ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/08 ojú ìwé 1
  • “Ẹ Gba Àjàgà Mi Sọ́rùn Yín”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Gba Àjàgà Mi Sọ́rùn Yín”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àjàgà Mi Jẹ́ Ti Inúrere Ẹrù Mi Sì Fúyẹ́”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jésù Mú Kí Ara Tù Wá
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • “Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Màá sì Tù Yín Lára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Bá a Ṣe Lè Rí Ìtura Nínú Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 5/08 ojú ìwé 1

“Ẹ Gba Àjàgà Mi Sọ́rùn Yín”

1 Nínú ayé tí kòókòó jàn-án-jàn-án àti àníyàn kúnnú ẹ̀ yìí, à ń rí ìtura tòótọ́ gbà torí pé a dáhùn padà sí ìkésíni Jésù pé ká wá gba ìtura lábẹ́ àjàgà tòun. (Mát. 11:29, 30) Iṣẹ́ kan tó ní ìpèníjà tiẹ̀, àmọ́ tó ń mára tuni wà lára ohun tó túmọ̀ sí láti gba àjàgà jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn. Iṣẹ́ náà ní wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti wá máa gbádùn ìtura tá à ń gbádùn lábẹ́ àjàgà onínúure Jésù.—Mát. 24:14; 28:19, 20.

2 Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà Tù Ẹ́ Lára: Jésù ò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun ru ẹrù tiẹ̀ mọ́ èyí tí wọ́n ti ń gbé kiri tẹ́lẹ̀ o, ohun tó ń sọ ni pé, kí wọ́n pa ẹrù ìnira wọn tì, kí wọ́n wá máa gbé tòun tó fúyẹ́. Àwọn àníyàn àti àìnírètí tó wà nínú ètò àwọn nǹkan yìí ò mu wá lómi mọ́ bẹ́ẹ̀ la ò ṣe làálàá mọ́ nítorí ọrọ̀ àìdánilójú. (Lúùkù 21:34; 1 Tím. 6:17) Bọ́wọ́ wa tiẹ̀ dí, tá a sì ní láti ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa bàa lè tẹ́nu, síbẹ̀ ìjọsìn Ọlọ́run làkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. (Mát. 6:33) Tá a bá ń ní èrò tó tọ́ nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ò ní ni wá lára, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lara á máa tù wá pẹ̀sẹ̀.—Fílí. 1:10.

3 Ó sábà máa ń wù wá láti sọ ohun tó bá ṣe pàtàkì lọ́kàn wa fáwọn èèyàn. (Lúùkù 6:45) Ọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ìbùkún tó ṣèlérí pé Ìjọba rẹ̀ máa ṣe fáráyé lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ sáwa Kristẹni. Nítorí náà, ẹ ò rí i bára ti máa tù wá tó tá a bá pa àníyàn wa ojoojúmọ́ tì nígbà tá a bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká lè máa sọ “ìhìn rere àwọn ohun rere” fáwọn èèyàn! (Róòmù 10:15) A mọ̀ pé, bá a bá ṣe ń ṣe nǹkan léraléra tó, la ṣe máa lóye rẹ̀ tó, ayọ̀ wa á sì túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Nítorí náà, ara á túbọ̀ tù wá tá a bá lè fi kún àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ẹ sì tún wo bára ṣe máa tù wá tó táwọn èèyàn tá à ń wàásù fún bá dáhùn padà lọ́nà tó dára! (Ìṣe 15:3) Ká tiẹ̀ wá láwọn èèyàn ò fìfẹ́ hàn sí iṣẹ́ ìwàásù wa tàbí tí wọ́n ń ṣàtakò, síbẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa fún wa ní ìtura tẹ̀mí tá a bá ń fi sọ́kàn pé inú Jèhófà dùn sí ìsapá tá à ń ṣe àti pé òun ló máa mú kí iṣẹ́ náà méso rere wá.—Ìṣe 5:41; 1 Kọ́r. 3:9.

4 Bá a ti tẹ́wọ́ gba ìkésíni Jésù, à ń gbádùn àǹfààní tá a ní láti máa sìn nífẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísá. 43:10; Ìṣí. 1:5) Kò sóhun tó tún lè tuni lára bí èyí!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́