ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w20 June ojú ìwé 17
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé ẹ Óò Máa Bá a Lọ Láti “Rìn Nípa Ẹ̀mí”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ṣé Ò Ń jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ẹ Máa Bá A Lọ ní “Síso Èso Púpọ̀”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Máa Fi “Ìwà Tuntun” Wọ Ara Rẹ Láṣọ Lẹ́yìn Tó O Ti Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
w20 June ojú ìwé 17

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó wà nínú Gálátíà 5:​22, 23 nìkan ni “èso ti ẹ̀mí”?

  • ÌFẸ́

  • AYỌ̀

  • ÀLÀÁFÍÀ

  • SÙÚRÙ

  • INÚ RERE

  • ÌWÀ RERE

  • ÌGBÀGBỌ́

  • ÌWÀ TÚTÙ

  • ÌKÓRA-ẸNI-NÍJÀÁNU

Ànímọ́ mẹ́sàn-án péré ni ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó ní: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Àmọ́ kò yẹ ká wá ronú pé àwọn ànímọ́ yìí nìkan ni ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká ní.

Ẹ kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní ẹsẹ tó ṣáájú pé: “Àwọn iṣẹ́ ti ara . . . ni ìṣekúṣe, ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, ìmutíyó, àwọn àríyá aláriwo, àti irú àwọn nǹkan yìí.” (Gál. 5:​19-21) Gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù sọ kẹ́yìn yìí fi hàn pé àwọn nǹkan míì wà tó jẹ́ “iṣẹ́ ti ara” bó ṣe wà nínú Kólósè 3:5. Bákan náà, lẹ́yìn tó mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó para pọ̀ jẹ́ èso tẹ̀mí, ó sọ pé: “Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí.” Torí náà, kì í ṣe gbogbo ànímọ́ dáadáa tí ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká ní ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà.

Kókó yìí túbọ̀ ṣe kedere tá a bá fi wé ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Éfésù, ó ní: “Oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ ló jẹ́ èso ìmọ́lẹ̀.” (Éfé. 5:​8, 9) Àbí ẹ ò rí nǹkan, bí “ohun rere” tàbí ìwà rere, òdodo àti òtítọ́ ṣe jẹ́ apá kan “èso ìmọ́lẹ̀” náà ló jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí.”

Bákan náà, Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì pé kó “máa wá òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà àti ìwà tútù.” (1 Tím. 6:11) Nínú àwọn ànímọ́ mẹ́fà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà yìí, mẹ́ta péré (ìyẹn ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìwà tútù) ló jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí.” Ó dájú pé Tímótì máa nílò kí ẹ̀mí Ọlọ́run ràn án lọ́wọ́ kó lè ní àwọn ànímọ́ mẹ́ta tó kù náà, ìyẹn òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run àti ìfaradà.​—Fi wé Kólósè 3:12; 2 Pétérù 1:​5-7.

Torí náà, kì í ṣe àwọn ànímọ́ tó wà nínú Gálátíà 5:​22, 23 nìkan ló yẹ kí Kristẹni ní. Kò sí àní-àní pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ mẹ́sàn-án tó para pọ̀ jẹ́ “èso ti ẹ̀mí.” Àmọ́ àwọn ànímọ́ míì wà tó yẹ ká ní bá a ṣe ń dàgbà nípa tẹ̀mí ká lè “gbé ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”​—Éfé. 4:24.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́