Fi Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ṣe Àfojúsùn Rẹ
1 “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Ohun tí Jésù Kristi sọ nígbà yẹn bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu.
2 Ojoojúmọ́ la túbọ̀ ń rí àwọn èèyàn tó mọyì òtítọ́, tí wọ́n sì ń fẹ́ mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tó ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún ń jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo fẹ́ máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló yẹ kó o ṣe?
3 Ní Ohun Tó Ò Ń Fojú Sùn: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rí i dájú pé o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé. Má gbà gbé ohun tó ò ń fojú sùn yìí nígbàkigbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí. Níwọ̀n bí wíwàásù àti kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ti wà lára iṣẹ́ tá a gbé lé àwa Kristẹni lọ́wọ́, gbogbo wa ló yẹ ká túbọ̀ máa sapá láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
4 Àwọn Nǹkan Míì Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn: Pàtàkì lọ̀rọ̀ àdúrà àtọkànwá fún gbogbo akéde Ìjọba Ọlọ́run. Ìgbà míì wà tá a máa ń ṣalábàápàdé àwọn èèyàn tó ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè lóye Bíbélì. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni lílò tí Jèhófà ń lò wá láti wá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rí, ká sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́!—Hág. 2:7; Ìṣe 10:1, 2.
5 Lẹ́yìn tí arábìnrin kan ti gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, ó kó ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? síbi táwọn èèyàn ti lè rí i níbi iṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí obìnrin kan mú ọ̀kan lára ìwé àṣàrò kúkúrú náà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ ọ̀rọ̀ sí àlàfo inú fọ́ọ̀mù tó wà lẹ́yìn rẹ̀, kíá ni arábìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
6 Àwọn akéde tó mọwọ́ bá a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa bá a nìṣó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wàá máa darí. Fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, má sì ṣe jẹ́ kí àǹfààní èyíkéyìí tó lè jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ ohun tó o fojú sùn yìí bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Bó pẹ́ bó yá, wàá ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.