ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 10/15 ojú ìwé 23-27
  • Máa Ṣìkẹ́ Àǹfààní Tó O Ní Láti Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣìkẹ́ Àǹfààní Tó O Ní Láti Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWA ÈÈYÀN ŃKỌ́?
  • MÁA FI OJÚ TÍ Ó TỌ́ WO IṢẸ́ TÍ JÈHÓFÀ YÀN FÚN Ẹ
  • MÁA GBÁDÙN ÀǸFÀÀNÍ TÍ O NÍ LÁTI JẸ́ ALÁBÀÁṢIṢẸ́PỌ̀ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ!
  • À Ń Láyọ̀ Bá A Ṣe Ń Bá Ọlọ́run Ṣiṣẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • A Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tá A Ní!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Mọyì Ojúṣe Rẹ Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 10/15 ojú ìwé 23-27

Máa Ṣìkẹ́ Àǹfààní Tó O Ní Láti Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Jèhófà!

“Àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—1 KỌ́R. 3:9.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Àǹfààní wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti máa ń ní látọjọ́ tó ti pẹ́?

  • Iṣẹ́ wo ló yẹ ká ṣìkẹ́ jù lọ báyìí?

  • Kí ni ohun tí à ń fayọ̀ retí lọ́jọ́ ọ̀la?

1. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo iṣẹ́, kí sì nìyẹn mú kó ṣe?

JÈHÓFÀ máa ń láyọ̀ nídìí iṣẹ́ tó ń ṣe. (Sm. 135:6; Jòh. 5:17) Ó fẹ́ káwọn ẹ̀dá olóye tí òun dá máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ wọn, kínú wọn sì máa dùn pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ wọn láṣeyọrí. Torí náà, ó yan iṣẹ́ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń tuni lára fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń ṣẹ̀dá àwọn nǹkan ó pe àkọ́bí Ọmọ rẹ mọ́ra kí wọ́n lè jọ ṣe é. (Ka Kólósè 1:15, 16.) Bíbélì sọ fún wa pé kí Jésù tó wá sáyé, ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lókè ọ̀run “gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́.”—Òwe 8:30.

2. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì tó ń múnú wọn dùn?

2 Àpẹẹrẹ lóríṣiríṣi wà nínú Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń yan iṣẹ́ fáwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ tí Ọlọ́run sì lé wọn jáde nínú párádísè tí wọ́n ń gbé, Ọlọ́run “yan àwọn kérúbù sí ìlà-oòrùn ọgbà Édẹ́nì àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.” (Jẹ́n. 3:24) Bákan náà, ìwé Ìṣípayá 22:6 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde láti fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ han àwọn ẹrú rẹ̀.”

ÀWA ÈÈYÀN ŃKỌ́?

3. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, báwo ló ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀?

3 Nígbà tí Jésù wà láyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, ó fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún un. Ó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ ní ti pé ó yan iṣẹ́ pàtàkì fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ kí wọ́n máa fi ìháragàgà retí ohun tí wọ́n máa lè gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó ní: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí, nítorí pé mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.” (Jòh. 14:12) Kí Jésù lè jẹ́ kí wọ́n mọ bí iṣẹ́ náà ti jẹ́ kánjúkánjú tó, ó sọ fún wọn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀sán; òru ń bọ̀ nígbà tí ènìyàn kankan kò lè ṣiṣẹ́.”—Jòh. 9:4.

4-6. (a) Kí nìdí tá a fi dúpẹ́ pé Nóà àti Mósè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn? (b) Kí ni gbogbo iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fáwọn èèyàn máa ń yọrí sí?

4 Kódà, kí Jésù tó wá sáyé ni Ọlọ́run ti ń yan iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ fáwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà kò ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn, àwọn èèyàn míì wà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn gẹ́gẹ́ bó ṣe ní kí wọ́n ṣe é. (Jẹ́n. 1:28) Jèhófà fún Nóà ní ìtọ́ni pàtó nípa bó ṣe máa kan áàkì tí Ọlọ́run máa lò láti dá ẹ̀mí àwọn èèyàn sí nígbà Àkúnya omi ńlá náà. Ó fara balẹ̀ ṣe gbogbo nǹkan tí Jèhófà ní kó ṣe. Àwa rèé lónìí, torí pé Nóà ṣe gbogbo nǹkan tí Jèhófà ní kó ṣe, ó ṣe é dórí bíńtín!—Jẹ́n. 6:14-16, 22; 2 Pét. 2:5.

