ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/08 ojú ìwé 8
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrẹ̀lẹ́kún Láti Ọ̀dọ̀ “Ọlọrun Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • ‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Tí Ẹni Tó O Fẹ́ràn Bá Kú
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 4/08 ojú ìwé 8

Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú

1. Kí nìdí táwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ fi nílò ìtùnú?

1 Ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ló máa ń báni nígbà téèyàn ẹni bá kú, àgàgà fáwọn tí kò nírètí Ìjọba Ọlọ́run. (1 Tẹs. 4:13) Ọ̀pọ̀ ló máa ń ṣe kàyéfì pé: ‘Kí nìdí téèyàn fi ń kú? Ibo làwọn òkú wà? Ṣé mo tún lè ráwọn èèyàn mi tó ti kú mọ́ báyìí?’ Àwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí fún wa láwọn àbá tá a lè lò láti tu àwọn tá a bá bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣọ̀fọ̀ ikú mọ̀lẹ́bí wọn tàbí ọ̀rẹ́ wọn nínú.—Aísá. 61:2.

2. Ṣé ó dáa ká máa fa ìwàásù wa gùn nígbà tá a bá bá àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ pàdé?

2 Láti Ilé Dé Ilé: Bí onílé kan bá sọ fún wa pé, èèyàn òun kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣaláìsí, a lè bi ara wa pé, ‘Ṣé ìbànújẹ́ ò ti sorí ẹ̀ kodò báyìí? Ṣé àwọn mọ̀lẹ́bí tó ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn wọn tó kú ṣì wà nínú ilé ọ̀hún?’ Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá dára ká jẹ́ kí ìwàásù wá ṣe ṣókí. (Oníw. 3:1, 7) Ká bá a kẹ́dùn, ká wá fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìròyìn tàbí ìwé pẹlẹbẹ tó bá ipò tó wà mu, ká sì rọra fi í sílẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, a lè padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ọkàn rẹ̀ bá ti balẹ̀ díẹ̀ láti fi Bíbélì tù ú nínú.

3. Bó bá ṣeé ṣe, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo la lè kà fún onílé kan tó ń ṣọ̀fọ̀?

3 Nígbà míì ẹ̀wẹ̀, a lè wòye pé àǹfààní ló jẹ́ láti wàásù fáwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Àkókò kọ́ nìyẹn láti máa ta ko ohun tí onílé bá ń sọ, bó bá ṣeé ṣe a lè ka ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìrètí àjíǹde látinú Bíbélì fún un. (Jòh. 5:28, 29) A sì lè fi ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò táwọn òkú wà hàn án. (Oníw. 9:5, 10) Àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde tó wà nínú Bíbélì sì lè jẹ́ orísun ìtùnú. (Jòh. 11:39-44) A tún lè jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tí Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ sọ nípa ìrètí tó ní nínú Jèhófà nípa àjíǹde. (Jóòbù 14:14, 15) Ká tó kúrò níbẹ̀, a lè fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú? tàbí Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, a sì lè fún un ní ìwé pẹlẹbẹ míì tàbí àṣàrò kúkúrú tó bá yẹ. A sì tún lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ká pàfiyèsí rẹ̀ sóhun tó wà ní orí 6, ká sì ṣètò láti padà wá jíròrò kókó náà.

4. Àwọn ìgbà míì wo la lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

4 Láwọn Ìgbà Míì: Ṣé àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí máa wá síbi ààtò ìsìnkú tó fẹ́ wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? A lè ti wá àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó máa tù wọ́n nínú sílẹ̀ fún wọn. Àwọn ilé iṣẹ́ kan tó máa ń bójú tó ìsìnkú ti mọrírì níní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tó ń tu àwọn èèyàn nínú kí wọ́n lè fún àwọn ìdílé olókùú. Àwọn ìkéde ààtò ìsìnkú tó máa ń wà nínú àwọn ìwé ìròyìn ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti kọ ọ̀rọ̀ ìtùnú ní ṣókí sáwọn ìdílé olókùú. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tí ìyàwó rẹ̀ ṣaláìsí gba lẹ́tà àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú díẹ̀, òun àti ọmọ rẹ̀ obìnrin lọ sílé akéde tó fi lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí wọn, ó béèrè pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ fi lẹ́tà yìí ránṣẹ́ sí mi? Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì!” Ọkùnrin yẹn àti ọmọ rẹ̀ gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé ìjọ.

5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àǹfààní èyíkéyìí tó bá ṣí sílẹ̀ láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

5 Oníwàásù 7:2 sọ pé: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè.” Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa ń fẹ́ láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ju àwọn tó ń ṣe fàájì lọ. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa wà lójúfò sí àǹfààní èyíkéyìí tó bá ṣí sílẹ̀ láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́