Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Oct. 1
“Àwọn òjọ̀gbọ́n mọ̀ pé ipa kékeré kọ́ ni bàbá ń kó nínú ìdílé. Kí lo rò pé ó lè mú kéèyàn jẹ́ bàbá tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Jésù jẹ́ ká mọ bí àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́. [Ka Jòhánù 5:19.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́fà tó jẹ́ ojúṣe bàbá.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 18 hàn án.
Ile Iṣọ Nov. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì pé báwo ni Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ á tún ṣe máa dá àwọn kan lóró títí ayé. Kí lèrò tìẹ nípa èyí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì kọ́ wá pé Ọlọ́run kì í ṣe òǹrorò tàbí ẹni tó máa ń foróyaró. [Ka Ìsíkíẹ́lì 18:23.] Wàá gbádùn àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.”
Jí! Oct.–Dec.
“Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń jiyàn lórí ọ̀ràn bóyá èèyàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tó bá ti kú. Kí lèrò tìẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jóòbù gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. [Ka Jóòbù 14:14, 15.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tí Bíbélì kọ́ni lórí ọ̀rọ̀ ìwàláàyè lẹ́yìn ikú.”
“Ǹjẹ́ o rò pé ó wu Ọlọ́run pé kí àìtó oúnjẹ máa pọ́n aráyé lójú bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe láti yanjú ìṣòro náà. [Ka Sáàmù 72:16.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ayé yìí di Párádísè pa dà.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 7 hàn án.