5 Jèhófà fún Mósè ní ìtọ́ni pàtó nípa bí ó ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn àti bó ṣe máa ṣètò iṣẹ́ àlùfáà, gbogbo ìtọ́ni yìí ló sì tẹ̀ lé. (Ẹ́kís. 39:32; 40:12-16) Kódà títí dòní, à ń jàǹfààní nínú bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. Lọ́nà wo? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé àwọn apá tí Òfin pín sí jẹ́ àpẹẹrẹ “ohun rere tí ń bọ̀.”—Héb. 9:1-5, 9; 10:1.

6 Bí Jèhófà ṣe ń mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ó máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní iṣẹ́ tó yàtọ̀ síra látìgbàdégbà. Gbogbo ìgbà sì ni iṣẹ́ tó ń yàn fún wọn yìí máa ń fògo fún un, ó sì máa ń ṣe àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ láǹfààní. Èyí ṣe kedere nínú àwọn ohun tí Jésù gbé ṣe kó tó di pé ó wá sáyé àti nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 4:34; 17:4) Lọ́nà kan náà, iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa lóde òní máa ń fi ògo fún Jèhófà. (Mát. 5:16; ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

MÁA FI OJÚ TÍ Ó TỌ́ WO IṢẸ́ TÍ JÈHÓFÀ YÀN FÚN Ẹ

7, 8. (a) Ṣàpèjúwe iṣẹ́ táwọn Kristẹni lóde òní láǹfààní láti máa ṣe. (b) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Jèhófà?

7 Wàá gbà pé ohun ìyanu gbáà ló jẹ́ bí Jèhófà ṣe fún àwọn èèyàn ní àǹfààní ńlá náà pé kí wọ́n wá jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ òun. (1 Kọ́r. 3:9) Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé irú èyí tí Nóà àti Mósè ṣe, irú bí àwọn tó ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ṣìkẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní yìí, yálà iṣẹ́ rẹ jẹ́ láti máa ṣe àtúnṣe sáwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí o wà lára àwọn tó ń kọ́ orílé-iṣẹ́ wa tó wà ní Warwick, ní ìpínlẹ̀ New York. (Wo bí orílé-iṣẹ́ wa ṣe máa rí nínú àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ni. Àmọ́, iṣẹ́ tó gbawájú jù lọ táwa Kristẹni ń ṣe ni iṣẹ́ ìkọ́lé tẹ̀mí tó ń lọ lọ́wọ́. Iṣẹ́ yìí ń fi ògo fún Jèhófà, ó sì ń ṣe àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn láǹfààní. (Ìṣe 13:47-49) Ètò Ọlọ́run máa ń tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ bó ṣe yẹ ká máa ṣe iṣẹ́ náà. Nígbà míì, èyí lè yọrí sí pé kí iṣẹ́ tí ètò Ọlọ́run yàn fún wa yí pa dà.

8 Tipẹ́tipẹ́, làwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí máa ń múra tán láti gba ibi tí ètò Ọlọ́run bá darí wọn sí. (Ka Hébérù 13:7, 17.) Ètò Ọlọ́run lè fún wa ní ìtọ́ni pàtó nípa iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wa, àmọ́ a lè máà kọ́kọ́ lóye ìdí tí wọ́n fi ní ká ṣe é bẹ́ẹ̀. Ohun tá a mọ̀ dájú ni pé ó máa ṣe wá láǹfààní tá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà nínú àyípadà èyíkéyìí tó bá rí i pé ó yẹ láti ṣe.

9. Àpẹẹrẹ wo làwọn alàgbà ń fi lélẹ̀ fún ìjọ?

9 Ọwọ́ tí àwọn alàgbà fi mú ọ̀rọ̀ ìjọ jẹ́ ká rí i pé ó ń wù wọ́n gan-an láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. (2 Kọ́r. 1:24; 1 Tẹs. 5:12, 13) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn múra tán láti sa gbogbo ipá àwọn, wọ́n sì ń mú ara wọn bá onírúurú ipò mu. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tuntun tí ètò Ọlọ́run bá fún wa lórí ọ̀nà tá a lè gbà máa wàásù Ìjọba tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀. Nígbà míì, wọ́n lè kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti ṣètò pé káwọn ará máa wàásù ní pápákọ̀ etíkun, láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí àti ìjẹ́rìí orí fóònù, àmọ́ wọ́n máa ń rí i nígbà tó bá yá pé ó ń yọrí sí rere. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́rin kan lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ wàásù lágbègbè kan táwọn èèyàn ti ń ṣe okòwò, àmọ́ tí wọn kì í sábà wàásù débẹ̀. Michael sọ pé: “Ẹ̀rù ń bà wá, ìdí sì ni pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn la ti wàásù nírú àgbègbè yìí kẹ́yìn. Àmọ́, mánigbàgbé ni iṣẹ́ ìwàásù wa láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, ó ní láti jẹ́ pé Jèhófà ti mọ̀ pé ẹ̀rù ń bà wá. Inú wa dùn gan-an pé a tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, a sì gbára lé Jèhófà!” Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọ̀nà tuntun kan tó o lè gbà wàásù ní àgbègbè rẹ yọjú, ṣé wàá gbìyànjú rẹ̀ wò?

