Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ẹ̀yin Akéde Ọ̀wọ́n:
Àtẹ́wọ́ sọ lẹ́yìn tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbọ́ ìfilọ̀ kan láàárọ̀ Monday, February 4, 2008, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́. Bí ìfilọ̀ náà ṣe kà rèé: “Lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, àwọn alága àwọn alábòójútó láti àwọn ìjọ tó wà ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti dé sọ́dọ̀ wa. Gbogbo wọn ti wà ní Patterson báyìí láti bẹ̀rẹ̀ kíláàsì àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ kan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣètò fún àwọn alàgbà ìjọ.”
Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà gbádùn ìfararora tó ń gbéni ró tí wọ́n ní pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n láǹfààní láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ pẹ̀lú ìdílé Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì tún gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń ṣe nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà gbádùn àwọn àkànṣe àsọyé tí ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tó wà ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ, ìyẹn sì wà lára àwọn ohun tó mú kí ilé ẹ̀kọ́ náà lárinrin.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn alàgbà tó láǹfààní láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ló ti fìmọrírì wọn hàn. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìṣírí ńlá ló jẹ́ fún mi láti wà ní Bẹ́tẹ́lì fún odindi ọ̀sẹ̀ kan gbáko!” Arákùnrin míì kọ̀wé pé: “Mo ti gba okun kún okun láti túbọ̀ máa fìtara bójú tó ojúṣe tí mo ní nínú ìjọ.” Ẹ̀kọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ báyìí ṣàlàyé onírúurú apá tó jẹ́ ojúṣe alága àwọn alábòójútó, èyí á sì mú kó rọrùn fún wọn láti túbọ̀ bójú tó ìjọ lọ́nà tó múná dóko.—Ìṣe 20:28.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ yìí ò tíì bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà báyìí, a máa fi ìsọfúnni tó yín létí nígbà tákòókò bá tó. Inú wa dùn pé Jèhófà ti pèsè ilé ẹ̀kọ́ yìí nítorí ìfẹ́ tó ní sí wa, a sì ń wọ̀nà fún ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ ní Nàìjíríà.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Nàìjíríà