Iṣẹ́ Ìwàásù Máa Ń Jẹ́ Ká Lókun Nípa Tẹ̀mí
1. Àǹfààní wo là ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
1 Tá a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù déédéé, ó máa fún wa lókun nípa tẹ̀mí, ó sì máa jẹ́ kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i. Àmọ́ o, olórí ìdí tá a fi ń wàásù ni ká lè múnú Jèhófà dùn. Síbẹ̀ tá a bá ṣègbọràn sí àṣẹ náà pé ká “wàásù ọ̀rọ̀ náà,” a máa rí ìbùkún Jèhófà, a sì tún máa ṣe ara wa láǹfààní láwọn ọ̀nà míì. (2 Tím. 4:2; Aísá. 48:17, 18) Báwo ni wíwàásù ṣe lè fún wa lókun kó sì tún jẹ́ ká láyọ̀?
2. Àwọn ọ̀nà wo ni iṣẹ́ ìwàásù gbà ń fún wa lókun?
2 À Ń Rí Okun àti Ìbùkún Gbà: Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá, dípò àwọn ìṣòro tó ń báwa fínra lóde òní. (2 Kọ́r. 4:18) Tá a bá ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn, ńṣe ló máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì òtítọ́. (Aísá. 65:13, 14) Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n má sì jẹ́ “apá kan ayé,” ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìpinnu wa láti ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé lágbára sí i.—Jòh. 17:14, 16; Róòmù 12:2.
3. Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe ń mú ká láwọn ànímọ́ Kristẹni?
3 Lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tún máa ń jẹ́ ká láwọn ànímọ́ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe ń sapá láti “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” ń sọ wá dẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (1 Kọ́r. 9:19-23) Bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn tá a ‘bó láwọ, tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn’ sọ̀rọ̀, ó máa ń mú ká kọ́ béèyàn ṣe ń lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn àti ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. (Mát. 9:36) A máa ń kọ́ ìfaradà tá a bá forí tì í láìka ẹ̀mí ìdágunlá tàbí àtakò sí. Ayọ̀ wa máa ń pọ̀ sí i tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—Ìṣe 20:35.
4. Ojú wo lo fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
4 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó ń fi ìyìn fún Ẹnì kan ṣoṣo tó tọ́ láti gba ìjọsìn wa! Iṣẹ́ ìwàásù máa ń fún wa lókun gan-an. A máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún tá a bá ń fi tọkàntọkàn “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24.