10. Àwọn àyípadà wo ló wáyé nínú ètò Ọlọ́run lẹ́nu àìpẹ́ yìí?

10 Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan kí àyípadà wáyé nínú ètò Ọlọ́run. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì. Èyí gba pé káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wọ̀nyí ṣe àwọn àyípadà, àmọ́ kò pẹ́ rárá tí gbogbo wọn fi rí àǹfààní tó wà nínú àyípadà náà. (Oníw. 7:8) Inú àwọn tó múra tán láti ṣe àwọn àyípadà náà máa ń dùn gan-an pé àwọn kópa nínú ìtàn àwa èèyàn Jèhófà lóde òní!

11-13. Àwọn ìṣòro wo ló dojú kọ àwọn kan torí àwọn àyípadà tó wáyé nínú ètò Ọlọ́run?

11 A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára àwọn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ti ń sìn wà lára èyí tí wọ́n pa pọ̀ mọ́ ti orílẹ̀-èdè míì. Àwọn míì lára wọn ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Ètò Ọlọ́run sọ pé kí tọkọtaya kan tí wọ́n ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kékeré tó wà ní Amẹ́ríkà Àárín lọ dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Iye àwọn tó ń sìn níbẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po ọgbọ̀n sí iye àwọn tó wà ní ẹ̀ka tí tọkọtaya náà ti ń sìn tẹ́lẹ̀. Rogelio ni orúkọ ọkọ, ó sọ pé: “Ojú ro wá gan-an láti fi àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wa sílẹ̀.” Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Juan, tí wọ́n gbé òun náà lọ sí Mẹ́síkò sọ pé: “Ó dà bí ìgbà tí wọ́n tún èèyàn bí lẹ́ẹ̀kejì, wàá tún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í láwọn ọ̀rẹ́ míì. Ó gba pé kéèyàn kọ́ àwọn àṣà tuntun àti báwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe ń ronú.”

12 Bákan náà, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì láwọn orílẹ̀-èdè kan tó wà nílẹ̀ Yúróòpù, tí wọ́n lọ dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì láwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ. Ẹni tó bá fẹ́ràn kó máa wo àwọn òkè ńláńlá tó rẹwà máa gbà lóòótọ́ pé kò rọrùn fáwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Switzerland láti kúrò ní àgbègbè tí àwọn òkè tí ó rẹwà yí ká. Kò sì kọ́kọ́ rọrùn fáwọn tó wà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà láti kúrò lágbègbè tí nǹkan ti tù wọ́n lára.

13 Àwọn tó ń kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì ní láti ṣe ọ̀pọ̀ àyípadà. Torí pé, ilé wọn ti yàtọ̀ báyìí, wọ́n á máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọn kò mọ̀ rí, ó sì lè gba pé kí iṣẹ́ wọn yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìjọ tuntun, wọ́n á sì máa wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun, kódà ó tún lè gba pé kí wọ́n kọ́ èdè tuntun. Àwọn àyípadà yìí lè má rọrùn rárá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ló ṣe àwọn àyípadà yìí tayọ̀tayọ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀?

14, 15. (a) Báwo làwọn kan ṣe fi hàn pé àwọn ṣìkẹ́ àǹfààní táwọn ní láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jèhófà láìka irú iṣẹ́ ìsìn tó jẹ́ sí? (b) Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa?

14 Arábìnrin Grethel sọ pé: “Mo gbà láti lọ torí mo fẹ́ fìyẹn sọ fún Jèhófà pé ìfẹ́ tí mo ní fún un ló ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe orílẹ̀-èdè tí mo wà tàbí ilé tí mò ń gbé tàbí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí mo ní.” Arábìnrin Dayska sọ pé: “Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi gbà á torí Jèhófà ló rán mi níṣẹ́.” André àti Gabriela náà sọ pé: “A rí àǹfààní míì tó ṣí sílẹ̀ fún wa láti sin Jèhófà, torí ṣe la gbé àwọn ohun tó wù wá tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.” Wọ́n gbà gbọ́ pé tí Jèhófà bá ti sọ pé ó yá àfi kéèyàn yára tẹ̀ lé e, ká má ṣe ṣàwáwí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún wa—láti máa ṣe iṣẹ́ Jèhófà!

