̀ wé Aroko, ó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí ẹ̀mí yàn wé àwọn ẹ̀ka àjàrà tó ń so èso. Nígbà tí Jésù ń sọ nípa iṣẹ́ tí Bàbá rẹ̀ tó jẹ́ Aroko máa ń ṣe, ó tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ ẹ̀ka lára àjàrà náà. (Jòh. 15:1-4) Ẹ̀kọ́ tí èyí kọ́ wa ni pé gbogbo ẹni tó bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà gbọ́dọ̀ dà bí ẹ̀ka tí ń so èso lára “àjàrà tòótọ́” náà, ìyẹn Jésù Kristi. A gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti máa so “èso ti ẹ̀mí” àti èso ti Ìjọba Ọlọ́run lọ́pọ̀ yanturu.—Gál. 5:22, 23; Mát. 24:14; 28:19, 20.

2 Èso ti Ẹ̀mí: Ọ̀kan pàtàkì lára ọ̀nà tá a lè gbà mọ̀ bá a bá ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run ni pé ká jẹ́ kí àpẹẹrẹ èso tẹ̀mí máa hàn nínú ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbé ayé wa. Ǹjẹ́ ò ń ṣe ipa tìrẹ láti jẹ́ kí àpẹẹrẹ èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa hàn gbangba nínú ìgbésí ayé rẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé àti nípa ṣíṣàṣàrò lé e lórí? (Fílí. 1:9-11) Má ṣe jáfara láti máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ kó o bàa lè ní àwọn ànímọ́ táá jẹ́ kó o lè máa fògo fún Jèhófà kó o sì lè máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run.—Lúùkù 11:13; Jòh. 13:35.

3 Bá a bá ń jẹ́ kí àpẹẹrẹ èso ẹ̀mí mímọ́ máa fara hàn nínú ìgbésí ayé wa, ó tún máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tó nítara. Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ máa ń mú ká máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láìfi ti ọwọ́ wa tó máa ń dí pè. Àwọn ànímọ́ bí àlàáfíà, ìfaradà, inúure, ìwà pẹ̀lẹ́ àti ìkóra-ẹni-níjàánu máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ìhà tó tọ́ ká kọ sáwọn alátakò. Ayọ̀ máa ń mú ká ní ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ìsìn wa kódà nígbà táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́.

4 Èso Ti Ìjọba Ọlọ́run: Ó tún yẹ ká máa so èso ti Ìjọba Ọlọ́run. Èyí sì ní nínú rírú “ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ [Jèhófà].” (Héb. 13:15) Ọ̀nà tá a sì lè gbà ṣe èyí ni nípa wíwàásù ìhìn rere tìtaratìtara láìyẹsẹ̀. Ṣé ò ń sapá láti máa túbọ̀ so èso Ìjọba Ọlọ́run nípa fífikún ìwọ̀n tó ò ń ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

5 Jésù fi hàn pé ìwọ̀n èso táwọn ọmọlẹ́yìn òun tó jẹ́ olùṣòtítọ́ á máa so á yàtọ̀ síra. (Mát. 13:23) Nítorí náà, dípò tí a ó fi máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn, ńṣe ni ká rí i pé gbogbo ohun tí agbára wa ká là ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà. (Gál. 6:4) Bá a bá ń fi òtítọ́ inú yẹ ara wa wò níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní fífògo fún Jèhófà nípa “síso èso púpọ̀.”—Jòh. 15:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́