ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/09 ojú ìwé 3
  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • “Èyí Ni Ohun Tí Ìfẹ́ fún Ọlọ́run Túmọ̀ Sí”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 1/09 ojú ìwé 3

‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’

1. Kí nìdí tá a fi ṣe ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’?

1 Ara wa ti wà lọ́nà gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé tuntun náà, ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ February 23! Nínú ìwé náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí kádìí lẹ́tà tí wọ́n kọ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olùfẹ́ Jèhófà pé: “Nítorí náà, ó dá wa lójú pé ìwé yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fi òtítọ́ ṣèwà hù ní ìgbésí ayé rẹ, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ dúró ‘nínú ìfẹ́ Ọlọ́run . . . pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.’—Júúdà 21.”

2. Àwọn apá wo nínú ìgbésí ayé ni ìwé tuntun yìí ti máa ràn wá lọ́wọ́?

2 Àwọn Nǹkan Tá A Lè Máa Wọ̀nà Fún: Báwo la ṣe lè fáwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn, eré ìnàjú, ọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ, ìwà wa, ìgbéyàwó, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa? Ẹ̀rí ọkàn wa á di èyí tá a mú bá àwọn ìlànà òdodo tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Sm. 19:7, 8) Bí òye wa nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa wù wá láti máa ṣègbọràn sí i nínú ohun gbogbo, a ó sì máa tipa bẹ́ẹ̀ múnú Ọlọ́run dùn.—Òwe 27:11; 1 Jòh. 5:3.

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká sa gbogbo ipá wa láti máa kópa nínú ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

3 Pinnu Pé Wà Á Dáhùn: Bó o bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, fi ṣe àfojúsùn rẹ láti yin Ọlọ́run láàárín àwùjọ àwọn èèyàn rẹ̀. (Héb. 13:15) Gbogbo ìjọ ló máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé tuntun yìí pa pọ̀. Torí pé ìwọ̀nba làwọn apá tá a ó máa gbé yẹ̀ wò lọ́sẹ̀, èyí á fún gbogbo wa láǹfààní láti máa múra sílẹ̀ dáadáa, á sì jẹ́ ká fi ìdánilójú sọ ohun tá a kọ́. Bá a bá ń múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, táwọn ìdáhùn wa ṣe ṣókí tó sì sojú abẹ níkòó, èyí á mú ká máa ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, á sì tún jẹ́ kí ìpàdé gbádùn mọ́ni kó sì nítumọ̀. (Héb. 10:24) Síwájú sí i, ayọ̀ wa á tún kún bá a ṣe ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ jáde.

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́?

4 Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó sọ pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn pa àṣẹ Jèhófà mọ́ láti lè dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Jòh. 15:10) Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ bá a ó ṣe máa fàwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa àti bá a ṣe máa ‘dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’—Júúdà 21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́