15 Láwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti pa àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì pọ̀, ètò Ọlọ́run ní káwọn kan tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tẹ́lẹ̀ lọ máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Denmark, Norway àti Sweden para pọ̀ di ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Scandinavia, ọ̀pọ̀ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tẹ́lẹ̀ ni wọ́n rán lọ sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ọ̀kan lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Florian àti Anja, wọ́n sọ pé: “A wò ó pé adùn wà nínú àyípadà tó bá wa yìí. A gbà pé ibikíbi tí Jèhófà bá sọ pé òun ti fẹ́ lò wá, àǹfààní ńlá ló jẹ́. A lè sọ tọkàntọkàn pé ìbùkún Jèhófà lórí wa pọ̀ jaburata!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wa lè máà bá ara wa nínú irú ipò táwọn arákùnrin àti arábìnrin yìí wà, àmọ́ a lè fi hàn pé a ní ẹ̀mí ìmúratán ká sì fi Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́ bíi tiwọn. (Aísá. 6:8) Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣìkẹ́ àǹfààní tí wọ́n ní láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, ní ibi yòówù kí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ sìn ín.

MÁA GBÁDÙN ÀǸFÀÀNÍ TÍ O NÍ LÁTI JẸ́ ALÁBÀÁṢIṢẸ́PỌ̀ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ!

16. (a) Kí ni Gálátíà 6:4 sọ pé ká ṣe? (b) Kí ni àǹfààní tó ga jù lọ tí èèyàn lè ní?

16 Èèyàn aláìpé sábà máa ń fi ara wọn wé àwọn mìíràn, àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé ká fọkàn wa sí ohun tá a lè ṣe. (Ka Gálátíà 6:4.) Ọ̀pọ̀ nínú wa kò ní ipò àṣẹ kankan nínú ètò Ọlọ́run. Bákan náà, gbogbo wa ò lè jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì tàbí ká sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Kò sírọ́ níbẹ̀ pé àǹfààní gidi làwọn iṣẹ́ ìsìn yìí jẹ́! Àmọ́, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé gbogbo wa pátá la ní àǹfààní kan tó ga jù. Èyí ni bá a ṣe jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó yẹ ká ṣìkẹ́ àǹfààní yìí!

17. Kí lohun táá máa ṣẹlẹ̀ níwọ̀n bí a bá ṣì wà nínú ayé Sátánì yìí, àmọ́ kí nìdí tí kò fi yẹ ká jẹ́ kó bà wá lọ́kàn jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ?

17 Níwọ̀n bí a bá ṣì wà nínú ayé Sátánì yìí, ọwọ́ wa lè má tẹ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó wù wá. Nígbà míì, ojúṣe ìdílé, àìlera àtàwọn ipò míì lè fa ìdíwọ́ fún wa. Àmọ́, kò yẹ ká jẹ́ kí ìyẹn bà wá lọ́kàn jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ. Má ṣe fojú kéré àǹfààní tó o ní láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti jẹ́rìí nípa orúkọ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, o sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run máa bù kún ìsapá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n lè ṣe jù ẹ́ lọ. Má gbàgbé pé gbogbo àwọn tó ń yin orúkọ Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀!

18. Kí ló yẹ ká múra tán láti gbé tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí sì nìdí?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwa, tí a sì jẹ́ aláìpé, Jèhófà ṣì fẹ́ ká jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú òun. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká ṣìkẹ́ àǹfààní tá a ní láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọjọ́ ìkẹyìn yìí! Torí náà, ó yẹ ká múra tán láti gbé àwọn ohun tó wù wá tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, torí a mọ̀ pé Jèhófà máa fún wa ní “ìyè tòótọ́” nínú ayé tuntun Jèhófà, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tá a ti máa láyọ̀, tí a sì máa wà ní àlàáfíà.—1 Tím. 6:18, 19.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ǹjẹ́ ò ń ṣìkẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní? (Wo ìpínrọ̀ 16 sí 18)

19. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú?

19 Bó ṣe ń ku díẹ̀ ká wọ ayé tuntun yìí, ẹ ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ó ní: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì mú kí o ní àníṣẹ́kù nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Diu. 30:9) Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run yóò jogún ilẹ̀ tó ti ṣèlérí fún wọn. Lẹ́yìn náà, a máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tuntun, ìyẹn láti sọ ayé di Párádísè!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́