A Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tá A Ní!
1 Látìgbà táráyé ti ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yìí, àìmọye àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lónírúurú ni Jèhófà ti fà lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tó bá ń fún wọn láwọn àǹfààní náà, kì í wo ti bóyá wọ́n jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, kì í wo tọjọ́ orí, kì í sì í wo ti ipò tí wọ́n wà láwùjọ. (Lúùkù 1:41, 42; Ìṣe 7:46; Fílí. 1:29) Àwọn àǹfààní wo ló tiẹ̀ fà lé àwa náà lọ́wọ́ lónìí?
2 Díẹ̀ Lára Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tá A Ní: Àǹfààní kan ni pé Jèhófà ń kọ́ wa. (Mát. 13:11, 15) Àǹfààní mìíràn ni bá a ṣe máa ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ jáde láwọn ìpàdé ìjọ, èyí tó jẹ́ ọ̀nà kan láti yin Jèhófà. (Sm. 35:18) Ìyẹn ló ṣe jẹ́ pé tìtaratìtara la fi ń dáhùn nígbà tá a bá láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, bá a bá ka iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún wa nínú ìjọ sí pàtàkì, a ó lè máa sapá láti ṣe é dáadáa. Níwọ̀n bí ṣíṣàtúnṣe tó yẹ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àti mímú kó wà ní mímọ́ ti jẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, ǹjẹ́ a máa ń ṣe é ní gbogbo ìgbà?
3 Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ mìíràn tá a tún ní ni pé, Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run ń gbọ́ àdúrà wa, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò tíì dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ tiwọn. (Òwe 15:29) Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa ń fetí sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kì í fi rán ẹnikẹ́ni. (1 Pét. 3:12) Kì í fìwọ̀n sí iye ìgbà tá a gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí òun. Ẹ ò rí i pé àǹfààní tó yẹ ká kà sí pàtàkì gan-an ni, pé ó ṣeé ṣe fún wa láti máa gbàdúrà “ní gbogbo ìgbà”!—Éfé. 6:18.
4 “Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run”: Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní tó ṣe pàtàkì jù tá a ní gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” ni wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 3:9) Iṣẹ́ tó ń fèèyàn lọ́kàn balẹ̀ ni, ó sì máa ń tuni lára. (Jòh. 4:34) Kò pọn dandan kí Jèhófà lo àwa èèyàn láti ṣiṣẹ́ náà, ṣùgbọ́n nítorí ìfẹ́ tó ní sí wa, àwa ló faṣẹ́ náà lé lọ́wọ́. (Lúùkù 19:39, 40) Àmọ́ o, kì í ṣe ẹnikẹ́ni tí Jèhófà bá rí ló ń fún láǹfààní yìí. Àwọn tó bá máa ṣiṣẹ́ ìwàásù gbọ́dọ̀ dé ojú ìlà àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè fún, kí wọ́n sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. (Aísá. 52:11) Ṣé à ń fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí nípa rírí i dájú pé a ò pa ọ̀sẹ̀ kan jẹ láìlọ sóde ẹ̀rí?
5 Àwọn àǹfààní tí Jèhófà ń fún wa yìí máa ń mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀. (Òwe 10:22) Láé, a ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn àǹfààní náà! Bá a bá ń ṣe ohun tó ń fi hàn pé lóòótọ́ la mọyì àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní, a ó lè máa múnú Baba wa ọ̀run dùn, Ẹni tó ń fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.”—Ják. 1:17.