ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/08 ojú ìwé 8
  • O Lè Di Olùkọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Di Olùkọ́!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Bí A Ṣe Ń Dá Àwọn Òjíṣẹ́ Ìjọba Náà Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Jèhófà Ń Dá Wa Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Yìí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ̀yin Alàgbà, Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Dá Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 11/08 ojú ìwé 8

O Lè Di Olùkọ́!

1. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni gbogbo akéde Ìjọba Ọlọ́run ní?

1 Ọ̀kan lára àwọn apá tó lérè jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni kíkọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó máa ń wúni lórí gan-an tá a bá rí i tí onítọ̀hún tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ràn án lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Ják. 4:8) Ohun tó yẹ kó jẹ́ àfojúsùn gbogbo àwa tá a jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run ni pé ká kọ́ ẹnì kan tí ebi òtítọ́ ń pa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ká sì máa rí bí onítọ̀hún ṣe ń ṣàwọn àyípadà pàtàkì nínú ìwà, èrò, àti ìṣe rẹ̀.—Mát. 28:19, 20.

2. Kí ló lè fà á táwọn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí í darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí?

2 Gbára lé Jèhófà: Nígbà àtijọ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń rò pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó lè ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé àwọn lọ́wọ́. Nítorí pé Mósè, Jeremáyà, Ámósì àtàwọn èèyàn gbáàtúù mìíràn gbára lé Jèhófà Ọlọ́run ló mú kí wọ́n borí iyèméjì tàbí àìbalẹ̀ ọkàn wọn, wọ́n sì gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta ṣe. (Ẹ́kís. 4:10-12; Jer. 1:6, 7; Ámósì 7:14, 15) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù “máyàle.” Báwo ló ṣe ṣe é? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé “nípasẹ̀ Ọlọ́run” ni. (1 Tẹs. 2:2) Jèhófà ló yẹ káwa náà gbẹ́kẹ̀ lé fún ìrànlọ́wọ́, ọgbọ́n, àti okun tá a nílò láti máa darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń méso jáde.—Aísá. 41:10; 1 Kọ́r. 1:26, 27; 1 Pét. 4:11.

3, 4. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó tó lè ràn wá lọ́wọ́ nínú kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

3 Gba Ìdálẹ́kọ̀ọ́: Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe Olùkọ́ni Atóbilọ́lá wa ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tẹ̀mí tá à ń gbà déédéé, èyí tó ń mú ká pegedé ní kíkún gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. (Aísá. 54:13; 2 Tím. 3:16, 17) Máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí nípa ṣíṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti fi kún òye rẹ nípa Ìwé Mímọ́, kó o sì mú kí ọ̀nà tó o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sunwọ̀n sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé olórí ìdí nìyí tá a fi ṣètò ìpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, gbogbo ìpàdé ìjọ pátá la ti ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni.

4 Sapá láti kọ́ àwọn ọ̀nà tó rọrùn tó o lè gbà kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀. Ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 227, ṣàlàyé pé: “Kókó ọ̀rọ̀ rẹ ní láti yé ìwọ fúnra rẹ kedere kí ó tó di pé wàá lè ṣàlàyé rẹ̀ yé àwọn ẹlòmíràn.” Bá a bá ń dáhùn láwọn ìpàdé, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti fàwọn kókó pàtàkì tó máa wúlò fún wa sọ́kàn. Nítorí náà, máa múra sílẹ̀ dáadáa, kó o lè túbọ̀ máa kọ́ni pẹ̀lú ìdánilójú.

5. Àwọn àfikún ìdálẹ́kọ̀ọ́ wo là ń jàǹfààní nínú ìjọ tó lè mú ká máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí olùkọ́?

5 Kò sí àní-àní pé látìbẹ̀rẹ̀ làwọn Kristẹni òjíṣẹ́ ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látara ẹni kìíní kejì tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn náà. (Lúùkù 10:1) Tó bá ṣeé ṣe, máa bá àwọn akéde tó nírìírí dáadáa lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn bíi aṣáájú-ọ̀nà, àwọn alàgbà, àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Máa kíyè sí i bí wọ́n ṣe ń lo àpèjúwe tó rọrùn àti bí wọ́n ṣe ń lo àwòrán tàbí nǹkan míì tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa láti fi ṣàlàyé ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ní kí wọ́n fún ẹ ní àwọn àbá nípa bó o ṣe lè di olùkọ́ tó sunwọ̀n sí i. (Òwe 1:5; 27:17) Fi ìmọrírì hàn fún gbogbo àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n ti ń wá.—2 Kọ́r. 3:5.

6. Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ téèyàn bá fẹ́ di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

6 Gbara lé Jèhófà, kó o sí máa jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ń pèsè. Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú. (Sm. 25:4, 5) Ìwọ náà lè ní ayọ̀ tó máa ń wá látinú ríran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi tìrẹ!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́